Eyi ni bowo EFCC se te awon ogbologbo omo Yahoo l’Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 11, 2017

Eyi ni bowo EFCC se te awon ogbologbo omo Yahoo l’Abeokuta

Titi di bi a ti n sakojopo iroyin yi loro awon akekoo ileewe giga gbogbonise ti Moshood Abiola, MAPOLY towo awon osise ajo to n ri si sise owo ilu mokumoku, iyen EFCC te lai pe yi si n je kayeefi fawon araalu, nitori ti won so pe won o nise meji ju ise jibiti ori ero ayelujara, Yahoo-Yahoo lo. 

Ko si nkan meji to mu kasiri won tu sowo awon ajo EFCC bi ko se bi ko se ona ti won ni won n gba na owo won, ati bi won se so pe ise Yahoo-Yahoo ti won n se ko mo, won ni won tun te e nidi peluu. 

Okunrin kan ti won foruko bo lasiri ladugbo Saraki Adigbe la gbo pe o kowe sawon ajo EFCC, eka tipinle Ekoo pe ki won tete wa a bawon wa nnkan se soro awon omo Yahoo-Yahoo ti won fi ileewe MAPOLY boju. 

AWIKONKO gbo pe, opo igba ni won ti foro awon omo Yahoo yi to awon olopaa leti, sugbon ti won so pe won o ri nkan se sii, atipe ona ti won lawon osise olopaa SARS fi n gbowo lowo eeyan timura won ba jo tomo Yahoo ko see fenu so, sugbon nigba ti wahala naa po ju, ti won bere sii fejo won sun awon oga won lori radio lo mu ki won sa seyin die. 

A gbo pe ilo tawon omo Yahoo yi n lo awon obinrin, paapaa awon obinrin to je pe ise asewo ni won fi n jeun lo mu kawon eeyan tete foro naa to awon ajo EFCC leti. 

Gbara ti won ni Leta naa te awon EFCC lowo ni won ti gbera lati bere iwadii, ko too di pe lojo ketadinlogun osu to koja yi lasiri won tu nigba ti won loo ko won ninu ogba ileewe won leyin ti won ti koko loo gbase lowo awon alase ileewe naa. 

Awon merin la gbo pe owo te ninu ogba ileewe, ko too di pe won mu won lo sile lati loo ko awon toku. Iyalenu lo je nigba ti won ni won ye gbogbo inu ile ti won n gbe wo, to won si ri orisirisi igba oogun,eyi to je ki won mo pe osole ni won se, to won fi ise Yahoo boju. 

Awon towo te naa ni: Adesina Olalekan, Makinde Noheem, Toheeb Ogunowo, Somotun Olusola, Somotun Sodiq, Tajudeen Hafeez Bolaji ati Kareem Olaseni.

A gbo pe ile faaji to wa ninu papa isere MKO Kuto lowo ti te awon kan, nigba towo palaba awon toku segi ladugbo Panseke si Onikolobo. 

Awon min in towo tun te ni Iyun Ifeoluwa, Odusanwo Ibrahim, Obanijesu Opeyemi Soneye, Azeez Olayinka, Babatunde Ajala, Ojejimi Ademola, Aderowunmi Ayomide ati Oluokun Oluwaseun.

Ipele kinni si Ipele keji (ND1 -ND2) ni won wa ti won ti n ko eko otooto. A gbo pe yato si pe won n fise Yahoo boju, won tun n yi iwe lati fi lu awon eeyan ni jibiti owo. 

Lara awon nnkan ti won ri gba lowo won ni Komputa alagbeka, Laptop, ayederu iwe ti won yi lati fi lu awon eeyan ni jibiti owo, igba atawon nnkan min in. 

Nigba to n jewo gbogbo ise ti won ti se, okan lara won, Kareem Olaseni, eni odun mokanlelogun so pe oun ni ayederu oruko oyinbo, Dean Robert toun n lo lati fi lu awon eeyan ni jibiti lori Facebook. 

O ni orisirisi ona loun maa n lo lati fi tan awon to ba ko soun lowo, bii ko so fun won pe won ti je lotto, won si gbodo san iye owo kan lati fi gba owo to won ba je. 

O loun lawon to maa n boun loo gba owo naa ti won ba ti san an, awon ni won maa san owo yi sinu akanti oun ni bank toun n lo. 

Sugbon ni bayii, ajo EFCC ti je ko di mimo fawon araalu pe iwadii tun di n lo lowo, ati pe leyin iwadii awon peluu asiri to run to tu sawon lowo, awon yoo foju gbogbo won bale ejo. 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI