Odomokunrin kan, Osho Obafemi ti so pe
ise toun mo ju, to si tun rorun foun ju ni jija moto gba, ogba awon olopaaa ni
Eleweran niluu Abeokuta lokunrin naa ti n tu asiri ara e nigba ti won
safihan e.
Obafemi |
Gege bi AWIKONKO se gbo, okunrin kan ti
won poruko e ni Adebayo Adekoya loo fejo sun awon olopaa lojo keji osu kerin
odun yi pe awon kan da oun lona won si gba moto Toyota Corolla toun sese ra,
toun ko tii gba nomba si lowo oun.
Ohun taa gbo pe ni pe agbegbe Ikoto
n’Ijebu Ode lokunrin naa n gbe, sugbon Sagamu lo so pe won ti gba moto naa lowo
oun ni nnkan bi aago mesan ale ojo naa. O ni pelu ibon ni won fi ri moto naa
gba.
Loju ese lawon olopaa ti bere igbese
lori bi won se le ri awon eeyan naa mu, ti Olorun si fun won se, towo si te
Obafemi nilu Ibafo. Iyalenu lo je nigba tawon olopaa mu, bo tile je pe won loo
koko bawon olopaa sagidi sugbon to mu won debi to n ko awon moto to ba ja gba
si.
Olorun lo mo awon to loo se gboborun
fawon ti won jo n sise pelu Obafemi, nitori gbara ti won so pe won gbo pe owo
olopaa ti te Obafemi ni won ti na papa bora ki on too de be. Moto merin otooto
ni won ba ninu ogba ti won n ko awon moto si.
Lesekese ni won ni Obafemi ti so pe ki
won se oun jeje, oun si maa jewo awon ise toun atawon toku oun ti joo se seyin,
sugbon titi di asiko yi, awon olopaa si n wa awon toku.
AWIKONKO gbo pe awon moto ti won ri gba
lowo Obafemi ni Toyota Corolla alawo dudu, Jiipu Pilot Honda, Almera Nissan ati
Toyota Corolla alawo eeru.
Nigba to n jeri soro naa, Komisana
olopaa so pe ki eto aabo tubo le kesejare lawon olopaa se n sise tosan-toru,
eyi lo si fa kasiri awon odaran maa tu sawon lowo. O ni lesekese tawon araalu
ba ti ta awon lolobo lawon ti maa n gbe igbese.
Bakan naa lo so pe kawon eeyan ma se
maa gboju fo awon ajoji ti won ba salabapade ladugbo won da, ki won tete foro
naa to awon olopaa leti, nitori aabo emi ati dukia awon araalu lo je awon
olopaa logun.
No comments:
Post a Comment