Sunny Ade fariga, o loun ko nii gba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 23, 2017

Sunny Ade fariga, o loun ko nii gba

Bi ayeye ojo ibi odun mokalelaadorin (71years) se wole de, AWIKONKO fee mu itan to seese e ki e ma tii gbo ri nipa gbajumo olorin nni, Oloye Sunday Adeniyi Aladegeye topo mon on si King Sunny Ade ati Oloye Bolarinwa Abioro, eni to je Balogun ilu Ipokia ati alaga ileese olorin ile Adulawo, iyen African Songs Limited. Gbogbo nnkan ti e ba si kaa nibi, e gba pe ooto ni gbogbo e, nitori pe ise iwadii ijinle gidi la se lori e.
 
Lodun 1974, ti iroyin naa jade sita, opo eeyan niroyin naa se ni kayeefi, to mu ki won maa beere lowo ara won pe “ki lo sele, ki lo le faa?”. Idi nip e Oloye Bolarinwa lo gbe Sunny Ade, eni to tun je irawo olorin to n gbe jade lasiko naa lo sile ejo.

Gbogbo eni to ba mo King Sunny Ade lo mo Oloye Abioro, bee lawon to ba mo Oloye Abioro gbodo mo King Sunny Ade. Sunny Ade je gege bi omo, nigba ti Oloye Abioro je gege bii baba. Kori-kosun lawon mejeeji je funra won nigba naa. “Ki lo wa le sele laarin Baba ati omo e” ni ibeere tawon araalu to fi mo awon eeyan loke okun n beere lowo ara won.

Ninu awon ti won koko ba towo bowe adehun lati gba sileese to n gbe orin Adulawo jade, iyen African Song Limited, Sunny Ade leni-keji ti won ba towo bowe adehun tawon oloyinbo n pe ni sign. Ayinde Bakare leni akoko, Sikiru Ayinde Barrister leni-keta.

Gege bi awon to ni agbekale, Odomokunrin Sunny Ade ko ri nnkan meji ro ju ti ife to ni si ise orin, lori bo se maa tayo nidi ise naa laarin awon ti won jo n figagbaga. Ko ronu nipa bo se maa ri owo nidi ise naa, bi ko se awon agbekale to le muu tayo laarin awon elegbe e.

Awon nnkan yi lo to fun Oloye Abioro, okan lara awon olowo, oloro, gbajumo nidi ise orin lati gbe Sunny Ade jade, ko si fi han faraye. Won ko awon iwe kan t’oloyinbo n pe ni documents wa foun atawon isongbe (ban boys) e lati towo bo (sign), eyi ti won pe ni contract.

Koda, ki won pe loruko miran, ko kan Sunny Ade. Yoruba bo, won ni “Won ni ko wa a je saara, o ni ojo ti wo’nu ju. Se ata ti won ni ko o mu wa ni, abi iyo ti won beere?”. Sunny Ade atawon onilu (band boys) e ko foro naa para rara. Ko si ani-ani pe ko seni to ka awon nnkan to wa ninu awon iwe (documents) ti won fee towo bo ninu won, nnkan to jo won loju ni pe awon naa fee di olorin to n gbe rekoodu jade sita. Sunny signed towo bowe yi, awon onilu e naa towo bo o, inu gbogbo won dun un.

KSA, Abioro atawon olorin nileese African Songs Limited (ASL)
Odun marun gbako niwe adehun (contract) ti won towo bo maa dopin. Sugbon ki ojo naa too de, oruko KSA ti tan kaakiri agbaye, o ti di nnkan ti t’omode t’agba fi n sorin ko losan ati loru. Rekoodu e Challenge Cup ta debi tawon gan ko lero, eedegbeta (500,000) ni won ta nigba naa.

Ko si iyemeji pe Sunny Ade lo maa gbajoba orin fun opolopo odun. Ileese ASL naa mo pe awon ri nnkan to da nigba ti won ri Sunny Ade. Awon alase ileese yi ko duro de asiko ti iwe adehun ti won towo bo maa de, won ti gbe iwe adehun min in wa fun Sunny Ade lati towo bo.

Won ti pari gbogbo ise nigba ti won maa gbe iwe yi wa siwaju e. KSA atawon onilu e ko tete fura, sugbon won tun gba lati towo bo iwe adehun olodun marun un min in pelu ileese ASL. Ileese ASL lo ni gbogbo ase lori gbogbo orin, ati attune ati lilo awon orin ti KSA ba n ko, to fi mo awon ode ariya to ba n lo kaakiri agbaye.

Iyen nikan ko. Laarin akoko yi, Won o gba ki Sunny Ade maa lo sere lawon ibi ti won ba pe e si, yala ode ariya, ile-ijo, eto apeje rampe tabi eyi to wu ko ri, lai je pe o gbase lowo awon alase ileese ASL. Iwe adehun (contract) yi tun so pe ileese ASL tun ni agbara lati so pe ki adehun naa tun teswiwaju pelu odun meji tabi opolopo odun ti won ba fe leyin ti adehun akoko ba pari. Sunny Ade ko lagbara lati so pe oun ko se mo.

Ko tan sibe, lori awo orin (album) ti won bat a, eyi ti won ta ni naira mefa (N6.00) nigba naa, ogun kobo (20kobo) lo n je ti Sunny Ade atawon onilu e, ASL lo ni gbogbo owo toku. Beeni! E le ti ba a pade.

Pelu idunnu lori okiki e to n kan kaakiri agbaye, Sunny Ade ko ro o leemeji to tun fi towo bo iwe adehun min in yii, awon onilu e naa tun towo bo o. Ogun kobo nigba naa, owo gidi ni. Se bi Yoruba lo so pe “Orogun iya re da sokoto fun o, o ni ko bale, melo gan an ni iya to bi e da fun e?”, oro buruku toun terin.

Won n reti ogun kobo won lori awo (album) kan. Wel, nigba ti asiko to lati san iye owo to ye ko je, o wa foju han gbangba leyi isiro ifikun ati ayokuro (mathematically and arithmetically), ko ye ko je ogun kobo. Won tii ro ti ipolowo ati igbelaruge mon on. Nigba to si je pe olorin naa ni won n gbe laruge, oun gan an lo ye ko fara gba a. Leyin o reyin, won fun Sunny Ade ni kobo meedogun (15kobo) lori awo (album) kan.

Boyalemo pe KSA yato si Chike Obi, olusiro (mathematician) nni. Sugbon o mo pe ogun kobo (20kobo) ati kobo meedogun (15kobo) yato gedengbe sira won.
Nigba to n wo awon ti won jo n figagbaga nidi ise orin lasiko naa, o sakiyesi pe oun nikan loun n pawo to kere ju sapo ara e. Akegbe e, Oloye Ebenezer Obey, iyen Baba Commander, owo to n gba lori awo orin e kan je aadorin kobo (70kobo), awon to ku n ri owo to to kobo marundinlogoji (35kobo) ati ogoji kobo (60kobo).
  
KSA, Queen Oladunni Decency ati Baba Commander
Gege bi a ti n ba oro naa bo, isele kan tun sele leyin ti Sunny Ade rii bawon akegbe e nidi ise orin ti won jo yan laayo se n ri owo to joju, ti won si n ri se, tokiki won si tun n kan kaakiri, lo ba sepade papo pelu awon onilu, won jo jiroro, won pinu lati loo ba oga won, Oloye Abioro soro, ki won si jo sasaro to jinle.

Igba yi gan an ni Sunny Ade pinnu lati beere fun ekun’wo lori owo to n gba lori awo orin kan ti won n ta. Alaga ASL, Oloye Abioro fowo leran, o n gbo gbogbo nnkan ti KSA atawon onilu e n ba a so. O farabale lati gbo gbogbo alaye won daadaa. Nigba ti won soro tan, Oloye Abioro min kan’le, o jokoo sara, lo ba gbe iwe nla kan jade. Nibi to jokoo si, Sunny Ade rii pe iwe adehun tawon ti n towo bo lateyin wa ni. Iwe adehun lori adehun. Awon iwe to de won papo.

Oloye Abioro je ko ye won pe “Adehun ni adehun. Oun lo si de ise ti won gba.” O ni “Nnkan ti e towo bo ni yii. Ko si afikun, ko si ayokuro.” O da awon iwe naa pada. Ejo ba ku s’ake.

Sibe, ko te Sunny Ade lorun, o ni “Oloye, eleyi kii se oro adehun, eyin ni baba wa, nnkan ti a fe ni pe ki e mo riri wa nipa fi fun wa lawon nnkan to to si wa. E je ka gbe ti oro adehun ti segbe kan.”

Oloye wo irawo kekere olorin yi gege bi obi se n wo omo e to ba beere pongila (candy) min in. “Ka gbe ti adehun segbe kan? Ki awa 333 gbe adehun segbe?. O beere pelu iyalenu, O ni “Se o mo pe ki ba dara ka gbe ti adehun ise ti a gba segbe kan?, sugbon nkan to wa nidi e ni pe, ko le bo’fin mu.”

Haba! Ko bo’fin mu bii ti bawo?! Igba yi gan an ni enikan wa mu aba wa pe ki won ran awon ore e sii lati bawon be e lori oro yii. Sunny Ade gba, nigba to je pe “Eni ti o mo oju Ogun, ni pa obi ni 're.”

Won ba lo sodo Omoba Okunade Sijuade, eni ti ko ni pe e di Ooni Ile Ife nigba naa. Won tun lo ba Oloye Afolabi Joseph. Ko daa, won tun lo ba Oloye Ebenezer Obey lati da si oro naa, to fi mo Oloye Nurudeen Alowonle (O see se ki e tun ka itan nla nipa Nurudeen Alowonle ati Haruna Ishola lai pe yii lori Iroyin Awikonko.)

Gbogbo won fipade si kootu Balogun tiluu Ipokia gege bi awon agbejoro lati seranwo fun ileejo lati da ejo, ti won n pe ni “Amici Curiae”, lati ba awon olorin naa da si oro to n dun won lokan

Awon ojogbon yi jiroro lori oro naa gege bi amofin (advocate) to ni iriri ati imo. Won lo awon apeere ninu iwe ofin ile Yoruba eyi ti won ko tii sakosile e. Won lo awon owe Yoruba, won lo apejuwe ninu itan Oduduwa. Alaga naa gbo gbogbo alaye won, o si da ejo naa nu pe adehun l’adehun.

Oloye yi ko kan da ejo naa nu lasan, o tun gbe awon iwe (documents) min in jade to toka si adehun olodun marun un min in. Asiko yi gan an ni ofin sese n ye Sunny Ade, to si n kekoo nipa ofin. O ti waa di ojogbon ninu isiro, iyen professional mathematician.

O gba Masters ninu ekoo nipa okoowo, iyen Business Administration peluu idanilekoo to dan monran. O mo Pataki ati atubotan titowo bo iwe. O tun kowe pe ki won sun ejo naa siwaju.

Oba ilu nile Afrika ba ara nikorita “ko ye mi mo”, ko mo igbese to tun fe e gbe. Orin e tuntun ti pari lati gbe e jade, sugbon Oloye Abioro ti n dunkoko mon on pe afi ko tun towo bowe adehun min in koun too le gbe orin naa jade sita. KSA ko si setan lati towo bo iwe adehun min in pelu e digba ti won yoo fi yanju oro ekunwo ti won n fa lowo.

Asiko yi gan an ni KSA ranti okan lara awon owe iya-iya e to so pe “Ti abiku ba gbon ogbon ati ku ni igba erun, iya abiku a gbon ogbon ati sin oku e si etido.”

Sunny Ade wa a pinnu lati gbe awo orin e tuntun jade peluu ileese min in. ipinnu e ni lati lo awo orin naa duna-dura lona ara-oto peluu ileese African Songs Limited. O woo pe kaka koun tun maa gba ogun kobo, okan bale pe alaga ileese naa yoo fee san naira kan (N1.00) foun lori awo orin kan.

Orileede Naijiria lo ti gbe se orin naa, o wa gbe e lo si London lati lo poopo. Nnkan ti Sunny Ade gbagbe lati mo ni pe Ogbologbo ni Oloye Abioro je nidi ise nss. Ki eda orin naa too te Sunny Ade lowo, Oloye Abioro ti nii rekoodu tuntun naa lowo.

Inu ile ni Baba Ibeji, Sunny Ade wa to n tun gbiyanju lati palemo fun awo orin min in nigba ti won mu iwe kootu wa fun un. Iwe kootu yi nigba to ye e wo daadaa, o rii pe wahala nla loun gbe dani, nitori pe iwe yi lo daa lowo ko lati gbe orin naa jade, tabi ko ta a sita, tabi ko ti e tun se nkan lori e. Akatunka lo ka awon iwe naa, ko daa, pelu pe kii se amofin, o mo atunbotan awon iwe to ko dani. Oro buruku toun terin.

Oro m ba ro ma r’ofo, efo n ba ro maa fi j’ekoo, pelu ibanuje okan, o ranti bo se kuro niluu Abeokuta wa siluu Ekoo pelu sile kan ati peni mejidinlogun (one shilling and eighteen pence)! O ranti awon odun to lo peluu Baba Sala. O ranti bi ko se ri nkankan nibi irin ajo to rin lo siluu Jebba ati Kano peluu Baba Sala.

O ranti bi ko se foju kan iya e f’odun meji gbako ati bo se tun jiya lati di olorin. Ko gbagbe bo se je pe eyo metala pere lo ri ta ninu awo orin akoko to se e. Sugbon ni bayii to ti wa de bebe aseyori, ti ase kootu tun fee da lowo ko. Peluu ipinnu atokanwa, o mo pe oun ko le fi ise naa sile.

KSA ati eni to je gege bi awokose (mentor) e, Baba Moses Olaiya
O ranti ojo akoko e ni Osodi nigba to sinna lati de ile Moses Olaiya, to je pe ile Victor Olaiya ni Tinubu ni won dari e lo. O ranti bo se kunle sinu erupe lati gbadura l’Osodi. Lesekese lo ronu nnkan to le se. Sunny Ade kunle pelu ohun ebe aanu, o gbadura kikan.

Nigba to maa dide lori eekun e, o ti gba agbara otun, okun tuntun ti de, ironu e tuntun ti soo sii lori. O ti wa mon on nnkan to le se lati ri ona abayo. Igboya ara-otun ti de. Irole ojo naa lo da ileese ti e sile.

Won bi ileese Sunny Alade Records
Lesekese lo sare dide lori ikunle to wa. O ranti awon ihale Oloye Abioro lati fa a wale ni gbogbo ona. O mo pe o ye koun ni agbejoro to lagbara, to si le ja foun lati tako ota e to fe e dii lowo ije. O jade sita, o rin kaakiri, o si salabapade Gani Fawehinmi, ogbologbo agbejoro.

Gani Fawehinmi gba awon iwe ti kootu ti KSA ko fun wo, iyen awon iwe ti Oloye Abioro fi pe e lejo si kootu. O woju KSA, o tun ye awon iwe naa wo. O rii pe Oloye Abioro ko fe e fi nkankan sile fun KSA atawon onilu e. o ti mo nnkan ti KSA fe ki ile ejo se foun, nitori pe gbogbo iwe adehun KSA ati ileese ASL.

Nnkan merin pere ni Oloye Abioro fe ki ileejo se foun; akoko ni pe ki adehun to wa laarin ileese e ati Sunny Ade si maa tesiwaju; eleekeji ni pe ki ileejo da KSA lowo ko lati ma se ta tabi pin awon awo orin to ba se sita; eleeketa ni pe ki Sunny Ade ko awon iwe akosile rekoodu to ti ta foun; eleekerin ni pe ki Sunny Ade san milionu kan (1milion) naira foun gege bi owo itanran pe o tapa si adehun to ba ileese ASL se.

Lojo igbejo ti gbogbo pade ni kootu, se ni kootu kun lojo yi bii pe won fe e dajo ogboju odaran. Gani Fewehinmi ti dira Ogun was i kootu lojo naa, awon iwe ofin to ko was i kootu lojo na to lati si yara ikawe (Library). Orisirisi iwe nipa imunileru (Slave trade), ija feto omo eniyan, iwe ogun atibeebeelo.

Nnkan ti Gani Fewehinmi koko gbe siwaju ile ejo ni pe ki ileejo pase fun ileese Afican Song Limited lati pese gbogbo iwe akanti (account) oja ti won ta fodun meta to koja. Ileejo si fase sii. Igba yi gan an loro too foju han pe milionu kan din ni egberun lona ogorun naira (900,000) ni awon orin Sunny Ade ti ileese naa n ta lodun, to si je pe egberun lona ogofa (62,000) naira ni gbogbo owo ti Sunny Ade ti gba lowo ileese naa laarin odun mewaa. Oro buruku toun terin gba a.

KSA gbarada nile ejo
Gani funra e ko gbagbe lati so fun ileejo bi ogun kobo tun se pada di kobo meedogun. Bee lo tun salaye awon ona eburu bii imunileru to wa ninu iwe adehun to ko le KSA lowo lati towobo. O ni awon iwe adehun naa ko yato si iwe adehun owo eru sise nigba ti won si n sowo eru lorileede yi, pelu pe a ti gbominira kuro lowo awon amunileru.

Adajo to dajo nigba naa, L. J. Dosunmu farabale gidi lati gbo awon alaye lenu awon mejeeji, iyen agbejoro KSA ati agbejoro ileese ASL. O wa sun ojo igbejo min in sojo kerinla osu keji odun 1975 (February 14, 1975). KSA ko ti e ri ojo naa ro pe ojo yen gan lojo ayajo ololufe kaakiri agbaye. Nnkan to wa lokan ni ibi ti aago elepon naa maa duro si nigba ti adajo ba dajo tan. Eru n ba gidi.

Gongo so
Nigba t’ojo kerinla osu keji naa de, nnkan bi aago meje aaro lawon eeyan ti bere sii de si kootu. Ise nla lawon to n sise ni kootu se lojo yi lati sakoso awon ero to wa woran ni kootu lojo naa.

Onidajo Dosumu nigba to n soro so pe gege bi ofin, iwe adehun to wa laarin awon mejeeji ku oju osuwon, o bofin mu, o si gbodo maa tesiwaju. Aya KSA ja, eru ba a, o woju agbejoro e, Gani Fawehinmi, iyen so fun pe ko fowo wonu, ko farabale maa gbo, nitori pe ejo kan soso ni won si da ninu merin.

Onidajo naa so pe niwon igba ti won ti pin awon awo orin naa kaakiri orileede Naijiria, ko si n kan tawon le se lati gba gbogbo awon awo orin naa pada, ileejo ko lati da Sunny Ade ati alagbata (Marketer) e, M. Ola Kazim lowo ko lati ma se pin awon awo orin naa. Okan Sunny Ade bale nibi to wa, erin pa ereke e, inu e dun.

Idunnu subu lu ayo
Se e o gbagbe pe Oloye Abioro fe e gba milionu kan naira gege bi owo itanran pe Sunny Ade tapa si adehun to ba ileese oun se? Ileejo so pe aaye gba Sunny Ade lati ba ileese orin miran sise niwon igba ti adehun won si n lo lowo, nitori naa, ki Sunny Ade san oodunrun (N300) naira gege bi owo itanra dipo milionu kan naira. Sunny Ade rerin nibi to wa.

Ileejo pase fun KSA lati ma se gbe orin miran jade titi digba ti iwe adehun to towobo pelu ileese ASL yoo fi pari. Iporuru okan tun ba Sunny Ade nibi to jokoo si nitori to ronu nnkan to ma maa je ki osu mefa ti ojo adehun naa ku fi pari.

Nise lo dabi eni pe adajo naa reran denu okan KSA, lo ba tun pase pe Sunny Ade lase lati lo maa sere fawon ololufe e kaakiri laarin osu mefa ki adehun naa pari ko le maa ri owo fi toju ebi e, sugbon ko lase lati gbe e jade tabi ta a sita.

Adajo dide, Sunny Ade atawon eeyan e fo soke, ni won ba di mo Gani Fawehinmi, agbejoro won to gba won sile loko eru.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI