Gbajumo osere tiata
to filu Abeokuta sebugbe, Alaaji Waheed Ijaduade tawon ololufe e tun mo si
Dimeji ti b’AWIKONKO soro lori iku to pa okan lara awon eeyan pataki nidi ise
tiata, Oloogbe Isaiah Olurotimi Ayinde topo mon on si Abu Olododo, eni to je
agba akowe iranti (Continuity Director) ninu awon fiimu agbelewo to n
jade. Dimeji ni boun se sunmo on too, iyalenu lo je foun pe oun ko mo pe
oloogbe naa ni aisan kan lara. E kaa bo se so.
AWIKONKO:
Kin ni e le so nipa oloogbe Abu Olododo?
Dimeji:
Olurotimi Isaiah Ayinde, Abu Olododo je eni ti a ti mora ti pe, o ti le ni
ogbon odun. O sunmo mi pupo. Oun lo maa n se akowe iranti (continuity) gbogbo fiimu ti mo gbe jade, okan pataki to tun dara ju
ninu awon to n se akowe iranti ni. Ti o ba ki n se pe oun lo dara ju, okan lara
awon taa nii nipinle Ogun ni, ti mo si le fowo soya e, nitori pe critics ni peluu.
To baa maa ba ibi kan
yo sii yin nigba ti a baa n se atunto ere, iyen screenplay, ee mo pe ododo oro wa ninu nkan to ba so. Ko sigba ti
mo fee ya ise, ti mi o ki n lo o, nitori pe irinse pataki lo je. O ba mi lokan
je pupo nigba ti mo gbo iroyin iku e, ko da gan an, gbogbo bii ose meji seyin,
a jo se atunto (screenplay) ise kan
ni.
O sunmo mi lopolopo.
Bawon eeyan se n so pe o ni polisi (policy), sugbon mo rii pe o feran mi, o
si tun beru mi. Ibanuje lo je pe asiko yi lo ku si.
AWIKONKO:
Won ni eyin ni osere tiata ti Abu Olododo ba soro keyin, se looto ni, ati pe ki
le jo so?
Lakoko, o le ri bee,
nitori pe mo lo fun Creative Nigerian Summit kan niluu Ekoo, eyi tijoba apapo sagbekale e, o seni laanu
pe ko raaye lo, sugbon nigba ti a soro, se lo n bi mi leere nnkan ti a ba bo
nibe, nitori pe iru awon nnkan bee lo maa n nife si nipa ilosiwaju paapaa to ba
je mo tise tiata ati lagbo osere. Oro ilosiwaju la si ma jo n so ni gbogbo
igba.
Leyin yen, o tun ni
awon ise kan to ti n seto e, to si fee se pelu ileese OGTV, temi naa si n
gbadura pe ki ero yen ma ku sona bi eefin, nitori pe o ti file sasobora. O n
beere nipa awon omo wa to maa nife lati darapo mo ise yen. Mo ni taa ba rira, a
a tubo soro sii nitori pe o n fe mo nkan ti mo ri sii, ati iha ti mo ko sii, mi
o fe maa so gbogbo e lori foonu. Mo si ri ateranse e titi di aago mewaa kuseju
mokandinlogun (9:41pm) ale ojo naa lori Whatsapp mi.
Se lo waa ya mi lenu
bi mo se gbo pe o ku, adiitu lo je fuun mi. Okan ninu awon omoose mi, Yemkem lo
pe mi, to n so fun mi, nitori won mo pe emi a ti e la sunmo ara wa ju. O n
beere pe ki lo se Olododo, mo ni ko si nnkan to se e, o ni nnkan toun gbo ni pe
o ku, aya mi ja, mo ni a si soro lale ana kee. Lesekese ni mo ti loo wo aso, ti
mo si lo sibe. Igba ti mo de be ni won so pe won ba lori ijokoo, to fowo leran,
to si dake si be.
Gege bi nnkan ti mo
gbo, omo merin ati iyawo meji lo ni, bo tile je pe okan lara awon iyawo e ti
lo, sugbon eyokan lo wa pelu e.
AWIKONKO:
Kini ipinu egbe osere tiata fun ayeye isinku e?
Dimeji:
Gege
bi egbe, awa naa gbodo ni nnkan ti a maa se lori ayeye ikeyin fun, nitori pe
eeyan pataki ni, a o si gbodo sinku e gege bi eni ti a o ka kun ninu egbe. A
sese maa loo jokoo lati se asaro ni, ti a si maa kopa to joju pelu bo se je
okan pataki ninu awon omo egbe. Bo tile je pe won o ni oruko bii ti awa, ti
awon eeyan ko fi bee mon on, sugbon awa taa jo n sise mo ipa to n ko leyin kamera ati nigba ti a baa n po ise po.
Ko seni ti Abu
Olododo ko ba sise ninu awa onitiata Yoruba lorileede Naijiria, a fi awon to
sese n wole. Awon bii Olaiya, Mista Latin, Odunlade, paapaa gbogbo awon ise
Mosun Filani to je pe emi ni mo sakoso e, Abu Olododo pelu awon to lewaju akowe
iranti won. Bee naa lo je pe ilaji ninu ise Oloogbe Alaasari to je pe emi ni mo
sagbateru e, oun lo se akowe iranti won.
AWIKONKO:
Ko pe ose kan ti Oloogbe Oloye Adebayo Faleti ku ni Abu naa tele. Awon to ti lo
laarin eyin osere tiata lodun yi ti fee to mewaa, ki lo n sele gan an?
Dimeji:
“Le sebo, le soogun, baa ti waye paari la maa ri.” Emi o nigbagbo pe akufa tabi
aida kan wa ninu bawon osere tiata se n
ku lasiko yi, ewe kan o si le jabo lara igi lai si ase Olorun Oba. Bonikaluku
ba de ibudoko e, o di dandan ko bo sile. Sugbon nitori pe eni to loruko lawon
eeyan se n mo, aimoye awon to n ku lojumo tawon eeyan ko mo won. E je ka mojuto
ara wa, ka gbaruku ti aare ati aisan to ba n se wa lasiko. E ma je ka bara je,
e je ka gba pe asiko won lo to.
No comments:
Post a Comment