Francis atawon ore e to lu awon Fulani lalubami dero atimole - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 25, 2017

Francis atawon ore e to lu awon Fulani lalubami dero atimole

Beeyan ba ri awon ogbologbo adigunjale merin towo olopaa ipinle Ogun te niluu Ofada nijoba ibile Obafemi Owode ipinle naa lojo Abameta Satide ijerin bi won se n wo pakopako yoo ro pe awon odaran naa ko le pa esinsin lai mo pe iwa buruku owo won ju ti paramole lo. 

Madu Abuchi, Onyeka Okafor, Francis Onyeka ati Hafiz Mustapha lawon mereerin ti won ni won ko fawon ara Ofada lokan bale,  ti won n fojoojumo yo won lenu losan ati loru. 

Gege b’AWIKONKO se gbo, ni nnkan bi aago kan oru ojo naa lakara won tu sepo, towo olopaa te won leyin tawon araalu loo foro won to awon agbofinro leti. 

AWIKONKO gbo pe lai pe yi lawon eeyan naa loo ja awon Fulani meji kan, Muhammed Ruga ati Babuga lole maalu meji, ti won ni won se awon Fulani naa basubasu ki won too salo. 
Won ni se ni won so awon Fulani naa lapa atese, ti won tun sa won lada ki won too salo pelu maalu nla meji. Leyin isele naa ni won loo foro naa to awon olopaa leti, ti won si bere igbese lati mu won bale. 

Ohun taa gbo ni pe lakoko ti won tun fee lo jawon kan lole ni Orile Igbehin nitosi Ofada gege bi ise won ni won lowo palaba won segi, to won si ri won mu. 

Tesan olopaa ni won ni won tun ti jewo pe kii se maalu nikan no won ji gbe, won lawon tun maa n ja tirela simenti gba lowo awon awako ileese simenti. 

Okunrin kan to n je Femi, eni ti won loo nile ni Sagamu ati Itori lo maa n ra awon eru ole lowo awon, bo tile je pe Femi naa ti na papa bora leyin tiroyin kan si pe asiri won ti tu. 

Lara awon nnkan ti won ri gba lowo won ni Okada Bajaj tuntun ti ko ni nomba, ada meta, obe eran, okun, irin, beliti awon sikioriti, atawon ero ibanisoro lorisirisi. 

Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti pase pe kawon olopaa FSARS maa ko won lo lati tesiwaju ninu iwadii won, ki won si rii daju pe owo won te Femi. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI