Pasito Kehinde ni Olorun ko lo pe oun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, August 14, 2017

Pasito Kehinde ni Olorun ko lo pe oun

Okunrin kan eni odun mejilelaadota,Kehinde Onayiga to pe ara e ni Wolii ti so pe kawon eeyan maa pe oun niranse Olorun, nitori Esu loun sise fun un, boya si ni oun le ri idariji gba lati odo Olorun.
 
Lojobo Tosde ose to koja, lawon olopaa safihan okunrin yii peluu Musiliu Jubril lori esun pe won ji omobinrin, omo odun mokanla gbe ti won ko si ti ri omo naa titi di akoko yii.

Gege bi AWIKONKO ti gbo niluu Sagamu lowo ti te awon eeyan naa, iwadii fi ye wa pe Odomokunrin to n gbe lodo Pasito yii lowo koko te lori esun omo ti won ji gbe naa.

Oun lo wa ni kawon olopaa se oun jeje,nitori pe Wolii Kehinde lo ran oun nise pe ki oun ba oun wa omobinrin ti ko ba ti balaga wa, oun fee fi sise fawon omo yahoo ti won je onibara oun.

Musiliu naa lakoko to n ba oniroyin wa soro ni Eleweran lose to koja naa tun jewoo pe ise birikila loun se, ati pe soosi Wolii Kehinde loun loo, o ni bo se be oun nise naa, to si seleri foun pe oun yoo foun ni egberun lona ogun naira, lo je koun tete jara mo.

O tun salaye pe omobinrin kan tawon jo n gbe loun dogbon ni ko sin oun loo sinu oko, oun fee loo ko igi, boun se tan omo naa loo sodo Wolii naa niyen, toun ko si mo nnkan to fomo naa se.

Nigba tasiri tu tawon olopaa mu oun loun jewoo pe Wolii Kehinde lo be oun nise naa Sugbon Wolii naa so pe iro ni eni naa pa mo oun, loooto lo so pe oun mo on ri, o ni omo iya ijo oun ni, odo oun lo si n gbe.

Bakan naa lo tun so pe nnkan to ba oro naa je ati pe Olorun to fee tu asiri oun ni awon ogun abenugangan toun fi sise wolii oun, ti won ba nile oun. O ni o ti to bi odun metadinlogun toun ti di Wolii toun si ni soosi Kerubu ati Serafu, Agbo Jesu to n dari, peluu awon ogun to n loo naa.

Se ni Kehinde tun jewo pe Alfaa kan ni Sagamu toun ti koko wa lodo e,koun to di igbagbo osan gangan loun ti gba awon ogun dudu toun lo yii, o si ti pe toun ti n loo.

O so pe peluu gbogbo nnkan to sele yii, oun mo pe Olorun ko lo pe oun.Ni bayii, Komisanna awon olopaa nipinle Ogun,Illiyasu Ahmed ti so pe nigba tawon yoo ba fi pari iwadii awon,Wolii atomo eyin e yii, yoo jewoo ibi ti won gbomo naa pamo si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI