O tan o, Awujale ti soro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 11, 2017

O tan o, Awujale ti soro

Opo awon eeyan ni won ti ro pe Awujale tile Ijebu, Oba Sikirulai Adetona tiroyin e kan sigboro ni nnkan bi ose meta seyin pe o ti waja ko nii farahan nibi ayeye Ojude Oba olodoodun todun yi, nitori ti won so pe ara kabiyesi naa ko tii ya daadaa, to si wa ni oteeli to ti n gbatoju nipinle Ekoo.
 
Ohun taa gbo pe o fa iroyin naa ni bi won ko se rii laafin e, paapaa lakoko ipalemo ayeye Ojude Oba ti won se koja lojo Sande to lo lohun niluu Ijebu Ode,  sugbon ti kabiyesi boniroyin soro lori ero ibanisoro pe oun ko ku, koko lara oun si le.

Ojo naa ni enu ya opo awon eeyan nigba ti won ri Kabiyesi to rin funra e, lati aafin e wonu gbagede ti ayeye naa ti waye, to si tun gun oke lo sibi to jokoo si, nitori ti won so pe Oba Adetona ko le da rin, se ni won n muu rin, ti ko tun le soro daadaa.
AWIKONKO gbo pe, ohun to fee mu ki aheso naa jo gate ni bi Kabiyesi se n lo ogbufo lati fi bawon eeyan soro lakoko to n soro lojo naa, ti won si so pe looto ni nnkan to n lo kaakiri igboro pe ara e ko tii ya, ko tun le soro daadaa.

Sugbon nigba to ya ni Gomina Amosun so fun ori ade naa pe to ba fe kawon eeyan yee gbe iroyin buruku kaakiri, ko soro jade funra e, lai lo ogbufo, nitori tawon eeyan ti n kun pe ko le soro daadaa. Eyi lo fa ti kabiyesi fi gba maiki lojo naa, to si bawon eeyan soro, to tun korin.

Oba Adetona nigba to n soro so pe “Gomina ni mo gbodo soro, ki e ma so pe mi o le soro mo. Tori pe oro yi soro. Mo ki gbogbo yin ku ewu odun. Mo dupe lowo Olohun pe mo wa nibi ayeye todun yi atawon  to n ba wa sayeye yi bii Glo, FCMB ati Rite to sese darapo.

“…Maa tun dupe lowo Gomina Amosun fun iranlowo ati akitiyan nitori o pe ti ojo ti n pa igun bo… Gomina n ba mi soro legbe mi, o ni se lo dabi pe won n pe awon omo Egba nijapelu ayeye yi, sugbon mo so pe ko ri be nitori pe opolopo odun lawon baba nla wa ti n se, tawa naa o si je ko parun. Ko si seni to ni nkan to le fi koju wa, eni to ba fe e wa koju wa, o gbodo mura daadaa, ati pe ko seni to le koju wa nitori pe wahala wa n be, o si lewu. Won a sare, Olohun nikan ni ko ni je ki emi won lo si nitori pe awon rowo fi se e.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI