Ise Fuji ti yato si ti tele – Adio Adeyinka - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 18, 2017

Ise Fuji ti yato si ti tele – Adio Adeyinka

Alaaji Taofeek Adio Adeyinka to je gomina egbe olorin Fuji, iyen Fuji Musicians Association of Nigeria (FUMAN) nipinle Ogun ti so pe ise orin Fuji kiko ti yato si oju tawon eeyan fi n wo o, nitori pe gbogbo nkan lo ti yi pada latari olaju to wole de.
 
Alaaji Adeyinka soro yi nibi ayeye ibura fawon oloye egbe tuntun nijoba ibile Abeokuta North lose to koja ladugbo Ago-Odo, Abeokuta. Nibi to ti so pe o ye kawon maa dan opolo awon omo egbe won wo leekookan lati le mo eni to dangajia lati korin Fuji ninu won, to mu ki won da eto kan ti won pe ni FUMAN with Friends sile.

O ni kii se pe awon deede pinu lati da eto naa sile, bi ko se lati maa gbe awon omo egbe olorin Fuji nipinle naa goke agba, kawon naa si le tete dolokiki nitori pe opo ninu won ni won lebun orin kiko, sugbon to je pe ko si an faani fun won lati korin fawon eeyan, depodepo pe won a se awo orin jade sita.

Nigba to n soro, o so pe “Idi pataki taa fi bere eto yi, nitori pe akoko iru e re e lorileede Naijiria ni pe, a fe e maa mo eni to ye lati gbe laruge nidi ise orin Fuji taa yan laayo. Kaakiri gbogbo ijoba ibile la si ti ma maa se, to je pe a ma maa fiwe pe awon eeyan lati waa woran wa.

“Nise la fee se e gege bii idije laarin awon omo egbe wa, ti a ba ti pari e, a maa ko oruko awon to ba gbegba oroke sile, leyin naa la maa wo yara igbohun sile lati sise papo gbe awo orin jade fun won.

“Ko se ni to se tan lasiko ta a wa yii lati gbe enikan jade faraye, onikaluku maa ja fori ara e ni, Pasuma ko le gbeeyan jade, bee naa ni Saheed Osupa tabi Malaika. A gbodo ja fori ara wa ni.”

O wa lo akoko naa lati gbawon oloye tuntun egbe naa nijoba ibile Abeokuta North lamoran pe ki won rii daju pe won n wa alaafia ati isokan ninu egbe naa lasiko ti won yoo lo.

Awon omo egbe tuntun naa ni Ogbeni Fatai Arowora, alaga; Ogbeni Ibrahim Adeyemi, igbakeji alaga kinni; Arabinrin iyabode Asabi, igbakeji alaga keji; Ogbeni Sulaiman Aremu, akowe; Ogbeni Moshood Ololade, akapo; Ogbeni Adeboye Ajani, akowe owo; Ogbeni Kabiru Akanni, alabojuto egbe; Waheed Alamu, Provost ati Olawale Ajao toun je Organizing Secretary.

Bakan naa ni won tun lo anfaani ojo naa lati fi si akanti ile ifowopamo fawon omo egbe naa kaakiri ipinle Ogun, eyi ti yoo mu kawon eeyan tete maa dawon mo nigboro peluu kaadi idanimo (ID Card) ti banki naa fee pese fun won.

Alaaji Adeyinka tun so siwaju pe ayipada to ti pada sinu egbe latigba toun ti depo naa ko se e ka tan, lara e ni ti igbese sisi akanti ile ifowopamo, eyi ti ko seyin ti ipenija tawon ni lati ko awon omo egbe kaakiri orileede Naijiria papo soju kan, iyen Data Base tawon ko tii ri se.

Alaga tuntun, Ogbeni Famous Fatai Okiki Arowora topo mon si Mista Packaging so pe “Egbe yi ti wa tipe, o si maa je nkan to maa dun mo wa ninu ti idagbasoke ba n de ba egbe yi peluu igbiyanju wa, bo tile je pe a o le ka a tan. A o fe iwa jatijati ninu ise Fuji mo.

“Ni ijoba ibile temi, mo n gbiyanju lati fo idoti yen mo, nitori awon eeyab gba pe awon janduku lo n korin Fuji, ti ko si ye ko ri be. Ko seni ti kii korin Fuji, bawon Kristeni se n ko o, bee naa lawon Musulumi n ko o, bakan naa lawon esin abalaye naa n ko o.

“Sugbon o wopo ninu Musulumi ni won se ro pe awon nikan ni, gbogbo eya lo n ko o, ebun lo si je feni t’Olorun ba fun lebun e lat ko o. Laye atijo ni won n fenu idoti ko Fuji, igba ti yi pada to je pe awon to n kekoo jade nileewe giga ti n ko o. Opo awon ti won n niwe eri tele ti lo n kawe sii.

O wa dupe lowo awon omo egbe paapaa gomina won fun iggbarukuti won lati je ki ayeye naa wa si imuse. O si seleri pe oun yoo sa gbogbo agbara oun lati je kawon omo egbe to si sako lo pada sinu egbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI