"E dakun e se wa
jeje" loro ebe to n jade lenu awon odaju abiyamo meji kan, Nasiru Adeyemo
atiyawo e, Idayat Adeyemo ti won ni won fee fomo won, Abibat Abike
Adeyemo seso lago olopaa to wa ni Eleweran niluu Abeokuta lojo Aje Monde ose to
koja.
Bawon araadugbo to
gbo sisele naa se n fepe ranse soko atiyawo naa, bee lawon kan tun n so pe ori
omo yi, ti won loo sese pe omodun meje ko gbabodi lo je ki won loo gbe e
ju sinu igbo.
Gege b'AWIKONKO se
gbo, won losan ojo Sannde ose to koja lawon araadugbo Asabala loju ona
Papalanto siluu Sagamu sakiye apo saka kan to n min legbe titi, eyi to fee ko
iberubojo bawon eeyan.
Bo tile je pe eranko
ni won koko ro pe won di sinu apo naa tele, sugbon igba ti won tuu,
to won rii pe eeyan lo wa nibe, anjoonu lawon kan tun ro bii. Eyi
lo faa ti won ni won fi ranse sawon agbaagba atawon odo to laya ladugbo lati
waa ba won wo nnkan to wa ninu apo naa.
Ninu oro ti okan lara
awon araadugbo naa to b'AWIKONKO so lori aago laaro ojo Isegun Tusde to koja
yi, eni to ni ka foruko boun lasiri naa so pe obinrin kan to n koja lo
laaro ojo naa lo sakiyesi apo saka naa, to si fi to awon eeyan
leti.
Eni naa je ko ye wa
pe lati ojo Eti Fraide ose to lo lohun ni apo naa ti wa nibe, sugbon
tawon eeyan ko fura pe eeyan ni won di sinu e.
O so pe ero
okan opo awon eeyan to n koja legbe e ni pe ile lasan ni won di sinu nitori pe
se lawon eeyan maa n di ile sinu apo, ti won a si gbe segbe titi fawon to
n ko ile lati gbe e lo danu.
Awon ti won mo omo
naa lo so pe awon mo awon obi e, ati pe isele naa ko le seyin won, eyi lo faa
ti won loo fi mu awon mejeeji nile lati for wa won lenu wo.
Bee ni enikan toro
naa tun soju e so pe iyalenu lo je pe eeyan lawon ri ninu apo tawon ro pe ile
lasan lo wa ninu e.
Ninu oro Obinrin naa,
o so pe "Lati ojo Fraide ni apo yi ti wa nibe, ero okan awon to n
gba egbe e koja ni won ro pe ile lo wa ninu e. Igba tenikan to n koja loo
tii le apo naa n min, lo fi pakiyesi awon eeyan si i.
"Eranko bi aja
tabi ewure la koko ro pe o wa ninu e. Awon odo ni won tu u to won si rii pe omo
kekere lo wa ninu e. Aya wa ti ja, anjoonu la koko pe, sugbon bomo
b naa se n se lo je ki won mo pe eeyan gidi ni."
Ninu oro ti won ni
Abibat so lo ti je ki won mo pe baba oun atiyawo e ni won ge okan ninu ika owo
oun
O tesiwaju pe
lesekese lawon to da omo naa mo ti loo ranse le awon obi e lati wa won nnkan ti
won, sugbon iyalenu lo je pe bawon eeyan naa se se lo je ki won fura si
won pe ko seyin won.
Eyi lo faa ti won fi
woo won lo siwaju awon agbaagba pe ki won so tenu won, nibe ni won si ti jewoo
pe Ki won se awon jeje nitori pe ise esu ni.
Won ni se lawon
mejeeji tun bere sii tako ara won nigba ti Nasiru so pe iyawo oun lo ni kawon
loo fomo naa seso, sugbon nigba ti won rii pe ori e ko gbabodi lo je
kawon di sinu apo, ko le tete ku.
Idayat so pe iro lo
pa moun nitori pe oun ko mo ile babalawo kankan to le mu koun so pe kawon loo
fomo naa soogun owo.
Loju ese ni won so pe
won ti loo fa won le awon olopaa Owode Egba lowo lati fese ofin too. Ko pe ti
won fi gbe awon mejeeji de tesan ni komisana olopaa ti pase pe ki won maa ko
won bo ni Eleweran.
Bawon kan tun se n so pe iya
Abike ti ko Nasiru sile lati nnkan bi odun meta seyin, bee lawon kan n so
pe Obinrin naa ti dagbere faye sugbon ti a ko tii le fidi e mule titi di asiko
ti a n sakojopo Iroyin yi.
AWIKONKO gbo pe awon eleyinju
aanu ni won gbe Abike lo si osibitu ti won loo ti n gba itoju titi di asiko ti
an sakojopo Iroyin yii lowo.
Ni bayii, komisana
olopaa, Ahmed Iliyasu ti tare won sodo eka olopaa to n ri soro ajinigbe ati
egbe okunkun lati tubo foro wa won lenu wo, bee lo so pe a fi kawon
mejeeji foju bale ejo.
No comments:
Post a Comment