Baba agbaaya to fipa bomodun meje lopo l'Ota dero atimole - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 11, 2017

Baba agbaaya to fipa bomodun meje lopo l'Ota dero atimole

Opo awon to gbo sisele baba agbaaya eni odun merindinlaadota, (46), Ezekiel Adegbenga to fipa ba omo to je ko je gege bi omoomo e lopo n'Iyana Ilogbo, Ota ipinle Ogun lo n so pe a fi ko ku sewon, nitori bo se baye omolomo je lati kekere. 

Ojule kerin, adugbo Olufunmi Ajayi nisele naa ti waye ni nnkan bi aago merin irole ojo Wesde ose to koja yi nigba ti won so pe asiri Ezekiel tu si iya omo naa lowo. 

Ohun taa gbo ni pe iya omo yi lo sakiyesi awon ayipada kan lara omo e lasiko to n we fun un niwaju ita ile won, nibe la gbo pe o ti beere awon oro kan lowo e, tomo naa so pe Dadi lo se kinni foun. 

Obinrin yi ko koko gba omo e yi gbo pe boya ko mo nnkan to n so, sugbon bomo naa se m soro lo je ko yee pe ko si iro ninu nnkan to n so jade lenu. 

Bo se di pe o pariwo sita pe kawon araadugbo gba oun, Ezekiel ti baye omo oun je, o ti fipa bomo oun sun. 

A gbo pe Ezekiel ko si nile lasiko naa, igba to maa pada wole ni nnkan bi aago meje irole, Oju ona ni won ti gbe ija ko o, toro naa si di isu ata yanyan. 

Eni to ta wa lolobo je ko ye wa nise ni Ezekiel koko se ni eni ti ko mo nnkankan, tawon eeyan si ni ki won gbee lo tesan, ibe lo ti maa jewo towo olopaa ba te e. 

Looto nigba ti won de be la gbo pe Ezekiel ti so fawon olopaa pe ki won se oun jeje nitori pe ise esu ni. O lasiko tawon obi omo yi jade jade loun dogbon tan an wole lati ran an nise. 

Bee lo so pe igba kan pere loun se kinni naa fun, no tile je pe oun ko le so emi to gbe ounje wo lojo naa, nitori pe leyin toun se tan loju oun too da. Lesekese lo so pe oun ti be omo yi pe ko daso asiri boun, ko ma so fenikan, toun si ra nkan fun.  

Ahmed Iliyasu to keep komisana olopaa ipinle Ogun nigba to gbo soro naa lo ti pase pe oun fee foju kan an, ti won si gbee e lo ba a ni Eleweran nibi to to n gbategun bayii. 

Bo tile je pe  Iliyasu ti tare e sodo eka olopaa to n ri si lilo omo nilokulo, sibe o ni lai pe ni Ezekiel yoo foju bale ejo latigba idajo to to sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI