Awon olopaa Amosun meji ku, won ni kii soju lasan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 30, 2017

Awon olopaa Amosun meji ku, won ni kii soju lasan

Titi di bi e ti n ka iroyin yi lawon eeyan to gbo sisele awon olopaa Gomina ipinle ogun, Ibikunle Amosun si n so pe oro naa kii soju lasan latari bawon eeyan naa se ku laarin ojo merin sira won.

Olayinka Robot
Gege b’AWIKONKO se gbo, Busoye Olayinka ati Wale Aderemi lawon eeyan naa ti won so pe okan pataki lawon mejeeji ninu awon olopaa to n tele Gomina Amosun, toun naa ko si le fi won sere.

Ojo Aje Monde ose to koja la gbo pe Wale Aderemi, omo bibi ipinle Ekiti to n sise lekaa DSS dagbere faye losibitu Mercy, to wa ni Panseke Abeokuta leyin ti won loo subu nile igbonse inu ile to n  gbe.

AWIKONKO gbo pe aisan taifoodu lo se Wale, ti won si fun laaye pe ko loo toju ara e losibitu nibi to tii lo ojo meloo kan, ko too di pe won ni ko maa lo sile. Aaro ojo Monde naa nigba to je pe koun loo fo enu, la gbo pe ese e gba ilekun, to si subu lule.

Lesekese lawon ti won jo n gbe e ti sare gbe e pada lo si osibitu Mercy naa, sugbon nigba ti won maa gbe e de be, elemin in ti gba a. Aaro ojo Tosde to koja la gbo pe won gboku e lo sipinle Ekiti to ti wa.

Ironu iku Wale lawon elegbe e si n ro lowo laaro ojo Fraide, nigba ti iroyin iku Busoye Olayinka tun fi kan si won, pe o pada emi e ninu ijamba moto lagbegbe Papalanto, nitosi Ewekoro.

Ohun taa gbo ni pe oun ati aburo e kan ni won jo n rin irin ajo lo sile e taa ko tii gbo ibi to wa titi dasiko taa fi sakojopo iroyin yi tan leyin to kuro nibi ise e ni nnkan bi aago mesan ale ojo Tosde naa.

 AWIKONKO gbo pe idunnu owo ti Gomina Amosun sese fawon to ba a sise lale ojo naa lo n gbe e lo sile lati loo fawon ebi e ninu e, ko too salabapade iku ojiji pelu aburo e ti won lesekese loun naa ti ku.

A gbo pe oko tirela kan lo n feyin rin jade ninu ogba Dolphin Steel Nig. Ltd jade si titi, iyalenu lo je nigba ti Olayinka tawon eeyan tun n pe ni Robot maa fi gboju soke, aso ko bomoye mo, abe tirela naa ni moto e Nisaan Primera pelu nomba idanimo Lagos, PH 406 KJA mori wo.

Oga agba ajo FRSC nipinle Ogun, Ogbeni Ckement Oladele nigba to n jeri soro naa so pe bo tile je pe kii se lesekese ni Olayinka ati aburo e ku, sugbon bawon se n gbe won wonu ogba osibitu ijoba to wa n’Ifo ni won dagbere faye.

Bawon eso Gomina Amosun se gbo sisele yi leru ba bere sii bawon, ti won beere lowo ara won pe taniku kan, nitori teru ti bere sii ba gbogbo. Onikaluku won la gbo pe won ti bere sii pe ohun ti won nigbagbo ninu e fun aabo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI