Ija Oselu; egbe oselu APC koju ija sira won l’Orile Ilugun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 31, 2017

Ija Oselu; egbe oselu APC koju ija sira won l’Orile Ilugun

Olopaa tun koju ibon sawon araalu
 
Oro Yoruba kan lo so pe “adie kii je ifun ara won”, sugbon se loro naa da bi eni pe oro naa ko ba tigbalode oloju taa wa yi mu mo nitori bawon omo egbe oselu All Progressives Congress, APC eka t’Orile Ilugun nijoba ibile Odeda se koju ija si ara won l’Ojoru Wesde to koja yi.

Mofoluke
Ibeere tawon eeyan to gbo nipa isele naa ni pe ‘ki loo fa ija’ nitori bi won tun se so pe nise lawon olopaa ti won ni ki won wa daabo bo awon eeyan tun se koju ibon sawon araalu nigba toro naa di bolo o yago lona.

AWIKONKO gbo pe asiko tegbe oselu naa se abewo kan ti won pe ni Mid-Term Assessment Tour sawon igberiko kaakiri ipinle Ogun ni wahala naa be sile lakoko ti ayeye naa n dun mo won.

Won ni bi odun 2019 se n sunmo etile lawon eeyan naa ti bere sii gbogun ti ara won lati da egbe naa si meji, konikaluku si duro laaye ara e lati ni omoleyin ti e.

Enikan tisele naa soju e so pe kii se pe won deedee da wahala naa sile bi ko se pe won fee pa alaga ijoba ibile idagbasoke Orile-Ilugun, Arabinrin Mofoluke Sowemimo gege bi won se so pe obinrin naa ti n dari won lati igba Otunba Gbenga Daniel.

Won ni Onarebu Adebayo Olashehu to je oludamoran fun gomina ipinle Ogun, iyen Consultant to the governor on IGR, eni to ti n se ipolongo lati dupo lati soju awon eeyan ekun naa nileegbimo asofin agba nilu Abuja lodun 2019 lo sagbateru awon janduku to da ayeye abewo naa ru.

Bee l’AWIKONKO gbo pe eeyan to wa nibe lojo naa le ni egberun meji lati ye alaga won si fawon ise akanse to se sibe, sugbon to je pe asiko ti ayeye naa n dun lawon janduku ti won ni Onarebu Olashehu ko wa sibe ti won ko ju aadota lo dide lati daa ru.

Enikan naa tun t’AWIKONKO lolobo pe akowe ijoba idagbasoke Orile-Ilugun, Ogbeni Jelili Adeogun naa wa lara awon to sagbateru bi wahala naa se waye nitori ti won so pe nise lo deede gbabodi fun alaga won to wa labe e.

Imura ti won ni Onarebu Olashehu ati Jelili Adeogun ti se lo je ki won ko awon olopaa ti won n lo lati loo gba owo ori lowo awon araalu dani lo lati loo fibon won tu won ka.

Lati fidi oro yi mule lo je ki AWIKONKO wa alaga yi, Arabinrin Mofoluke lo si ofiisi e lose to koja lati foro waa lenu wo, to si so pe bi kii ba a se pe oore ofe Olorun wa lara oun ni, o seese koun ti ku nitori pe oun gan an ni won doju ko lati pa.

O nibi ti won ti n le oun pelu ese kan aabo toun ni ni komu (bra) oun ti ja sonu, toun ko si lee so ibi ti bata meji ese oun gba. O lohun ko ni lero pe awon eeyan toun ko lo inu meji peluu won le pe apejo ote le oun lori.

Arabinrin Mofoluke to tun je diakoni (Deaconess) so pe bi ala loro naa si n ri loju ohun ati pe wahala toun n ba pade lojo naa ti da aisan soun lara, nitori pe se ni won tun beresiya oun ja, ti won gba bata lese oun, sugbon to je pe Olorun lo koun yo lowo won.

Lati fidi oro naa mule siwaju sii lati ba Onarebu Olashehu ati Ogbeni Jelili Adeogun ti won fesun kan soro, gbogbo igbese ti a gbe lo ja si pabo titi digba ti a fi sakojopo iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI