Onarebu
Sikirulai Olawale Ogundele to je alaga egbe oselu Peoples’ Democratic Party
nipinle Ogun soko oro si Gomina Ibikunle Amosun lori ona to n gba sejoba ipinle
naa. O ni iwa etanu ati talo fee mu mi lo n lo lati fi sejoba e. Bakan naa lo
soro lori ipo ti egbe oselu PDP wa lasiko, o ni agbara kankan ko si mo lowo
Buruji Kashamu, nitori pe awon ti kan iye apa e latari idajo tawon gba nile ejo
giga orileede yi. Ogundele soro yi lakoko to n ba AWIKONKO soro lai pe yi ni
ofiisi e to wa nilu Abeokuta. E kaa bi iforowero naa se lo.
Sikirulai Ogundele |
AWIKONKO:
Oruko yin?
OGUNDELE:
Oruko mi ni Onarebu Sikirulai Ogundele, ti mo je alaga egbe oselu Peoples’
Democratic Party, PDP nipinle Ogun.
AWIKONKO:
Gege bi alaga egbe oselu PDP nipinle Ogun, nibo ni e ba oro awon to ti yapa
kuro ninu egbe naa de bayii?
OGUNDELE:
A dupe lodo Olorun fun idajo ti ileejo giga julo gbe kale laipe yii, nitori pe
idajo naa je eyi to fi wa lokan bale wipe aaye ti si sile lati pari aawo to wa
laarin awon omo egbe. Awon kan wa ti won pe ara won ni omo egbe to je pe egbe
oselu APC lo n lo won, eleyi a fi opin sii. Egbe PDP ti mu ilana lati pada
sijoba po. A ti n bawon to see ba soro ninu awon to n fapa janu, ti a ba dibo,
o di dandan ko je pe enikan soso lo maa wole, eni ti ko ba wole, inu a bii die,
a si ti n be awon to n binu naa pe ki won loo fowo wonu, ki won ma binu mo, ki
won je ka jo se egbe naa. A dupe pe lara awon ti a ba soro, opo ninu won ti
gbo, won si ti pada sinu egbe PDP lodo wa. Sugbon awon ti won o tii pada
niisinyin, a rii pe awon ti won ti fi emi won bura fun Ogbeni Buruji Kashamu.
AWIKONKO:
Titi di akoko yi ni awon igun keji ti e jo n fa oro yi si n leri pe awon ni
akoso egbe naa wa lowo e. AWIKONKO fee mo ibi ti igbese naa de bayii. Ki le fee
so nipa?
OGUNDELE:
Awon ti won n soro yen kan n so sapo ara won ni nitori pe gbogbo ipade ti a n
se nilu Abuja, egbe ti wa lo n wole loo se ipade naa, gbogbo oruko to wa ninu
akosile gege bi olori egbe ni Naijiria, iyen lawon ipinle, oruko temi lo wa
nibe gege bi olori nipinle Ogun. A fi ka fi oro won senu dake. A ti gba leta
lati ilu Abuja pe a fee se ipade gbogboogbo (congress), awon naa tun loo ko ara won jo po ti won lawon n se
nkan, ti a mo pe ko si ona nibe. A si tun n fi asiko yi ro won pe ki won maa
bo, nitori pe aaye si sile fun won sinu egbe ti a pe ni egbe PDP, ki won fi
woroko sada, ki won maa bo wa darapo mo egbe PDP to je ojulowo.
AWIKONKO:
Laipe yi ni ipade kan waye nile Gomina ana nipinle Ogun, Otunba Gbenga Daniel,
nibi ti awon oloselu bii Onarebu Ladi Adebutu, Gboyega Nasiru Isiaka atawon min
in wa. Se kii se ona lati fi pin ipo nipade naa wa fun?
OGUNDELE:
Ko si nnkan to jo bee rara, kii se lati fi pin ipo. Ipade naa waye pe ki a le
so ara wa di okan soso ninu egbe oselu PDP. Ko nii si wi pe enikan n se ti GNI,
tabi Adebutu tabi Paseda, tabi Yayi, tabi awon min in, sugbon pe ki gbogbo le
sowopo lati di okan soso. Ti a ba fee le ogbeni oni fila gogoro kuro, gbogbo wa
gbodo parapo di okan. Nnkan tipade naa da le lori ni yen.
AWIKONKO:
Ki waa ni abayori ipade naa bayii. Se e ti joo gba lati sise papo ni?
OGUNDELE:
Ibi ti a yori e si bayii, ti a si ti gba nipe ki a gbe ti apoti gbigbe tabi ipo
ti won ba fee du lodun 2019 sile naa fungba die lati le jo to egbe yi papo, emi
ni mo mu aba naa wa gege bi ero okan mi, ti mo si gba pe gbogbo won lo fowo
sii. Leyin yen ki gbogbo eni to ba fee gbe apoti maa bo lati waa gbe.
AWIKONKO:
Bi a se n soro yi ni GNI si n so pe omo egbe oselu PDP loun, to si fee dupo
gomina.
OGUNDELE:
Enikeni lo lee jade lati dupo to ba wuu. Onikaluku lo ni anfaani lati jade dupo
gege bi omo egbe oselu, ti won si gbodo gba foomu. Gbogbo omo Naijiria tojo ori
won ti de ipele to ye lo leto labe ofin lati gbe apoti ipo gomina tabi eyi to
ba wu won. gbogbo eeyan ni nnkan ire wun. Gboyega Isiaka ko ti waa ba wa lati
so pe oun tun fee jade.
AWIKONKO:
Lati nnkan bi odun meloo kan seyin lawon Yewa ti n so pe awon ni ipo Gomina
kan, sugbon laipe yi Gomina Amosun so pe inu egbe oun loun ti fee mu Gomina
jade. Kini igbese egbe oselu PDP gege bi alaga?
OGUNDELE:
Gege bi egbe oselu PDP se duro, awa o le duro lori i pe eni kan ni ko loo mu
gomina wa. Enikeni lo lee loun fee jade. Ki baa je Yibo, ti o ba ti le waako,
tabi figagbaga pelu gbogbo awon to fee dibo, ko si wahala nitori pe ko si ninu
ofin egbe wi pe ibi bayii lo kan, ibi bayii lo gbodo lo. Lati bii odun 2011 ni
won ti so pe Yewa lo kan, a si gbiyanju pe ki Yewa se e, sugbon igba ti a rii
pe ti ba di Ijebu ati Egba lowo mu pe Yewa lo kan, o maa n da wahala ati
ariyanjiyan sile ninu egbe la fi woo pe gbogbo eni to ba loun fee jade, ki won
maa bo. Titi di bi a se n soro yi, enikan to loun fee jade ninu egbe PDP, to si
foju han ni Ladi Adebutu, omo Baba Ijebu to wa lati Ijebu. Ilekun si sile fun
gbogbo eni to ba loun fee gbe apoti idibo.
AWIKONKO:
A gbo pe wole-wode, iyen ajosepo labele ti n waye laarin egbe oselu PDP ati
Labour Party nipinle Ogun. Se ka gba pe aheso ni abi bawo lo se je?
OGUNDELE:
Gege bi mo se so leekan pe igi kan o le dagbose. Gege bi oloselu to ni opolo bi
emi, oun lo je ka joko lati woo pe awon egbe oselu kekeeke kan naa wa bii labour
Party, UPN, HOPE atawon egbe oselu miran bii meedogun, gbogbo won lo si ti gba
lati darapo mo wa, ki a le jo sise papo. Kii se egbe oselu Labour nikan
AWIKONKO:
Ki lo maa wa je gege bi anfaani fawon omo egbe yi?
OGUNDELE:
Ti a ba de ibi ta a n lo, a a mo nkan to kan, iyen ni pe ti a ba dori afara, a
maa mo bi a se maa fo. Awon anfaani orisirisi wa fun won. o dara pupo keeyan je
omoleyin egbe to wole ju ko je alaga egbe ti ko wole lo.
AWIKONKO:
A gbo pe ipade nla (congress) kan fee
waye lojo Satide to m bo yi, sugbon awon omo egbe bii Buruji Kashamu atawon kan
ko si ninu awon ti e fiwe pe lati wa nibe. Se won kii se omo egbe mo ni abi ki
lo faa?
OGUNDELE:
Okunkun ati imole ko le joo se papo, won o si le pade, ko seese. Oro Buruji
Kashamu atawon eeyan je omo egbe to je pe ero okan won ko ba ti wa mu. Ero okan
ti wa ni pe ka dibo, ka si wole. Ero okan ti won ni pe ki won gbowo lowo otun,
osi, oludije, egbe A, egbe B, okoowo (Business) lawon fi n se; awa si n fe ka
dibo, ka wole ibo. Iyato to wa laarin wa ni yen. A ti ri apeere eyi to sele
nipinle Ondo nigba ti Jimoh Ibrahim dide, to je oludije egbe ti Kashamu, to ni
kii se pe oun fee wole, sug bon oun kan mon on mo pe koun da egbe ru. Nnkan to
sele l’Ondo naa lo sele l’Edo. Won maa n korin kan pe “agaga ri ga, aarun to semi leekan ko tun semi mo, agaaga ri ga".
Egbe ti won ati ti wa, okunkun ati imole ni. Ero wa o papo, nitori e la se so
pe ki won lo ro kunle ninu egbe PDP. A ti so o lati inu osu keje to koja, ti a
si tun ti gbe igbese min in bayii, ti a si gbo pe won ti n lo sinu egbe Mega.
AWIKONKO:
Iru awon igbese wo ni?
OGUNDELE:
a ti ni ki won loo ro kunle, a o tii so pe a le won kuro ninu egbe nitori pe
agbara wa ko ni ka le won kuro ninu egbe. Agbara wa le so fun won wipe ki won
loo sinmi fungba die digba ti won maa fi se idajo fun won. Iru eni ti won n pe
ni Bayo Dayo, agbara wa ka lati so pe ko loo jokoo sile, o si nibi ti a daa
duro sii (suspension).
AWIKONKO:
Otungba Gbenga Daniel so laipe yi pe ti won baa pin egbe oselu PDP si
Southwest, oun se tan lati jade dupo alaga. Gege bi alaga egbe yi nipinle Ogun,
nje, OGD kaju e, ati pe se e se tan lati fowosowopo pelu e?
OGUNDELE:
A ti ba Otunba Gbenga Daniel sise ri, ti a si ti jo se wole-wode. A mo bi opolo
won se kun to lati le eto ilu ati eto egbe. Ti won ba fun OGD laye, awa ti a wa
nipinle ogun se tan lati gbaruku ti won. awon ipinle to ba ku naa, a maa sise
oselu lara won lati le sise fun Otunba Gbenga Daniel. OGD je gege bi eni ti a
le fowo soya le lori pe o ni eto, ogbon ati oye to le fi tuko egbe nitori pe se
loo tuko ilu yii daadaa ju ti eni to wa nibe yi lo.
AWIKONKO:
Nibo ni igbese lati gba ileese yin pada de duro. Igba wo le fee pada sibe?
OGUNDELE:
Awon to wa nibe, nigba ti won maa gba ibe, won paayan, won fo awon eeyan lori.
Ara awon nnkan tawon araalu si fi n wo wa niyen pe egbe PDP, egbe oni
jagidijagan ni, ti ko si ri bee. Ni se la fee fi eegun otolo too nitori pe pupo
ninu awon to ko ara won jo sibe, a si le rii eyi to si le ronu piwada ninu won.
a o setan lati loo fagidi gba ileese wa, a fe kawon agbofinro sise won. a ti
fun won ni leta, to ba si to asiko ti won maa lo, won a lo se e. Secretariat ko
ni koko nnkan t’oloselu fi n wole ibo. A o fe itajesile, bawon se gba a lowo
awon to n lo, to je pe se ni won ta eje sile, awa o fe se be e nitori pe a
kawe. A o gbodo ba obo jawura. Mo gbagbo pe ki osu yi too jale, won maa ko
gbogbo eru won.ws
AWIKONKO:
Ni ti owo ti Gomina Amosun loun fee ya lowo Banki agbaye, ti won maa fi ogbon
odun da pada. Ki ni nnkan ti e ri sii?
OGUNDELE:
Ijoba yi ati awon to n seto ijoba ipinle Ogun lonii, ogbon ori won ko kun to,
won o ni opolo ti won le fi da owo yen pada. Won o ni opolo ti won lee fi se
isuna na owo to le je ki won ni idaniloju lati le fun won lowo yen ati ireti pe
won a ri owo yen san pada. Gbogbo ilu lo mo pe ijoba ti won n se l’ogun lonii,
ijoba odaju ni, ijoba ojale onile bo ti e ni, ijoba ika ni. Tori e ni ko se si
eni to fee so pe awon fee bawon ni nnkan se papo, paapaa to ba ti jo mo eto
isuna owo, ka ya ara eni lowo, nitori won ti mo pe ijoba ti o too gbarale,
teeyan o nidaniloju lori e pe bi a ba fun won ni toro, won le soo di sisi.
Ijoba won ko yato si apa toro da nai nu.
AWIKONKO:
Orin agaga ri ga ti e ko, ona wo le fee gba lati ma je ki aarun yi tun jeyo mo?
OGUNDELE:
Ninu eto oselu, ti won ba fi aarun yen kan eeyan lodun yi, nkan ti eto oselu so
ni pe ki a ni suuru digba ibo min in, ti iya yen ba ka yin lara daadaa, ti
akoko idibo min in ba de, eo ni dibo fun won. nkan ti orin naa tunmo si niyen,
teeyan a si duuro digbi pe oun ko nii gba ki aarun naa tun pada se oun mo. Ti
iya yen ko baa tii dun un yan, ko, won a tun dibo fun won. gbogbo wa la mo pe
egbe APC, egbe eletan, ole, jaguda, jegudujera, aladanikanje, tara eni nikan
ni. Won tan araalu lati gba ibo araalu ni. Araalu ti wa rii pe won o kaju
osuwon rara. Eni to ba loun fee loo dibo fun egbe oselu APC niisiyin, o gbodo
koko wo iye ti won nta jala eepo bentiroolu nigba ijoba PDP ati niisinyi ti APC
n se lowo; won a tun wo iye ti won se owo dola.
Gbogbo nkan taa n ra pata lo ti gbowo lori, ti won si tan awon araalu pe awon a dogun, awon a dogbon fun won. gbogbo wa la ti rii pe bo se wa loke, lo wa laarin, bee naa lo wa nisale patapata ti won pe nijoba ibile. Tijoba ibile yen lo tun waa lagbara ju nitori pe se lo dabii pe won pare. Se lo dabii pe Ogbeni Amosun fi etaanu, ibinu okan, imo tara eni nikan, tenbelekun ati iwa o pa tooro da nai nu lo fi pa ijoba ibile run. Bi se n baa yin soro yi, ko si alaga ijoba ibile kan to le ri nkan kan gbe se. Gbogbo eeyan lo n wo won bayii, ti won n fi won rerin. Mo le fi gbogbo enu so o pe pupo lara awon omoleyin Osoba ni won ti darapo mo wa, bo se ye ki won darapo mo wa ni won se darapo. Orisirisi ona lawon eeyan fi n darapo, eeyan le wa ninu egbe ANPP, ko si darapo awon to wa ninu egbe APC, egbe APC gan an ko se maa daruko mo bayii nitori pe kii segbe oselu gidi. Egbe to je pe etan ni won fi koo jo ni. Ile taa ba si fito mo, iri lo maa wo danu. Ipinu won lasan ni pe won fee le egbe oselu PDP kuro lori ipo, leyin yen, ko si nkan min in mo. Olori egbe won lonii bayii gege bi Gomina Fayose se ti so kidibo too waye lodun 2015 pe eni toun n wo yi ko le sejoba to ba wole, awon nnkan to si so nigba yen lo ti n fara han bayii. Ao ri aare orileede nilu mo, sugbon a ni adele to je omo Yoruba, Olorun lo se tawon Hausa bee.

Ni soki, e se igbelewon Gomina Amosun laarin bi odun mefa aabo to ti lori ipo.
Nje awon eeyan ti ri eko ko?
OGUNDELE:
E see. Se erii, taa ba fee soro Amosun, a maa so lonii, a a dola. Mo ti so o,
mo tun fee tun un so, ijoba o pa tooro da nai nu ni. Ijoba odaju, ijoba talo
maa mu mi, ijoba bamubamu ni mo yo mi o mo bo ya ebi n pa omo eni kookan, ijoba
tinu mi ni maa se nijoba ti Amosun n se l’Ogun. Ti a ba ni gbe Amosun sori
iwon, ko le gbewon rara. Ti e ba wo nnkan ti won n pe ni Popularity Graphic Chart, Amosun ti ja sile patapata. Mi o
ro pe eegun Amosun kan tun le seri mo ninu oro eto oselu nipinle Ogun nitori pe
araale ahun Amosun ko gbadun ahun, ahun Amosun funra e ko gbadun ara e. e lo
saarin awon omo egbe Amosun, emi naa se alaga ijoba ibile n’Ifo rii, a rii nkan
ti a ti fun araalu, a si ri nkan taa se fun ara wa atawon eeyan.
Arise la ri ka, arika ni baba iregun. Ko si eni kan soso ninu awon alaga yen to le so pe oun tun fee lo teka fun Gomina Amosun mo tabi pe eni to ba tun faa sile loun maa lo teka fun un. Ijoba to je pe se lo gbe eto eko, eto ogbin, eto ilera ti segbe kan, kii se pe won fi se ona, eni to ba so fun un yin pe ona ni won fi se, iro lo n pa fun un yin. Kii se pe won n se ona, won kan n se waon ona wa leso ni, won n je kawon ona wa rewa, ko dun un wo loju nitori pe gbogbo nkan ti won gbe soke ni milionu naira yen, ti won ba gbe e sile ni milionu naira, nkan kan naa lo maa se. won kan n se ona wa loge lasan ni, ise ifonasoge lasan lo n se e bilionu lona bilionu owo aagun omo ipinle Ogun.
Taa ba wo ajosepo to wa laarin awon osise, ko dan monran, nitori pe won o ri owo osu won gba lasiko. Ipinle Ogun nigba ijoba Osoba, ipinle awon osise ijoba ni won n pe e nitori pe won n ri owo osu won gba nipari osu, won si n gba lekunrere, won n mu owo won loo fi ra oja l’oja. Owo ti won n gba losu lo n bo sowo awon oloja. Nigba ti Otunba Gbenga Daniel de, o so o din la, o pe awon olusowo lati waa da ileese nla-nla sile towo si n wole daadaa. Nigba ti Ogbeni oni fila gogoro de be, ni se lo mu wa pada si leyin-lleyin tigba Osoba, idi niyii tawon osise ko fi rowo osu won gba ti won le so pe awon fee lo fi ra oja l’oja, tawon ara oja le fi so pe awon n je anfaani ijoba. Ise ti won ni won n se, ni se ni won loo gbe fawon ajoji, tawon yen ba ti gba owo, won n ko lo silu ti won ti wa. Ise ti won si n se yi, ko fara han ninu local economy ipinle Ogun, gbogbo e kan se samura ni.

No comments:
Post a Comment