Olatunde foogun abenugongo lu Augustine pa n'Ibogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 25, 2017

Olatunde foogun abenugongo lu Augustine pa n'Ibogun

Ibeere tawon araalu tun bere sii beere lowo ara won ni pe "nigba wo lawon olopaa tun ti bere sii nigbagbo ninu oogun abenugongo?", nigba ti won mu okunrin kan,  Olatunde Akapo pe o foogun na enikan pa. 

Olatunde
Bo tile je pe ojoojumo lawon olopaa maa n so pe oro oogun ko si ninu iwe ofin orileede yi, sugbon toro naa ti yi pada bayii. 

Ohun ti a gbo ni pe oro kan la gbo pe o sele laarin Olatunde, eni odun mejilelogbon, 32years ati eni ti won jo n gbe, Augustine Ode, eni odun mejilelogoji, 42years ladugbo Alapako Eke, Ibogun ipinle Ogun. 

AWIKONKO gbo pe bawon eeyan se n gbiyanju lati bawon pari lawon mejeeji jo n leri iku sira won, pe enikan gbodo fi aye sile fenikan ninu won. 

Sa dede la gbo pe Olatunde wole lo, lero okan awon eeyan pe oro naa ti tan ninu, sugbon nigba to maa jade sita pada, oogun abenugongo la gbo pe o mu jade. 

Ere lawon toro naa soju e koko pe e,  afigba ti won ni Olatunde fi kinni naa lu Augustine leyin orun, tiyen si subu lule, to bere sii japoro be eni to lu magun lara obinrin. 

AWIKONKO gbo pe ko seni to le sunmo okunrin naa nileele to wa, nitori ti won so pe se lawon eeyan n sa seyin lati sunmo on kawon naa ma baa lu gude, ko too di pe o ku patapata. 

Nibe ni won lawon toro naa soju e to ranse pe aburo e pe ko waa wo nnkan to n sele, won ti foogun lu egbon e pa nitori oro ti ko to n kan. 

Bokunrin aburo oloogbe yi se de, to ri oku egbon nile, lo sare gba tesan olopaa to wa n'Ibogun lo lati loo fejo sun awon olopaa to wa nibe. 

Eyi lo faa ti won lawon olopaa naa fi gbera lati loo mo nkan to n sele,  nigba tawon naa de be, iyalenu lo je fun won pelu ipo ti won so pe won ba oku naa, pelu bawon eero tun se pe lee lori. 

Awon araadugbo la gbo pe won ko je ki Olatunde salo kawon olopaa too de, nitori ti won so pe okunrin naa ti mura lati fese fee. 

Pakopako bi maalu to ri obe lowo alapata la gbo pe Olatunde n wo nigba to de tesan olopaa, to si n bebe pe ki won dariji oun,  tori pe ise esu ni. 

Komisana olopaa ipinle Ogun nigba to gbo soro naa,  o ni ki iwadii tubo bere siwaju sii latari ayewo autopsy to ni ki won se foku naa, lati le je eri ti won loo ti gbe Olatunde lo siwaju adajo. 

Ni bayii, AWIKONKO gbo pe mosuari  osibitu jenera to wa ni Ifo la gbo pe won gbe oku naa si, nibi ti won ti n reti lati sayewo naa. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI