Ko sigba taa si ni pada si ese aaro - Mikky Kazzim - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 23, 2017

Ko sigba taa si ni pada si ese aaro - Mikky Kazzim

Onarebu to n soju ekun Obafemi Owode, Abeokuta North ati Odeda Federal Constituency nile igbimo asofin agba nilu Abuja, iyen Onarebu Mukaila Olayiwola Kazzim so pe ko si nnkan to le je ki orileede Naijiria nilosiwaju lasiko taa wa yi, bi ko se pe ka pada si ese aaro wa taa ti gbagbe.

L’Ojobo Tosde to koja yi ni Onarebu Kazzim lo soro yi nibi ayeye to ti si iso gaari igbalode fegbe awon oni gaari ninu oja Kila nijoba ibile Odeda, nibi ti ese ko ti gbero, tawon ara oja si mu orin ope bonu pe idagbasoke nla ti n de ba agbegbe won.

Ninu oro e, o so pe “Atunto, atunto la n pariwo, sugbon a fi ka pada si ese aaro wa, ka pada si gbogbo awon nkan taa ti se tele. Ka pada si ise ogbin ti won ti pariwo lati ojo yi, kii se pe nkan tuntun la sese fee loo se, nnkan taa ti n se tele ni, o kan je pe epo lo so wa di ole (lazy) nigba yen taa se fi sile, to je pe a o ri nnkan gbajumo ju epo lo.

“A ti n pa owo repete tele nidi ise ogbin, nitori pe nigba taa wa ni kekere, a ni epa, ororo, timber, ti e ba si wo owo ta n na nigba yen kobo marundinlogbon (25kobo), koko (cocoa) ni won ya si, awon to n gegi ni won ya si aaodota kobo (50kobo), eyi tunmo si pe ibi taa ti n ri owo niyen.

“O pe gan ki won to sese maa ya epo sori owo wa, nitori e la se ni ka pada si ese aaro wa, ti a ba n ri owo nibe, nnkan ti epo ba n mu wa, afikun lo kan maa je fun wa, ara atunto ta n so niyen, nitori pe fun idagbasoke orileede Naijiria ni.”

Nigba to n soro lori wahala awon omo egbe IPOB nile Yibo, o ni “Gbogbo wahala to n sele yen kan n se omo oloku bee ni, won ko le sin in pelu iya e. pupo ninu won ni won ko tii bi nigba yen ti ogun Ojukwu bere, nitori pe won ti iru awa yi, bo tile je pe a si kere, sugbon a foju rii, awon eyi taa ri, a gbo o.


“Eni to ba ri nkan to sele nigba yen ko ni gbero fun nkan ti won tun fe e maa se yi mo, nitori pe ko seni to gbadura fun ogun, ogun kii bimo to daa. A ni lati yi ironu won pada, ka so atubotan e fun won, ko digba taa ba bere sii ta eje sile. a ni lati je ki won mo pe alaafia lo se koko, nitori oe ti alaafia ba wa, onikaluku lo maa gbe igbe aye to dara.”

Bakan naa nigba to soro lori iso igbalode tuntun to ko fegbe awon oni gaari, o ni lara awon ileri taa se fun won ni, a si gbodo muu se fun won, nitori pe waon ni won ran wa lowo lati depo taa wa lonii.

Ninu oro e, “Kekere si leleyi, elo min in to ba debi pe oun fee ra gaari, ti ojo kaa mo, ko nii sibi to maa sa si, ojo maa pa won pelu gaari ati elubo ni, eyi lo je ka tete gbe igbese yi. Gaari ti omi ba ti wok o see ta mo, ko digba ti won ba beere ka to se e fun won nitori pe aarun oju ni. Ko sibi ti won kii tii je gaari kila lorileede yi paapaa lawon orileede kan lagbaye.

“Nkan to ku taa tun fe e se bayii ni ti oro mi, ati ile iyagbe to dun un wo loju, won nile iyagbe kan ti won n lo, sugbon ko boju mu to nitori pe ko si omi nibe, o di dandan ka se e, sugbon nipele-nipele la maa se e. Eyi to se koko ni bi owo se maa wole lati fi gbo bukata ara awon ati ebi won.”

O wa ro won pe ki won tubo fara bale foun lati tubo se awon eto lati mo awon nnkan amayederun wa fun won lai pe.

Nigba toun naa n soro, alaga ijoba idagbasoke Orile Ilugun, Arabinrin Mofoluke Soremekun dupe lowo Onarebu Kazzim fun idagbasoke to n mu wo agbegbe naa, bee lo dupe lowo ijoba Gomina Amosun fun akitiyan e lati mu idagbasoke ba gbogbo awon agbegbe nipinle Ogun.
O so pe isoro tawon ni ninu oja naa ko pe meji, bi ko se ti wahala ti babaloja, Oloye Dele Idowu n fawon ara oja yi lo latari bo se n gba isakole lowo won, to je pe ere to ye kawon eeyan naa je lo n gba lowo won gege bi isakole.

Arabinrin Mofoluke to tun je Diakoni (Deaconess) so pe gbogbo igbese ati akitiyan lawon ti gbe lori oro naa sugbon to si n ja si pabo, nitori gbogbo ona to ye kijoba idagbasoke naa maa fi ri owo ati lati maa fi pawo wole sapo ijoba ipinle Ogun ni babaloja naa n di mo won, to tun ti gbe won lo sile ejo lori e.

O wa rawo ebe sijoba pe ki won tete ba awon da Oloye Dele Idowu lowo ko, nitori pe tipatipa lo fi n gba oja lori awon oloja to n wa sise aje tori ran won, to si tun n pa won lara ninu okoowo won.

Alaga egbe oni gaari, Alaaji Tajudeen Lamidi topo mon on si Agbelere nigba to n b’AWIKONKO soro so dupe lowo Onarebu Kazzim fun ife to ni si won lati mu ki nnkan rorun fun won. o wa lo asiko naa lati fi ro Onarebu naa pe ko bawon wa nkan se soro babaloja, Oloye Idowu ati iyaloja won, Arabinrin Adunola James lori ona ti won ba fitinati won ninu oja naa.

O ni awon eto to n beere fun ti koja agbara awon, to je pe gbogbo ee to ye kawon maa je lori oja tawon n ta ni Oloye Idowu atawon oloye n gba lowo awon gege bi isakole, ati pe ijoba lo leto lati gba owo ori lowo awon.

Bee naa ni igbakeji alaga egbe oni gaari, Arabinrin Folake Jinadu so pe yato si tikeeti oja tawon n ja, babaloja naa tun n gba isakole lowo won, to si je pe gbogbo ere to ye kawon je lori oja won lawon fi n san isakole. 

Lati gbo tenu babaloja ati iyaloja naa, awon mejeeji so pe ko si nkan tawon fee so nitori pe se ni won lo anfaani sisi iso gaari lati wa fi yeye awon lojo naa, bo tile je pe awon ko fee yoju tele, sugbon tawon kan be awon pe kawon wa.

AWIKONKO gbo pe babaloja, iyaloja atawon kan ti pinu lati ma yoju sibi ayeye naa, sugbon ironu wipe won maa ri owo gba lowo Onarebu Mikky Kazeem lojo naa lo gbe won wa, gbogbo bi won si se wa nibi ayeye ni inu won ko dun pelu bawon eeyan se foju tembelu won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI