Idi tawon osise MAPOLY fi gbe ebo ka-n-ka losan gan-gan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 17, 2017

Idi tawon osise MAPOLY fi gbe ebo ka-n-ka losan gan-gan

Kayeefi loro naa si n je fawon araalu to gbo nipa iyanselodi tipatipa ti agbarijo awon osise ileeko giga gbogbonise ti Moshood Abiola to ti yi oruko pada di Moshood Abiola University of Technology bayii se lojo Isegun Tusde to koja.


Lakoko naa
Kii se bi won se bere iyanselodi naa lo je koro naa je kayeefi bi ko se ti ebo ka-n-ka ti won tun un gbe losan gangan pe awon ko nii gba ki won fi obo lo won peluu igbese tawon alakoso ileewe, iyen Governing Council naa n gbe labele lati da gbogbo won duro lenu ise.

Gege bi AWIKONKO se gbo, nnkan to faa ti won ni won fee fi dawon osise to le ni oodunrun (300) duro ni bi won se so pe won fee bere ise Yunifasiti ti ajo to n ri soro ileewe giga lorileede yi, iyen ajo, National University Commission (NUC) se ti fowo sii lose to lo lohun pe kise bere lekunrere.

Iroyin to te wa lowo je ko ye wa pe inu osu kesan an odun yi ni won fee bere ise Yunifasiti naa ni pereu, ati pe leyin ti won ba da gbogbo won duro, ni won yoo tun sese ko leta iwase, Application Letter, ti awon alakoso yoo si mo awon to kaju osuwon lati gba sise.

Igbese lati dawon osise yi duro lo lu sita fawon kan lojo Eti Fraide ose to lohun, ti won lawon kan ko kaa si, sugbon nigba to maa di ojo Aje Monde to koja, ti oro naa bere sii koja oju ti won fi n woo, ni won ba so pe bawon ko ba tete gbe igbese pajawiri, o seese ki kini naa bawon lojiji.

Eyi la gbo pe o fa a ti won fi sepade pajawiri pe awon kawon tete ja fun eto awon, nitori pe ko si osise tabi olukoo ti ko kaju osuwon lati ko eko to ba ilana Yunifasiti mu, nitori ti won so pe opo awon osise ti won fee da duro lo ti lo to ogun odun lenu ise.

Ohun taa gbo ni pe alaga igbimo eto naa, Ojogbon Peter Okebukola bawon agbaagba ninu ajo ASUP sepade lojo Aje Monde pe ki gbogbo awon osise kowe fise sile, kawon to ba si fee lati sise pelu Yunifasiti sese kowe iwase.

Sugbon gbogbo oro ti won lokunrin bawon eeyan naa so ni won so pe awon ko nii gba, ayafi ti won ba fee gbawon osise miran si Ipokia ti won n gbe MAPOLY lo.

Nigba to n soro nipa igbese naa, alaga igbimo eto naa, Ojogbon Peter Okebukola so pe aheso lasan ni gbogbo nnkan ti won n gbe kaakiri naa, o ni kii se pe won fee da won duro lenu ise, bi ko se pe won fe e ko gbogbo olukoo MAPOLY lo siluu Ipokia nibi ti Gomina Amosun gbe MAPOLY lo.

Lesekese ti Gomina Amosun gbo soro naa, lo ti pase pe ki awon osise pada senu ise won, ki igbimo ti won yan lori eto bi Yunifasiti naa yoo se bere yan komisana feto eko, Arabinrin Modupe Mujota gege bi okan lara won, lati je ki igbese ti won fee gbe bawon osise lara mu.

Okan lara awon olukoo to wa leka eko gbogboogbo (GNS), eni taa foruko bo lasiri nigba to n b’AWIKONKO soro losan ojo Eti Fraide so pe abajade ipade ti won se e je ko ye won pe bo tile je pe ileewe Fasiti naa yoo bere ise, sugbon odun meta gbako ni Politekiniiki naa yoo lo nibe ki won too ko won siluu Ipokia.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI