Odo-eran Bodija; Nnkan nla n sele nibe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 25, 2017

Odo-eran Bodija; Nnkan nla n sele nibe

Ilu nla n'Ibadan, ilu isembaye t'itan re daa pupo ni, ko seni je f'Ibadan sere. Ibadan nilu keta to tobi ju lorile-ede yii, awon eeyan to n gbenu re lowo yii to milionu meta. Bo tile je pe ile Yoruba ni, sibe kaakiri lati ri awon eya lorisi ti won tedo sibe, ti won n fibe sebugbe.

Baa se lawon Kristeni la ni awon musulumi, ti won jo n gbe po lalaafia. Ibe naa laduugbo ti won n pe ni Bodija wa. Bodija je agbegbe kara-kata bee lawon eeyan n gbebe. O tun je okan ninu awon oja to tobi ju nipinle naa. Inu Bodija yii kan naa lodo-eran wa, odo eran yii je okan ninu awon odo to gbajumo gidi, ti awon alapata atawon to n sowo eran ko fi sere.   
 
Eran je ohun tawon eeyan feran, awon elesin ati eleya lo n gbadun e. Sugbon t'Ibadan yato, sasa nibi te e maa lo, te o ni awon ile onje bii buka, tee ma ba orisi onje pade, bii; amala, eba, ati iyan pelu awon obe lorisirisii atawon eran ogunfe, eran igbe, eran maalu ati bee bee lo. Iyanilenu ni pe ko si bi ile olonje naa se le bo si koro to, sasa eeyan le o ni ri nibe. Awon oloselu, onisowo nla, atawon eeyan to ku die kaato fun. Awon eya eran bii; inu-eran, fuku, edo, okan, abodi atawon eya ara eran maalu tabi ewure le ma ba ninu obe won. Ohun t'Ibadan fi n salejo niyen. Ohun abuku ni k'Ibadan ma feran jeun. 

Opo awon ara Ibadan ti won feran eran yii, odo eran Bodija ni won ti n ri i ra. Odo eran ohun ko si ju irin iseju meji si ogba ileewe giga Ibadan, iyen Yunifasiti tiluu Ibadan lo, bee naa ni ko je irin iseju marun-un si ogba ileese ijoba Oyo lo. O je ohun to yanilenu, ti ko se e gbagbo pe iru odo eran Bodija yii, to je ibe ni gbogbo awon taa daruko yii; ti n ra eran ti won n je senu. Ko se e gbo seti paapaa. Odo eran Bodija je odo eran kan ti alaafia, ilera ati ohun amayederun jinna si pupo-pupo, kii se ohun to bojumu rara.     

...Ohun to n sele lodo eran Bodija

ko sohun amayederun nibe
Ko sohun to n sise lodo eran Bodija. Ohun amayederun atijo ti won ti se latodun 1986 ti won ti da a sile naa ni won si n lo. Ko seni to ronu ati fowo tun un se, gbogbo re lo si ti fee denukole tan. Eedegbeta eeyan lo n sise nibe lojoojumo. 

Idoti, eje, igbonse
Opo awon idoti ati egbin to n jade lara eran la maa ba pade lodo, awon nnkan bii eje eran, igbe eran, omi ara eran, atawon idoti inu eran. Bi awon alapata Bodija ti n ko awon idoti yii jade lara eran, dipo ki won seto bi won ti maa da won nu, lona imototo, seni won a ko gbogbo idoti naa soju kan, ibe naa ni won ti n pa eran ti won si ti n fo o, ibe naa ni won ko awon idoti yii si. Idoti tawon alapata ba sesi da sinu koto idaminu, se lawon idoti yii, lopo igba, maa n loo di gota, ko kuku seni to n bojuto o. Bee debe, egbelegbe esinsin lo ma ki yin kaabo. Inu omi idoti gota, ti ko san lo yii naa lawon alapata ti maa n fo eran ti won fee ta loja. Iwa obun gba a leyi. Bi won ba jaja gbiyanju, ti won ko idoti jade kuro ninu koto idaminu, iwaju odo ni won maa n ko gbogbo idoti ti won ko jade si, bee lawon kan si maa n fi ori akitan idoti eran yii sele igbonse won. Oorun idoti eran ati teeyan to maa n jade latori akitan ko kere. Ewu nla ni fawon to feran eran. 

ko seni to n ye eran ti won n pa wo
Ohun to tun ba ajao odo Bodija je ni pe ko si alabojuto fawon eran lodo. Ise tiwon ni lati bojuto awon eran ti won ko wo odo, lati yewo boya eran teeyan le pa je ni, paapaa awon nnkan inu eran naa. Sugbon ni Bodija, fun bii odun meji bayii, ko seni kan to n ye eran ibe wo. Awon oluyewo mewaa pere lo n sise nibe, awon alapata si le leedegbeta sugbon ojoojumo nija maa n sere laarin won. Idi ni pe ohun to ba mu ki oluyewo fi so pe eran kan ko to fun pipa, gbese de falapata niyen. Nitori naa, ogbon ni won fi n bara won lo. A gbo pe ileese aladaani kan ti ko odo eran mi-in si ibomi-i. Odun 2014 la gbo pe won ti ko o, ohun amayederun tawon alapata atawon oluyewo nilo lo ti wa nibe, ibe ni won fee fi tipa ko awon alapata Bodija lo, baa ti gbo. Sugbon titi di asiko yii, se lawon alapata yari, gbogbo igbiyanju awon agbofinro lati le won kuro ni Bodija lo ja si pabo. 

Awon eran to larun lara ni won n pa
Iwa aibikita ati iwa obun po lodo, bii; pipa eran temi ti fee bo lenu e, abi awon eran to ti ku fun tita. Tita awon eran to larun lara, awon arun bii iko awubi. Ka maa fo eran ninu omi idoti abi omi eje, igbonse nitosi odo nibi ti won ti n pa eran. Ka maa jeun nitosi odo, ka maa da ile sibi aito ati ka maa ta awon omo inu maalu tabi eran to ti ku. Awon alapata kan maa ge ibi eran ti arun wa lara re, won a ju u senu, ohun ti won n se ni lati mu u da awon onibaara won loju pe ko sewu loko! Orisi awon iwa odaran lo tun n joba lawon agbegbe yii, awon iwa bii ise asewo, awon to n loogun oloro, ko si eto ilera kan to dan moran nibe. Awon nnkan wonyi lo n sakoba fun eto ilera awon araalu. 

Ero repete lodo eran
Ohun to tun ye ka kiyesi ninu oro yii ni aibowo fun ofin ati bi ko se si eto to peye lodo. Onikaluku kan n se eyi to wu u ni. Ojoojumo lawon ero maa n wo witiwiti nibe, onikaluku pelu obe ti won fi n peran lowo. Eni ti o ba mo bo ti ye ko rin, to rin gbere-gbere, se ni won ma ti i kuro lona. Bakan naa la tun gbo pe awon alapata kan maa n fun awon eran won ni igbo mu, enikeni to ba duro sona tiru eran bee ba n bo lodo, inu ewu nla lo wa. Ohun la se maa n ri tawon elomii ma subu lule, nibi ti won ti n sa feran, elomi si maa n gbe apa lo sile. 

Ko somi nibe rara
Ohun kosemani loro omi je fun awon odo eran, nitori awon idoti to n ti ara eran jade ti won nilati fo danu, sugbon oro Bodija ko ri bee rara. Ko somi nibe rara, laipe yii lawon alapata sese da ogbon si i, ti won gbe kanga. Kanga ohun kii se eyi to dun un wo loju, nitori a gbo pe se lawon kan maa n se igbonse ninu kanga ohun. 

Ki la fee se si o?
Awon iwa aibikita, iwa obun lodo eran Bodija yii lo n mu ka bi ara leere awon oro kan. Bodija nikan si ko niru awon iwa obun yii ti n sele, bo se wa kaakiri orile-ede yii niyen. O ye ka beere lowo ara wa - Ki lohun taa n je lara eran wa gan-an na? Ipa wo lohun ta n je n ko lara ilera wa? Se odo eran to wa laduugbo wa se e wo loju abi iru ti Bodija naa ni? Ki la le se si i? Bawo la se le daabo bo ara wa kuro ninu iwa obun to le mu arun ati aisan wa fun wa yii? O tun ye ka beere ohun tijoba n se lati satunse awon odo-eran wa, ki lawon ijoba atawon alenu-loro nipa eto ilera le se lati daabobo eto ilera wa, gbogbo nnkan wonyi lo gbodo lesi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI