Eyi ni bi oga agba kan nipinle Ekoo se pokunso l’Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 23, 2017

Eyi ni bi oga agba kan nipinle Ekoo se pokunso l’Abeokuta

Titi di bi e ti n ka iroyin yi lowo lawon molebi okunrin kan, Buraimoh Oludare to pokunso sinu yara e lojo Aje Monde ose to koja si fi wa ninu ibanuje okan, nitori ti won so pe oloogbe naa ko fu won lara, tabi ko sebi eni pe oro kan n gbe lokan, ko too pinu lati gbemi ara e.
 
Boro naa se n se awon ebi Oludare ni kayeefi, bee lo tun n je iyalenu fawon to wa nibi isele naa, ti won n so orisiri nnkan to le fa a lati pokunso. Bawon se n so pe kii soju lasan, o lowo aye ninu, bee lawon kan n so pe boya ile aye lo suu ni.

Oludare, ti won loun ni oludare leka ileese to n soro awon odo nipinle Ekoo ni won ni ko ju nnkan bi iseju meedogun lo to fun okan lara awon omo e, Dotun to ni aisan iba loogun, ko too wo yara e lo lati loo pokunso.

Phase ii, Unity Estate ladugbo Gbonagun, Obantoko, Aebokuta nisele buruku naa ti waye ni nnkan bii aago merin irole, to si gba omije loju opo awon to wa nibe lojo naa, nitori ti won so pe okunrin naa ko eeyan mora, o si maa n bawon eeyan sere.

Dotun to loun ati baba oun lawon jo wa ninu ile lojo naa, ko si pe ti baba oun foun loogun nitori ara oun ti ko ya, toun ni aisan iba lo gba yara e lo, toun ti e ro pe nise lo fee lo sun, lai mo pe ero buruku naa ti wa lokan e.

Omo naa so pe nigba toun ko tete gbo ohun baba oun, loun pe e wo, ti ko si da oun lohun, lo je koun loo yoju wo ninu yara lati mo nnkan to n se nibe, sugbon iyalenu lo je nigba toun ri loke faanu, nibi to ti n min jolojolo nibi to so ara e ko sii pelu aso oke.

O loun ko mo nnkan toun le se nitori ti aya oun ja ati pe oun ko ri iru nnkan bee ri laye oun, lo je koun sa jade sita lati loo pe awon araadugbo pe ki won wa gba oun.

Nigba to n soro pelu ibanuje okan, iyawo oloogbe naa so pe oun ko si nile lasiko tisele naa waye, awon araadugbo lo pe oun lati so nnkan to sele, toun si gbera lesekese kuro nibi toun wa lati maa bo nile.

Obinrin naa so pe iwa odaju loko oun hu nitori pe asiko to ye kawon maa gbadun lo gbemi ara e, ati pe ko ba oun soro pe bioya oro kan n gbe e lokan, koun si gba a nimoran.

Lara awon araadugbo naa to bakoroyin wa soro lojo Wesde so pe o seese ko je lati ibi ise ni won ti saa si okunrin naa, ati pe lopo igba lawon osise ijoba maa saa si ara won, ti won si maa je ara won lese.

Eni naa to ni ka foruko boun lasiri so pe nigba toro naa sele, awon agbaagba to wa nitosi ni won ranse sawon olopaa Obantoko lati waa foju won to isele naa, ti won si gbe oku e lo si motuari jenera to wa n’Ijaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI