Awon ajinigbe merin to ji olopa gbe ti sagbako iku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 31, 2017

Awon ajinigbe merin to ji olopa gbe ti sagbako iku

Opo awon araalu to ri oku awon ajinigbe merin tawon olopaa fibon pa danu nibi ti won ti koju ija sira won lose to koja ni won tun n foku won sepe pe akutunku won lona orun, nitori ti won ko je kawon araalu fedo lori orooro.

Oku won
Gege b’AWIKONKO se gbo, won lawon ajinigbe marun tawon olopaa pa merin ninu won yi lo ji okan lara awon olopaa to wa lekun Owode-Egba, ti won si n beere milionu lona ogorun naira ki won too le yonda e fun won.

Bo tile je pe awon olopaa ko tete mo pe olopaa lawon ajinigbe naa gbe lo lati fi gbowo lowo awon ebi e, to je pe lasiko ti won n sewadi ni won too mo pe ara awon gan an niso ti n run, tawon ko si gbodo fi fale.

AWIKONKO gbo pe ka ni awon odaran naa mo pe okan lara awon olopaa lawon ji gbe lati fi gba owo ni, o see se ki won ti gbemi e, tabi ki won ma ti pinu lati jii gbe, nitori ti won so pe asiko tokunrin naa ko si lenu ise ni won jiigbe, toun naa ko je ki won mo iru eeyan to je laarin ojo marun to fi wa lahamo won.

Stephen Adesokan ti won ji gbe lagbegbe Siun lopopona Ajura siluu Abeokuta so pe gbogbo igba toun fi wa peluu won lo je pe ede ti won n so jo tawon Fulani, bo tile je pe oun ko le so iru ede ti won n so ni patoo, ati pe koun ti won n so ma baa ye oun ni won fi n so ede naa.

Olopaa ti won ji gbe
O nigba ti won beere ise toun n se loun so fun won pe ileese omi (pure water) loun ti n sise gege bi asogba. O ni won so pe bawon ko ba gba milionu lona ogorun naira lowo awon eeyan oun, se lawon yoo pa oun danu.

Nibi tawon olopaa ti sawari ibi ti won wa ni won loro naa ti di bolo o yago, nitori bi won se foju kan awon olopaa ni won ti bere sii dabon bo won, tawon olopaa naa si daa pada fun won pe o ju ara won lo.

Lesekese lawon merin ti ku ninu awon marun un to ji Stephen gbe, ti eni kan to ko si wa lagbede meji oorun ati aye. Ibe ni won ti ko won lo si tesan won lati foju won ha sawon oniroyin.

Abimbola Oyeyemi to je agbenuso funleese olopaa nigba to n b’AWIKONKO soro so pe “Ipe lorisirisi la gbo lose to lo lohun pe won ji enikan gbe, ninu iwadii lati rii pe olopa leni naa ti won n so, ti won tun n beere ogorun milionu naira lowo ki won to le fi sile.” 

Abimbola ni bawon olopaa ti won gbese naa le lowo see ti foju kan won lawon odaran naa ti doju ibon ko won bii pe won ti n reti won tele ni. O lesekese lawon naa ti daa pada fun won tawon merin si ku. Bee lo ni eni kan toku wa nibi to ti gba itoju, ki ara e le ya, ko too di pe won tun bere igbese min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI