Kani awon olopaa to n gbogun ti iwa
adigunjale ati egbe okunkun nipinle Ogun, Iyen FSARS foro naa fale lote yi ni,
o seese ki ara orun ti won ti n wa lati odun to koja tun ti ri ona lati na papa
bora, gege bo se se lodun naa.
Monsuru Adewale loruko ara orun na ti
won loun lo paayan nibi odun eegun to se ninu osu kefa odun to koja ladugbo
Kugba nijoba ibile Abeokuta North, toro naa si da wahala nla sile nilu
Abeokuta, tawon olopaa bere sii ko opo awon odo gege bi afurasi.
Gege b’AWIKONKO se gbo, won ni se ni
inu opo awon eeyan bere sii dun nigba towo olopaa te Monsuru to je okan lara
awon omo egbe awako NURTW, eka tipinle Ogun nitori pe odoodun to maa n se odun
eegun e lo maa n da wahala sile, tawon eeyan yoo si farapa yanayana.
A gbo pe nibi ti Monsuru ti paayan lo
ti lo egbe, tawon eeyan ko si ri titi di ojo to tun farahan pada lakoko odun
eegun ti won se, sugbon won loun lo se amugbalegbe eni to gbe eegun odun yi,
iyen eyi ti won se lose meji seyin.
Gbogbo akitiyan awon olopaa lati rii mu
ni won loo ja si pabo lati odun to koja nitori se ni won so pe Monsuru lo egbe
lati fi dofe kuro lojiji lakoko isele naa waye, to si je pe ilu Ekoo lo wa to
ti n sise e.
Iyalenu lo je nigba ti won tun ri
ipadabo e nibi odun eegun todun yi, sugbon gbogbo ero okan e ni pe ko seni to
maa ranti isele naa mo, lai mo pe iyan ogun odun si n gbona felifeli sile fun
un.
Won ni kaka Ki Monsuru se jeje lakoko
tawon eeyan n dunnu nibi odun eegun naa, oun gan an lo tun n pariwo pe oun yoo
foju awon eeyan ri mabo ti won ba ta felefele ju.
Nigba to maa di nnkan bi aago kan osan
ni won so pe oro naa di boolo o yago, nigba ti won so pe oti ti Monsuru mu
gbodi lara e, to si bere sii lu awon eeyan nilukulu, to fi di pe olori bere sii
du ori e, tawon merin si farapa.
Eyi gan an ni won loo bi awon to ti n
wa lati odun to koja, Iyen awon to pa eeyan won fi ranse sawon olopaa pe odaran
naa tun ti farahan leekeeji, tawon naa ko si foro ohun fale.
AWIKONKO gbo pe bawon olopaa se de be
lawon eeyan ti tuka, sugbon ti won lori tako Monsuru lojo naa, ti won si rii
mu.
Monsuru to so pe adugbo Obantoko loun n
gbe nigba to n bakoroyin wa soro lose to koja so pe ibanuje nla lojo ti won
ri oun mu naa je, nitori pe ka ni oun mo pe owo maa te oun ni, oun ko nii
yoju. O bebe fun idariji pe bi won ba foju aanu wo oun, oun yoo yi pada.
Ogbeni Abimbola Oyeyemi to je alukoro
ileese olopaa ipinle Ogun lakoko to n yannana oro naa fakoroyin wa lose to
koja, o ni Kani Monsuru mo pe awon olopaa si n wa oun ni, o seese ko ma yoju
mo.
O fi kun oro e pe bo tile je pe
Komisana awon ti pase pe ko si lo maa mu gaari logba ewon, sibe iwadii tun di n
lo lowo lati rii awon toku e to salo mu nitori pe o tun pelu okan lara awon omo
egbe okunkun to n da ijoba ibile Abeokuta North laamu.
Titi di bi a ti n sakojopo iroyin yi la
gbo pe awon araadugbo ti Monsuru n gbe fi n be awon olopaa pe ki won ma se fi
sile, ki won je ko jera mo ogba ewon nitori opo awon eeyan toun naa ti pa
nipakupa.
No comments:
Post a Comment