Soja to gun olokada pa l’Agbado ti dero tesan olopaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, August 14, 2017

Soja to gun olokada pa l’Agbado ti dero tesan olopaa

Kani awon olopaa lo iseju kan sii ki won too gbera lakoko tawon olokada agbegbe Agbado nipinle Ogun loo fejo odomokunrin soja kan, Abiola Odedeji sun won pe o ti seku pa okan lara won toruko e n je Niyi James, o seese ko ti na papa bora, ko si ti muu je bayii.

Bawon araalu to gbo sisele naa, to si n ya won lenu ni won n so pe afi ki won foju e bale ejo, ki won si sedajo iku fun un, nitori iwa odaju to hu lojo naa. Ni nnkan bi aago meta aabo osan ojo Tosde ose to koja la gbo pe isele naa waye.

Gege bi AWIKONKO se gbo, won ni Abiola loo ki orebinirin e kan, Amada David lagbegbe Agbado, asiko to n pada bo ni won loo da Niyi, eni ti won tun n pe ni Emi-Ero duro pe ko ba oun gbe ore oun, Damilare Oni ti won jo lo sibe lo si Ijaye nipinle Ekoo.

Lesekese ni won so pe Niyi so pe oun ko le lo nitori pe oun ko niwe ase tikeeti okada lati sise de ipinle Eko, eyi ni won loo bi Abiola ninu pe olokada koro soun lenu, to si fo eti e pe bi ko ba ti e beru oun, se ko ye ko beru aso soja to wa lorun oun.

Won nibi ti Niyi ti n fe maa bebe pe ko pe olokada min in, lo ti fa koboko yo, ti bere sii fi na pe oun loun fe ko gbee lo, sugbon to n so pe ko ma binu. Sugbon kaka ki Abiola wa olokada min in, ko fi Niyi sile ko maa ba ti e lo, nise lo tun yo obe jade lapo, to fi gun un.

Opo awon toro naa soju won ni won ko le summon on be nitori ti won so pe won beru soja, sugbon nigba ti won rii pe Abiola ti n gun Niyi ti won lomo Ikogosi ni nipinle Ekiti lobe, lo je kawon kan ninu awon olokada naa gba tesan olopaa lati loo fejo sun won.

AWIKONKO gbo pe kawon to lo tesan too de pelu olopaa, Abiola ti salo pelu ore e nigba ti won rii pe emi ti fee bo lara Niyi, sugbon awon to mogba ti won lo ni won juwe ibi ti won gba fun won, tawon naa si teko won leti lati le won mu.

Okan lara awon tisele naa soju e, Akinjobi nigba to n soro so pe “Ookan ni mo wa ti mo n wo nkan to n sele. Soja yen da olokada duro, sugbon iyen so fun un pe oun ko ni tikeeti to le de Ijaiye. Inu bii gan pe o koro sii lenu. Ibi I won ti n fa oro naa lo ti yo koboko jade to si fi n na.

“Ko pe lo tun fa obey o, to n fi gun lara. Pelu erin lo tun fi eje to wa lara obe yen nu ori Niyi olokada yi. O laimoye eeyan loun ti pa danu, ti ko si si nkan ti won le foun se. ibe loun ati ore e ti gbe okada ayarabiasa, ti won salo.”

Bee la gbo pe Amada ti won wa wa naa gbe okada min in salo. Bo tile je pe oun taa gbo ni pe Amada lo ranse pe Abiola lati waa lo ba oun hale mo eni kan to je oun lowo, ti ko fee san foun.

Bawon olopaa se debi isele naa ti won gbo pe won ti salo lawon naa ti tele won. agbegbe Clem n’Ijaiye ni won ti mu David, oun lo so fun won ibi ti Abiola gba, ki won to ri oun naa mu lagbegbe Masalasi.

Awon eeyan ni won sare gbe Niyi lo sileewosan ijoba Ifako-Ijaiye lati toju e, sugbon iyalenu lo je pe ko ju bii ogbon iseju lo ti won de be ni Niyi dagbere faye, nitori ti won so pe eje to da lara e ti po ju ki won too gbe e debe.

AWIKONKO gbo pe okan lara awon soja ti won ko lo lati loo koju awon Boko Haram nipinle Borno ni Abiola, nigba ti ore e, David wa nipinle Bauchi
Kolawole Jame, to je egbon Niyi nigba to n fomije soro lojo Fraide so pe ibanuje nla niku Niyi je fun molebi awon nitori pe oun lo n gbo bukata gbogbo ebi. O ni irole ojo Tosde ni ranse pe oun pe Niyi nijamba, to si po gan an.

Ninu oro e “Eni kan lo pe mi pe aburo mi Niyi nijambamoto, o si po gan an, mi o le fi ibi ti mo wa sile nitori nkan ti mo n se nibe. Igba ti mo maa debe lojo keji, ni won so pe won ti gbe e lo si jenera to wa Ifako-Ijaiye, ti mo si sare lo.

“Bi mo se de be ti mo salaye nkan ti mo ba wa ni won je ko ye mi pe aburo mi ti ku. Se loro naa dabi ala leti mi. Niyi lo n gbo bukata ebi nitori pe ko tii niyawo, bee ko si tii bimo. Ibanuje ati adanu nla niku e fun wa ninu ebi.

Okunrin naa loun loun mu Niyi kuro loko lodun mejo seyin nigba toun lo gbe l’Akure, ko pe to fi wa s’Ekoo. O so pe afi ki won foju Abiola toba aburo oun ba ile ejo nitoti pe iwa odaju lo hu, to si dawon loro ninu ebi won.

Agbenuso ileese olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe Abiola ti wa ni Eleweran lodo eka olopaa to n ri soro awon apaayan. O lawon ti foro naa to ileese soja leti lati fi iya to to je e. o loun mo pe laipe, abiola yoo foju winna ofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI