Senato Yayi di erujeje fun Gomina Amosun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 25, 2017

Senato Yayi di erujeje fun Gomina Amosun


Ko tii seni to le so ibi toro naa yoo yori si bayii, lori bi Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun se n fojoojumo yo awon to fi sipo nitori Senato Solomon Adeola, iyen Yayi, gege bi a tun se rii gbo lose to koja pe, Gomina Amosun tun ti yo okan lara awon alaga garaaji nilu Abeokuta, Akeem Iyeru, eni ti won loo ko ipa to po ninu idibo to gbe e wole lodun 2011 ati 2015.
 
AWIKONKO gbo pe leyin ti Senato Yayi kuro nibi eto kan tawon obinrin gbe kale lose to lo lohun, lo loo se abewo sawon osise garaaji to wa lagbegbe Ita-Oshin, tawon yen si kii kaabo pe awon n gbadun e.

Se e kuku mo iwa awon omo garaaji bi won se maa n se fawon ti won ba fee gbowo lowo e, pe baba rere, baba kee, bo tile je pe ko kii denu won, sugbon ki won le ri owo gba, eyi gan an lo fa ti won fi surubo Senato Yayi lakoko naa, toun naa si seleri fun won pe oun yoo mu inu won dun toun ba wole gomina lodun 2019.

Ko pe ti Senato Yayi kuro nibe lawon kan to sunmo Gomina Amosun ti se gbeborun fun un pe awon osise garaaji Ita-Oshin gba Senato Yayi lalejo, o si ti seleri orisirisi fun won, bee lo tun fun won lowo peluu.

Odi la gbo pe Gomina Amosun, eni ti kii fe gbo oruko Senato yi seti gba oro naa, to si ranse pe alaga garaaji yi, iyen Ogbeni Akeem Iyeru lati foro waa lenu wo pe ki lo ri l’obe to fi wa iru sowo.

Eni kan to sunmo ijoba ipinle Ogun, to gbe oro naa si AWIKONKO leti so pe lesekese ti Gomina Amosun foju kan Iyeru lo pase pe ko kowe fipo alaga naa sile, ati pe oun ko fe rii mo ni garaaji eyikeyi nilu Abeokuta nitori o ti gbabodi foun.

Bi e o ba gbagbe, laipe yi ni Gomina da okan pataki to feran ju, to je amugbalegbe e, Ogbeni Damilola Ogunpola duro leyin to gbo pe okunrin naa ti fee gbabodi, to si ti n lo sepade po pelu Yayi, gbogbo bi won se lokunrin naa fee so tenu e l’Amosun loun ko fee gboro lenu e.

Bakan naa la tun gbo pe o yo awon alaga APC nijoba ibile to to meedogun nitori tiroyin kan si pe won ti fee faramo Yayi, eni tawon eeyan ti n gbosuba fun un pe oun nipo Gomina Kan lodun 2019. 

Ko soun meji tawon osise n beru bayii bi ko se pe won sora won lati soro to jo mo ti Yayi, nitori pe bi eni bu ata si egbo lo ma n ri lara Gomina Amosun to ba gboruko Yayi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI