Ilumooka sorosoro
ori redio kan to filuu Abeokuta sebugbe, Oloye Sande ogunsola tawon eeyan tun
mo si Tantala ti soro, o pariwo sita pe kawon eeyan ma ro pe eto kan toun n se
lori redio nileese Family FM ni gbogbo ojo Sande laago mesan an aaro si aago
kan osan ma ro pe oun le lo anfaani e lati da ajo alaanu sile.
Tantala |
Tantala so pe ko si
lokan oun lati da ajo alaanu sile, nitori pe se ni eto ori redio naa yiwo mo
oun lowo lairo tele nitori pe nnkan toun ko fi ojo kan soso sun oorun lati ronu
nipa sise iranlowo fawon eeyan.
O ni kayeefi lo si n
je foun bi eto naa se di eto iranlowo lojiji, nitori pe nigba toun maa bere e,
ironu oun ni lati maa lo akoko to sile nigba tawon da ileese redio naa sile mu
inu awon araalu dun dipo ki won kan maa lo orin lasan.
Oloye Ogunsola so
ninu oro e lo ti so pe “Mi o ni lokan lati da ajo alaanu sile. iyalenu ni ipele
ti eto naa wa lonii si n je fun mi, nitori pe mi o ti e ni lokan lati maa fi
eto naa ran awon eeyan lowo, kayeefi ni. Nkan to faa ni pe, nigba ti a bere
redio molebi ti a mo si Family FM, ti
mo si rii pe akoko si sile repete.
“Mo kan woo pe laaro
Sande yen, kaka ki won kan maa lo orin lasan, ki won je ki n maa fi sere, dawon
eeyan laraya, iyen awon ti ko ba lo si soosi tabi asalatu. Tawon eeyan ba pe mi
sori eto naa, ti mo si beere ibeere, mo maa fun awon awon to ba gba ibeere mi
lebun lapo ara mi, kinu awon eeyan tun le maa fi dun sii.”
O tesiwaju oro lori
bi eto naa se yiwo moun lowo pe “Lojo kan leyin ti mo pari eto, ti mo dele lowo
ale, ni arabinrin kan pe mi, to si salaye fun mi pe oun sese bimo ni, ko si si
nnkan toun fee je ati omo oun. O loun rii pe mo maa fawon eeyan lebun ati owo,
pe ki n ran oun lowo. O ni to ba je raisi
kongo kan, ki n foun, nibe ni ara ti ta mi, inu mi baje pelu ipo to wa yen. Ibi
to ti n soro naa ni foonu e ti ku.
“Lati ojo naa titi
di ojo ti mo tun fi pada loo seto yen ni foonu arabinrin yen ko lo mo. Ori eto
na ni mo ti waa salaye fawon araalu pe eni kan pe mi, o si so isoro to ni fun
mi, sugbon ti foonu e ko lo mo latigba naa, ati pe to ba n gbo eto naa, ko waa
ba mi ki n too pari eto lojo naa lati fun lawon eru ounje ati owo.”
Tantala so pe “Boro
naa se yiwo mo mi lowo niyii, tawon eeyan waa bere sii lo anfaani e lati maa
pe, ti won n so isoro ti won ni. Aya emi gan an koko ja pe iru kini mo ko ara
mi si yii. Awon alaboyun, alaisan, awon tebi n pa atawon ti won nisoro
lorisirisi si n pe lati so isoro won.”
Nigba to tun n soro lori
awon isoro ati ipenija toun gan an n dojuko nipase eto yii, o ni “Ipenija po
lorisirisi, bii kelomin in pe wa pe oun fee wa fun wa lowo tabi ni ounje, ko di
ojo to seleri pe oun maa wa, ka ma ri. Ti a ba pe e pada lati beere, o le ma
gbe foonu e mo.
“Elomin in le so pe
oun ko ri aaye ni. Elomin in gan nitori pe o fee polowo ileese e, o le so pe
oun fee fi egberun kan naira seranlowo loruko ileese oun yen, ka ba oun daruko
ileese yen pelu nnkan ti won n se nibe, ti a o ba daruko e, se lo maa dabi eni
pe a lu oun ni jibiti, eyi ti ofin redio ko si gba wa laaye bee.
“Opo awon eeyan lo
ti so pe ka fun un yan ni eedegbeta (N500) naira, ka si ba oun daruko e ati
ileese oun. Ti a o ba si sora se, ileese redio le ro pe a ti gba owo nla, ogbon
la ma fi n se e, ti a o ba tun daruko ileese onitohun, yoo tun pe wa labe aso
pe ao daruko ileese naa daadaa, ti won o mo bo se lo.”
O fibinu soro lori
bawon kan se maa n so pe se lo n feto naa pawo wole sapo ara e, o ni “Won ti e
maa n ro pe a fi n dokowo ni, pe awa naa n ri ti wa nibe, ko ri bee. Mo maa n
pe adabi le ara mi lori eto naa pe ti m ba yo ninu awon nkan ti won n fun mi
lati fun awon alaini nitori pe ise ti mo n se to mii jeun, to tun too bo awon
ebi mi. Eru maa n ba mi lati na owo tto ba di ojo Satide ni, nitori awon to maa
pe awon nilo iranlowo lojo Sande ti m ba n seto lowo.
“Lapo ara mi lojo
Sande, ojo ti mi o ba seranlowo rara, ni mo maa n na egberun lona ogun
(N20,000) naira. Aimoye awon alaini to ti wa sori eto naa, ti won si lo sile
pelu ogberun lona ogun ati egberun lona ogbon naira, kolonka ni won. mo mo pe
eni to ba n saanu naa a ri aanu gba, nitori pe ko seni to ba Olorun dowo po to
padanu ri.
“Aipe yi lawon kan
sese darapo lati maa fun wa ni ahon eran lati fi seranlowo, bee naa lenikan tun
so pe iye toun baa n ni lojo mejo-mejo, oun a maa fi ran wa lowo. Opo awon
eeyan ni mo ti ran lowo, ti mi o kii soo lori afefe. Lojo Itunu aawe to koja
yi, mi o le ka iye adie ti mo ra lati fun awon eeyan.”
Nigba to n so iha
tijoba ko si eto naa, o ni “Iyen gan an nise. Mo ti soo ri lori eto naa pe to
ba je pe se la bu ijoba lori eto naa, laarin iseju marun un, won a ni ki won wa
gbe wa, sugbon ti a ba ni ki won ran wa lowo, ibe ni a o ti ni gbo nkankan.
Ijoba o tii gbo wa bayii, sugbon o di ojo ti won ba bu won. nnkan ti mo mo ni
pe oke lowo afunni n gbe. Mo je eeyan kan to ko awon eeyan mora, oun gan an lo
fa ti mi o fi n toro owo. Ibunkun Olorun nii mu nii la lai fi laalaa kun. O
dara ti a ba ri eni ran wa lowo, tori pe mo mo pe opo awon eeyan ni won ko ri
ounje je, emi naa si ti wa nipo naa ri, ti mo si mo bo se n rii. Adura mi ni pe
ki Olorun ma fi okuta ropo mi.”
No comments:
Post a Comment