Won ti ha o; Chukwudi atore e ti won gba moto ni Sagamu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 10, 2017

Won ti ha o; Chukwudi atore e ti won gba moto ni Sagamu

Ileese olopaa ti rowo to awon odaran meji kan, Chukwudi Okorie ati Nkemjika Nwoke ti won so pe won ko nise meji ju ki won maa dena de awon onimoto duro lori ere, iyen ni opopona Ekoo si Sagamu.

Awon mejeeji
Gege bi AWIKONKO se gbo, ogunjo osu to koja ni won lawon kan  loo ta awon olopaa ekun Sagamu lolobo, ti oga olopaa to wa nibe iyen DPO si ran awon olopaa kogberegbe FSARS lati loo mu won, ki won le fi won jofin.

Iwadii fi ye wa pe  ni nkan bi aago mesan aabo ale ojo naa tawon olopaa de ibi ti won ni won ti n dana, ni won doju ija ko won towo si te Chukwudi ati Nwoke nigba tawon yooku juba ehoro..

Titi di asiko yii lawon olopaa si n wa awon to ti won salo naa, sugbon ti omisana olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu si seleri pe ko sibi tawon odaran naa le gba towo awon ko nit e won.

O so pe awon ohun ija oloro orisirisi bii iso, ibon Pump action meji, ibon ibile kan atawon ota ibon merin ni won ri gba lowo awon towo te naa.

Bee lo tun ro awon araalu pe ki won ma se bo enu won nigba ti won ba gbo firi awon afurasi odaran ladugbo won, nitori aabo emi ati dukia awon araalu lo je oun logun julo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI