Wahala awon omo egbe okunkun tun un peleke sii l’Orile Ilugun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, August 14, 2017

Wahala awon omo egbe okunkun tun un peleke sii l’Orile Ilugun

Titi di bi a ti n koroyin yi lowo lawon olugbe nijoba ibile Orile Ilugun si fi n gbe ninu iberubojo ti wahala awon omo egbe okunkun ti won ni won n fojoojumo yo won lenu, ti won ko tun je kawon ara oja Kila nisinmi bo ti to ati bo ti ye.

Mofoluke Soremekun, alaga Orile Ilugun
Lojo Isegun Tusde to koja lo yi ni won lawon omo egbe okunkun naa tun gbe wahala won yo, ti won si kolu awon oloja atawon olokada, eyi ti won so pe kabiyesi won lo n ti won leyin lati da wahala naa sile.

Gege bi AWIKONKO se gbo, won ni o ti to nnkan bii osu meta bayii ti won ti wa lenu laasigbo naa, eyi to je pe ko se ni to le sun ko diju mejeeji, tabi sun asunwora nigba ti won so pe okunrin kan toruko e n je Nurudeed Salau lo n sagbateru gbogbo wahala naa pelu atileyin kabiyesi.

Ohun ti a gbo ni pe idajo kan ti won gba laipe yii, eyi ti won so pe adajo ileejo Majisireeti to fikale silu Abeokuta, Idowu Olayinka da lojoru Wesde ose to koja nibi to ti pase pe kawon araalu maa sakoso oja Kila, ki won gba a mo ijoba ipinle Ogun lowo lo mu kawon eeyan naa maa huwa talo fee mu mi.

Gbogbo bi won se fesun kan alaga ijoba ibile idagbasoke won, Onarebu Arabinrin Mofoluke Soremekun pe ko mu idagbasoke ba oja naa, to je pe ko mo ju ko maa gbowo ori ori lowo awon oloja lo niwaju onidajo Olayinka ni won lobinrin naa ko sise iwadii to kun to ko too sedajo naa.

Sugbon awon kan to gbe oro naa si wa leti so pe Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ti pase fun obinrin naa pe egberun lona oodunrun din ni aadota (N250,000) naira lowo toun fee maa gba nijoba ibile e losoosu, sugbon ti won so pe lati nnkan bi osu meta, se lobinrin naa n mu owo lapo ara e lati fi kun owo to fi n jise fun ijoba.

Bo tile je pe lose to koja ni gomina Amosun bawon alaga ijoba ibile ati idagbasoke sepade nibi to ti kona oro sagbari gbogbo won pe owo ko wole bo se ye ko wole mo, nibi ti won ti so pe okan lara awon alaga naa busekun pe oun ko gboru oro bee ri laye oun.

Ohun taa gbo ni pe lojo tawon omo egbe okunkun yi, gbogbo oja awon oloja patapata ni won je run, ti won tun se awon oloja basubasu nitori pe ojo naa bo si ojo ti won na oja Kila.

Asiko yi gan an ni won lawon olopaa Odeda koja si, ti won si jo woya ija, sugbon leyin-o-reyin ni won lawon olopaa na papa bora nigba ti won lagbara won ko ka won, nitori ti won so pe olopaa meta pere ni won.

Ibinu ni won fi loo pe awon toku won wa ni tesan, ti won si mu enikan lara won ninu soobu e, eni to si wa latimole titi dasiko ti a n sakojopo iroyin naa lowo, bo tile je pe won ko daruko e.

Okan lara awon agbofinro Odeda taa foruko bo lasiri lo fun wa loruko awon eeyan naa ti won so pe won n da ilu Orile Ilugun ru, tapa awon agbaagba ilu ko si ka won, awon naa ni; Kamorudeen Adeagbo, Mukaila Adeagbo, Taofeek Omobolanle, Wasiu Omoiwa, Tobi Owoeja, Biodun Sodamola, Musibau, Olaolu Oladipo, Damenster, Idowu to je alaga egbe olokada Iyana Efon tele, Morufu topo mo si Consulate ati Sunday ti won loun ati Consulate jo n gbe ni Omi Adio nilu Ibadan.

Gbogbo igbese AWIKONKO lati ba Onarebu Mofoluke soro nipa boro naa se je atawon esun ti won fi kan an lo ja si pabo, obinrin naa nigba to n b’AWIKONKO soro lori foonu so pe oun ko loro lati so nitori pe alaafia ilu loun n wa. O loun ko fe koro naa bo sita gbangba nitori pe awon ti n yanju e.

Bakan naa titi di asiko ti a koroyin yi tan, ni AWIKONKO ko tii ri Kabiyesi ba soro, bo tile je pe okan lara awon baale nibe to ni ka boun lasiri so peojo ti pe tawon ti n bawon omo naa soro pe ki won jawo ninu wahala ti won n fa naa, sugbon ti won ko tiikun soro awon agba.

Okunrin naa so pe oun ti pase pe eni towo olopaa ba ti te ninu won ni ki won loo foju e bale ejo lesekese nitori pe gbogbo won llawon ti bawon obi won soro, sugbon ti won ko le towo omo won bo aso.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI