O ma se o; Tirela Dangote pa Kehinde, o tun kan olopaa lese ni Papalanto - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 16, 2017

O ma se o; Tirela Dangote pa Kehinde, o tun kan olopaa lese ni Papalanto

Beeyan ba wa nibi ti won ti sinku arakunrin kan tojo ori e ko tii ju odun mejilelogbon lo, eni ti won poruko e ni Kehinde, ti won ni okan lara awon tirela Dangote te pa lojo Abameta Satide to koja yi, yoo somi loju soororo pelu bawon eeyan se n gbe ileese Dangote to wa niluu Ibese sepe nla-nla.

Oku Kehinde
Oni tii se Aiku Sande ni won sinku Kehinde nilana Musulumi si abule kan ti won pe ni Adunbu niwaju aafin Oba Olu Itori leyin ti won loo gboku e ni mortuary osibitu jenera to wa n’Ifo ipinle Ogun, leyin tawon dokita sayewo ti won loo ti ku patapata.

Pelu iroyin to te AWIKONKO lowo ni nnkan bi aago mesan ale ojo Abameta Satide to koja yi, won ni ni nnkan bi aago mejo kuseju marun un ni awako tirela naa te Kehinde pa nikorita Papalanto.

Ohun ti a gbo ni pe soobu ti Kehinde ti n gerun fawon eeyan lo ti kuro, to si so fawon ti won jo wa pe oun fee de agbegbe 2:1:4 ni Ifo, oun ko si ni pe e de, nitori nnkan toun fe e loo se ko ni gba oun lakoko pupo.

AWIKONKO gbo pe okan lara awon olopaa to mu gege bi ore toun naa n lo si Ifo lo fi okada gbe e lo ni deede aago meje aabo, sugbon nigba to maa ku die ki won debi ti won n lo, la gbo pe olopaa naa ti a ko tii gbo oruko e gba ipe lori foonu e, pe ko tete pada si Itori nitori ise pajawiri kan n duro de e nibe.

Se won so pe kadara ko le tase, ki Olorun ma je ki kadara buruku se mo wa lara, nitori pe kaka ki Kehinde sokale lori okada ko si je ki olopaa yi maa ba tie lo, se lo so pe kawon tun jo pada loo lati lo mo nkan to n sele, ni won ba yi pada.

AWIKONKO gbo pe bi won se de ikorita Papalanto nibi ti ona ti pin sona merin, ni won so pe tirela Dangote kan ti ko si eru ninu e n sare bo lati ona Sagamu, ko si duro lati mo boya ona dara tabi o ye koun duro, won ni se loo kan ja soju titi.

Asiko yi gan an ni won so pe olopaa to wa okada yi naa ti wa nikorita yi, ti won so pe ko si ona to fee gbe e gba lati jawo fun awako tirela Dangote to ti kan won lara tan, sugbon nigba ti won so pe awako naa maa fi mo nnkan to n sele, o ti gbawon olopaa ati Kehinde danu.

Nigba ti Kehinde maa fi subu kuro lori okada sileele, ori ni won so pe o mu lo sile, eyi lo faa ti won ni ori e fi fo, ti eje si bere sii da, olopaa naa ni won so pe ese toun n naa kan si meji.

Oku e tun re e
AWIKONKO gbo pe ariwo tawon toro naa soju won pa ni ko je ki awako tirela Dangote naa duro,  to na papa bora. Bo tile je pe won lawon kan fi moto le, sugbon nigba ti won tun rii pe ere to n sa naa po ju, to si tun pa elomin in niwaju, ni won ni won fi pada leyin e.

“Nibo lo wa, nibo lo gba” nibeere ti won lawon toro naa soju won n beere lowo ara won, sugbon ti won ni ko duro. Nigba tawon eeyan maa fi sunmo Kehinde ati olopaa nibi ti won subu si laarin titi, Kehinde ti ku, olopaa yi ni won lo n pariwo ekun pe “E ma je n ku bayii.”

Lesekese la gbo pe awon alaanu seto, ti won si oku Kehinde ati olopaa yi loo si osibitu jenera ti Ifo. Motuari la gbo pe won gbe oku Kehinde lo nitori ti won ni ko si nkan tawon dokita fee foku naa se, sugbon ti olopaa n gba itoju lowo.

Okan lara awon to sunmo Kehinde to salaye oro naa fun AWIKONKO laaro oni, eni to ni ka foruko boun lasiri so pe “Kehinde lo maa n gerun fun mi nitori pe o morun un ge. Iku e ya wa lenu gan an nitori pe ko seni to roku ro o. Ko pe to firidoomu fawon omose e meji kan tan lo ra omi (pure water) meji.

“Ko mu eyokan tan to fi gbe e sile. eyokan to ku lo so lu omobinrin kan ti won jo n sere ni nnkan bi aago meje. Ko pe lo so pe oun n lo si 2:1:4 n’Ifo, oun ati olopaa kan ni won jo lo. Ko tii ju ogbon iseju lo la gbo pe o ti ku, won ni tirela Dangote gba oun ati olopaa ti won jo lo ni Papa."

Enikan to tun gboro naa si wa leti so pe ore e kan ti won pe ni 'Shut up' lo se firidoomu fun omoose e, toun naa si lo gege bi oga lati loo sadura ni be. O so pe ibanuje nla niku Kehinde je faawon nitori pe bo se loyaya, bee naa lo nife tomo tagba.

Awon kan lo tun je ko ye wa pe ekeji Kehinde yi, iyen Taye e, okada naa lo gun to fi salabapade iku aitojo, ati pe okan lara awon molebi e kan naa, okada lo so o di alaabo ara. Ki Olorun maa fi iso e so wa. Amin.

Lara awon tisinku naa soju e lo so fun AWIKONKO pe epe lawon eeyan n gbe ileese Dangote se nitori pe won kii se idanilekoo fawon awako ti won n gba, eyi to je ki won maa wa tirela laibikita emi awon araalu.

Bee ni won rawo ebe sijoba ipinle Ogun lati tete bawon wa nkan se soro awon awako Dangote naa, nitori bi won se so pe ifemisofo won ti poju loju ona naa, ati pe emi eeyan ko jo won loju.

Bo tile je pe won ni wahala kekere kan fee dide latari ibi ti won fee sinku e si, nitori ti won so pe ki won loo sinku e sori ile iyawo e, sugbon tawon ebi iyawo yari pe ko seese nitori ojo iwaju, sugbon leyin o reyin ni won lori ile aburo e kan ni won loo sin in si

AWIKONKO gbo pe iyawo meta ni Kehinde fe, bo tile je pe ko fee ni to bimo akoko ti won poruko e ni Waheed tojo ori e ko tii ju odun marun lo fun, sugbon eyi ti won jo n gbe ti bimo meji fun un, to si je pe eleeketa ko tii bimo fun un.

Lati le fidi oro naa mule, AWIKONKO ba agbenuso funleese olopaa, Abimbola Oyeyemi soro, sugbon nnkan to so nipe ilu Ilorin loun wa, oun ko tii gbo nipa isele naa, o ni toun ba de ofiisi lojo Aje Monde loun yoo to sewadi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI