Asiri to wa nidi iwe itan tuntun “Yoruba Ni Tooto” - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 20, 2017

Asiri to wa nidi iwe itan tuntun “Yoruba Ni Tooto”

Ko si iroyin meji to n lo kaakiri orileede Naijiria to fi mo awon orileede kaakiri ile adulawo (Afrika) bayii, bi ko se ti ikojade iwe tuntun tileese iwe iroyin Alariya Oodua, iyen iwe iroyin to n sagbelaruge ewa ati asa Yoruba pelu ajosepo egbe awon oluko lawon ileeko olukoni fee gbe jade ninu osu kokanla odun yi.

Iwe tuntun naa ti won pe akole e ni “YORUBA NI TOOTO”, ti Ogbeni Kunle Babarinde to je olootu agba fun iwe iroyin Alariya Oodua ko, la gbo pe won fee se ikojade e ni gbongan nla kan to fikale sinu ogba ileewe tawon oniroyin, Nigeria Institute of journalism to wa   legbe Oteeli Excellent lagbegbe Ogba nipinle Ekoo l’ojobo Tosde, ojo kerindinlogun osu kokanla (November 16th, 2017).

Gege bi atejade to te AWIKONKO leti lai pe yi se so, won ni aago mejila aaro ni won yoo tepepe eto nla naa tawon ojogbon kaakiri orileede yi ti gbaradi fun ni won so pe gbogbo eto lo fe e pari bayii lati mu ojo naa larinrin.

Lara awon asiri to je ki iwe naa da yato si tawon iwe abinibi to so nipa itan ile Yoruba ti won ti ko seyin ni bi won se so pe egbe awon oluko nileewe olukoni, iyen Koleeji kaakiri orileede yi sise takuntakun lori e lasiko ti won n ko o lowo.

AWIKONKO gbo pe Omowe S.M Raji to je aare egbe awon olukoni nileewe olukoni, NCE lorileede yi lo bu owo lu ojo naa leyin opolopo ipade to ti waye laarin egbe naa pelu ileese iwe iroyin Alariya Oodua to fi mo awon ojogbon nipa eko ede Yoruba.

Asiri min in to tun je pataki ti won lawon ojogbon se yan iwe naa laayo ni awon akatunka, akafikogbon awon itan Ife pelu Modakeke, Alaafin Oyo, ilu Ibadan, Alaafin Arole to fi mo itan bawon Fulani se gba ilu Ilorin mo awon omo Yoruba lowo titi donii.

Nigba to n soro, Omowe S.M Raji je ko di mimo pe akoko iru e nile Yoruba niwe “Yoruba Ni Tooto” je, ati pe idi tawon fi gba iwe naa lowo eni to koo, iyen Ogbeni Babarinde ni ojo ola tawon ri ninu e, tawon si lo osu meta gbako lori e, pelu opolopo ise iwadii atawon amuye to ye lori lati le je itewo gba lowo awon to ba salabapade e.

AWIKONKO gbo pe lara awon to ti n mura sile fayeye ikojade iwe naa ni Oba Adeyeye Ogunwusi, Ooni Ile Ife ati Oba Saliu Adetunji to je Olubadan tiluu Ibadan ti won maa lewaju gbogbo Oba alaye nile Yoruba lojo naa, nigba ti Akeweje tiluu Iseyin, Alaaji Razak Adeleye tawon eeyan tun mo si “Agba Awo” maa je alaga ojo naa.

Alaaji Ganiyu Ajibola, iyen Akewusola ni olufilole agba ojo naa, nigba ti Iyaloja gbogboogbo, Oloye Folasade Tinubu Ojo; Oloye Toyin Kolade ati Alaaja Fatimot Mojisola Sanni maa je awon iya ojo naa.

Oga agba fun ajo OPC lorileede yi, Otunba Gani Adam ni oludanilekoo pataki ojo naa, nigba ti agbenu fun Aare Buhari, Ogbeni Femi Adesina lo maa salaye awon itan to wa ninu iwe tuntun yi fawon alejoo. Bakan naa ni olootu agba fun ileese iwe iroyin Vanguard lo maa fiwe naa lole.

Ohun taa tun gbo ni pe minisita foro iroyin ati asa lorileede yi, Alaaji Lai Muhammed lo maa je gege bi alejo pataki nibi ikojade naa, ti gomina ipinle Osun, Rauf Aregbesola yoo soju gbogbo gomina ile Yoruba.

Gomina tele nipinle Ekoo, to tun je asiwaju egbe oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni baba ojo naa.

AWIKONKO gbo pe nnkan ti yoo tun mu ayeye ikojade Yoruba Ni Tooto larinrin ni ti won fee fun lami eye awoodu, iyen awon taa gbo pe won ti ko ipa ribiribi nipa itesiwaju ede ati ile Yoruba lapapo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI