Baale ilu to n ra apa eeyan fi seso ti ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 23, 2017

Baale ilu to n ra apa eeyan fi seso ti ha o

Pakopako ni Baale abule Ososun nijoba ibile Ifo ipinle Ogun, Isiaka Ajani n wo logba olopaa leyin tasiri e tu sita pe oun gan an ni olori awon babalawo to n ra eya ara eeyan fi seso fawon eeyan.
 
Boroboro ni Baale naa n ka bi eye ayekooto nigba ti won mu pelu awon ogbologbo elegbe okunkun ti won ni won o nise meji ju ki won maa sowo eya ara eeyan lo tasiri won tu sita.

Ohun taa gbo ni pe agbegbe Ibogun ni Ifo lowo olopaa ti te gbogbo won ti won si so gbogbo ise ibi ti won ti se seyin ko too di pe okete won ko ri ona lati boru mo.

AWIKONKO gbo pe bawon eeyan yi se n segbe okunkun, ni won n digungbale, bee ni won tun n digun jawon araalu lole, ti won tun n fipa bawon odomobinrin to ba ko sakolo won sun bo se wu won.

Oluwaseun Odueh ti won tun n pe ni Cleff ati Wasiu Adejumo ti won n pe ni Bomber lawon omo egbe okunkun Eiye yi ti won ka owo eeyan mo lowo lose to lo lohun, ti won si tu asiri ise won fawon olopaa, awon gan an ni won satona awon olopaa bi won se mu awon babalawo meji to fi mo baale naa.

Ajani nigba to n soro kabamo iwa naa, to si ni ki won foju aanu wo oun, ati pe ise esu ni. O ni ajagungbale lawon eeyan naa koko pe ara won nigba ti won wonu abule wa, ti won si lawon fee soogun ibile.

O so pe ko pe ti won de ni won tun so pe awon n ta eeya ara eeyan, paapaa apa. O ni nigba toun rii pe o maa wulo fawon ise kan, lo je koun ra apa meji legberun mewaa, sugbon toun ko mo pe asiri si maa tu.

Awon babalawo meji towo tun te, Ifatona Akanni tawon eeyan n pe ni Ajana Oro ati Oko Musa so pe apa meta-meta pere lawon ra lowo awon eeyan naa, ati pe oogun asiri bibo lawon fi awon apa naa se, egberun marun lawon si n ra apa kan soso lowo won.

Musa so pe looto loun n sise babalawo tawon eeyan si mo oun, O ni ninu apa meta toun ra, owo apa meji pere loun si ri san, egberun marun naira to je owo apa kan lo ku toun fe e fun won ko too di pe won wa mu oun nile.

Okan lara awon odaran naa, Odueh so pe omo egbe okunkun Eiye loun, o ni kii se pe awon deedee maa ta apa awon tawon ba pa, sugbon kawon le maa fi ri owo naa lati fi mu idagbasoke ba egbe won lo je kawon bere si ni maa ta a fawon babalawo.

Bee ni Wasiu eni ogbon odun, to tun sise yahoo-yahoo so pe oun ti pa eeyan meji ninu egbe okunkun alatako, Aiye, iyen Kehinde ati Lekan Welder, ti won pa lara awon omo egbe won, ti won tun ge apa won lo.

Ni bayii, agbenu funleese olopaa ekun Zone 2, Arabinrin Dolapo Badmus nigba to n soro so pe ni nnkan bi aago meji osan ojo ketalelogun osu to koja lowo te Oluwaseun Odueh, to si jewo fawon, ko too di pe owo te awon emewa e to ku.

O l’ose yi gan lawon eeyan naa yoo foju bale ejo nitori tawon eeyan naa ti jewo, ti tun si nnkan tawon n duro de gege bi igbakeji oga olopaa ekun Zone 2, Adamu Ibrahim se ti pase fawon.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI