Asiri pasito Samuel to n lo dudu sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 25, 2017

Asiri pasito Samuel to n lo dudu sita

O ni elede loun maa n ri mole ninu soosi kii seeyan

A fi ki Olorun maa ko wa yo lowo awon iranse esu ti won foruko Olorun boju pe ara won niranse Olorun nitori bi asiri won se n fojoojumo tu sawon araalu lowo. 

Pasito Samuel atawon eeyan e
Lose to koja la mu iroyin ti pasito Kehinde Onayiga to n lo dudu wa fun un, bo tile je pe iru won naa si po kaakiri, ayafi eyi ti afefe ba fe si furo adie won. 

Ose naa lowo awon olopaa ipinle Ogun tun te iranse esu kan,  Samuel Babatunde to pe ara e niranse Olorun, to je oludasile ijo Kerubu ati Serafu, Itedo Isinmi Ayo to wa lagbegbe Egan, Iyana Iyesi, Ota. 

Ohun ti a gbo ni pe Samuel,  eni odun metadinlogorin, 77 maa n ra awon eeyan lati fi setutu fawon eeyan to ba wa sise irapada ni soosi, toun naa si tun maa n lo won funra e. 

AWIKONKO gbo pe asiri Samuel tu leyin tawon olopaa mu okunrin kan Jeremiah Adeola, to je ogbologbo ajinigbe lojo Abameta Satide to koja lo lohun, to si jewo pe Pasito Samuel ati enikan lo ran oun nise. 

Eyi lo faa tawon olopaa digboluja FSARS fi kogun loo ba lojo Aiku Sande nibi to ti n waasu oro Olorun fawon omo ijo e lori  pepe iwaasu, ti won si ko sekeseke sii lowo atese. 

Oro di boolo o yago lojo naa, sugbon ti enu ya opo awon eeyan nigba ti won bere sii fo awon ile ayika soosi, ti won si ri eya ara to jo teeyan, to ri mole niwaju soosi.

Nibe ni won ni Samuel ti ni ki won se oun jeje, pe oun a jewo fun won ti won ba gba oun laye. O ni kii se oun nikan lawon jo n see, okunrin kan to n je Haruna Afolabi, to je babalawo pelu. 

Ohun ti a gbo ni pe lesekese tiroyin ti kan si Haruna pe awon olopaa ti Waa mu Samuel lo ti fee ma papa bora sugbon tawon kan tawon olopaa lolobo pe okunrin naa ti n salo, ko too di pe won ragabu e mole. 

Haruna Afolabi, eni odun metalelogoji, 43years so pe ko si nnkan toun fee so nigba tasiri awon ti tu. O ni looto babalawo loun, o si ni boun se n sise oun. 

Samuel nigba to n bakoroyin wa soro, o ni "Mo kabamo pe emi ni mo se iru nnkan bayii. Odun 2005 ni mo ti da soosi yi sile, leyin tOlorun pe mi pe ki n wa sise foun. Mo koko sa seyin nigba yen, sugbon nigba to ya ni mo gba lati da ijo sile. 

"Mi o ri eeyan mole,  elede ni mo ri mole ti won so pe eeyan ni.  Aaye ni mo ri elede naa mole nigba ti mo rii pe ijo yen ko dagba bo se ye. Looto ni mo mo Jeremiah Adeola,  Ibadan lati pade ni ori oke kan. 

"Mi o mo nipa ka maa soogun, mi o si kii ra eeyan to won ba ji gbe. Iro lo pa mo mi nitori pe o ni aarun apolo ni ko je ko mo nnkan to n so. O fee ko ba mi ni. Nitori ki itura, le wa fawon omo ijo,  ki n le ri lokiki ati ilosiwaju ni mo se ti elede yen mole si enu ona abawole soosi, mi o fi se ibi."

Jeremiah nigba toun naa n soro, o ni "Enikan to n je Olaniyi lo fa mi wonu ka maa ji eeyan gbe loun 2013. Moto ni won maa n lo lati fi ji eeyan gbe. Egberun lona aadota naira ni Pasito Samuel maa n ra enikookan ninu awon to mo ba ji gbe lowo mi."

Komisana olopaa ipie Ogun, Ahmed Iliyasu ti waa pase pe awon olopaa oun gbodo rii daju pe won tubo sewadi lati le ti awon toku mu,  paapaa Olaniyi ti won loo ti salo. 

O seleri pe elese won ki yoo lo lai jiya ese won, nitori e ni won se gbodo foju bale ejo. O wa gbawon araalu lamoran pe ki won ma se bo enu won ti won ba kefiri awon odaran paapaa iru awon eeyan to won n feeyan seso bayii, Ki won maa fi to awon olopaa leti. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI