Mr Paragon sayeye ojo ibi aadota odun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 30, 2017

Mr Paragon sayeye ojo ibi aadota odun

Ese ko gbero ni gbongan ayeye igbalode DLK to wa niluu Abeokuta lojo Sande to koja yi nibi ti okan lara awon gbajumo agba osere to filuu Abeokuta sebugbe Emir Kayode Akindina ti ayeye ojo ibi aadota odun loke eepe.

Bawon osere nipinle Ogun se yabo gbongan ayeye naa ti Alaaji Wasiu Alabi Pasuma ti dalu bole fawon alejo pataki, bee lawon osere lati ipinle Ekoo at’Oyo naa ko gbeyin lojo naa.

Awon Oba alaye bii; Alawowo tiluu Awowo; Oba Rasheed Abdulahi Adewale, Olu Iwo tiluu Iwo ati Eselu tiluu Eselu lo wa lori ijokoo, to fi mo Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ti akowe ipinle Ogun, Taiwo Adeoluwa soju fun atawon oloselu bii Gboyega Nasiru Isiaka, GNI; Onarebu Adijat Adeleye.

Lara awon olorin to tun korin lojo naa ni Alaaji Sefiu Alao, Baba Oko; Beulah; Boye Best atawon olorin takasufe lorisirisi. Awon maketa bii Tenten Pictures ati Alaaji Kazeem, iyen Epsalum ko gbeyin, to fi mo MC Oluomo.

Nigba to n soro, Omoba Dele Odule to je Aare egbe osere TAMPAN, o so pe “Mo ki olojo ibi oni, Oloye Diakoni Emir Kayode Akindina ku ayeye aadota odun, a a se opolopo e laye ninu alaafia, owo aiku baale oro. Wiwa sibi mi lonii, ona meji lo pin si. Akoko ni pe, gege bi osere ti eni to n se ayeye aadota naa je osere, to tun je ninu egbe kan naa, TAMPAN taa jo wa, eto mi ni lati waa se ojuse mi gege bi aare. Eleekeji ni pe, oro ti mo fee so yi, e ma binu, e ma rii bi igberaga. Mo wa gege bii baba osere nipinle Ogun.

“Nigba ti mo n sayeye ogoji odun ti mo bere ere ori itage, opo awon eeyan ni won n so pe ko ri bee. Mo so pe ko le ye won, sugbon yoo ye won lola. Osagie wa nibi, igba ti mo lo sileewe awon olukoni (Teachers’ Training College) to wa ni Oru ni mo pade Osagie. Sugbon Osagie funra e mo wipe ipile ise tiata ni mo ti n bo.

Bee lo tun lo anfaani naa lati gboriyin fawon osere tiata nipinle Ogun, o ni “Mo dupe fun nkankan nipinle Ogun, mo si gbodo f’onte luu. Awon omo ipinle Ogun nikan lo n se deede, won n sise takuntakun gan an, won n fi gbogbo ara sise gidigidi. Inu mi dun pe mo je oomo ipinle Ogun, mo si le fowo e soya pe omo ipinle yi ni mi, nitori pe won n gbiyanju gan an, to ba ti doro ka sise tiata.

“Oro won kii se ka soju aye, tabi ka ri mi, bi ija ba wa nibe, e je ka mu yen kuro. Won n sise takun-takun, idi ni yi to fi je pe awon ni won n tayo ju, ko si jo mi loju. Olorun Olodumare ma ko si ni je ki won wale.”

Lakotan, Omoba Odule so pe “Nigba ti won mu iwe ipe (invitation card) wa ba mi, mi o ti e mo pe o ti pe aadota odun, abajo to fi n gbena woju awon booda e, a se oun naa rii pe oun ti dagba ni, ko le gbena woju mi nitori pe booda ni mi. Aadota oodun kii sere rara, ki Olorun je ki eni ti ko tii pe aadota odun, ko pe e pelu alaafia.

“Beeyan ba pe aadota odun, o ti koko jagunmolu akoko naa, o loju eni to le jagun akoko, ko wo aadota odun. Amoran mi ni pe ki Kayode loo sinmi naa fungba die bo se pe aadota odun yi, obi to ba fara sin lo maa n gbo. To ba ti pe odun mejilelaadota, ko tun bere ise lojuu pereu, titi to maa fi pe odun mokandinlogota.

“To ba ti waa pe ogota odun, nnkan to ba fee se, ko tesiwaju, nitori pe orun t’olomo nla naa la jo n lo.”

Alaaji Ebun Oloyede, Olaiya Igwe nigba toun naa n soro so pe, “Kayode Akindina to n se ayeye aadota odun lonii, awon elomin le maa ro pe bo ya ko to bee nitori pe o n ge irun e lo sile, o tun loju omo kekere, agbalagba arugbo ni. Omo Akindina ti mo mo ti to ogbon odun tabi ko ju bee lo die, sugbon tori pe won n se ni ‘Sir Kay’. Bee naa ni Pasuma toun naa fee se ayeye aadota odun bayii, awon eeyan lo n so pe ko to be. O n dogbon sii ni, o ju bee lo, o n din ojo ori e ku ni, sugbon tori pe e n pe ni Paso, agbalagba ni.

“E fi temi sile, awon kan ni mi o to iyen odun ti mo to, o temilorun bee, K1 ni mo fi jo. Sugbon nigba ti won ba ni ki baba yin wa gba boolu lori fiidi, ti mo ba danu, e e mo pe mo ti gbo, ko ye opolopo yin ni. Olorun oore ofe lo n funni lebun beeyan ba se ri. Agbalagba ni wa, eeyan ko kii gbo nidi ise tiata ni, ojoojumo la n dagba, sugbon e lo ro pe a o to bi a se pe ara wa. Eni to ba fi ojo ori kun ti e, o n ranse pe saare ti won maa sin in si ni.

“Kayode Akindina ko gba iranu laaye, o n bowo fagba gidigidi, sugbon ko ni faaye gba iranu. Ti e ba pe e pe ko waa ba a yin kopa ninu fiimu, ti e si fun un ni ipa ogun lati ko, to ba ti baa yin se mewaa, adura ni ki e maa gba lati pari eyi to ku, ki e si tete maa bere laaro tabi losan, nitori pe ko baa yin bo soju kamera ti aago meje irole ba ti lu.

“Awon omo Kayode ko nii ji Kayode lai kii se pe o ba ji funra e. O ni ilana ati ikora-eni-nijanu lori bo se n se nkan e. Kii sin owo, ti o ba lowo, o nii sapo ara e ni, sugbon o maa pon e le. Aburo mi daadaa ni Kayode Akindina. O kose tiata lati ibere dopin, o si mo nipa e daadaa. Ninu awon wonran-wonran to maa n se, eyi to ji lara mi lo po ju nibe, ninu ka kopa, eyi to ji lara mi wa nibe.

“Ju gbogbo e lo, nnkan ti mo fee so ni pe, nnkan ti onikaluku ba n se, ojo ori e lo lojoojumo, Olorun a je ka pe laye, a o si nii finira logba. Nitori naa, maa fi asiko yi ki e kuu oriire pe waa se opolopo odun laye pelu ifokanbale. Bo o se nirawo yi, ko nii ku, wa a tun rowo fi lo.”

Saaju akoko yi ni Amofin Taiwo Adeoluwa ti so pe “Mo fee fi tokan-tokan so pe inu mi dun pe mo wa nibi lati soju oga mi, ati lati soju ara mi. Inu wa maa n dun nipinle Ogun lati bu ola fun awon to ba je ti wa, eyi ti Mista Paragon je okan lara won. A wa nibi lati sajoyo pelu eni to ti ko ipa ribiribi, to tun ti ko awon eeyan lekoo.

“Nitori pe e je gbajumo, ko je ki e le mo iyi lati maa sajoyo ara yin. Mo maa n so fun Mista Latin ni gbogbo igba pe eyin diigi (mirror) tawon eeyan to wa nita fi n wo wa, eyin ni diigi ti a lo anfaani. Nnkan ti eyi elere ba so pe a je naa la je, nitori e la se maa n wa anfaani lati fi emi imoore wa han pada sii yin.

“Nigba taa de lodun 2011, awon die ni won gba wa laaye, sugbon fun ifowosopo ati igbarukuti gbogbo yin, paapaa julo agboole eyin osere tiata, Olorun se iwon to lee se. Lonii, a wa n dupe lowo Olorun foun to ti se fun wa, a o si le ma fi emi imoore wa han sii yin.

“Mi o mo pe omo kekere gan an ni Emir, Mista Paragon niori pe awon fiimu yin ti poju iyen ojo ori yin lo. Nigba ti e wa pe e fee sayeye aadota odun, mo ni mi o ti e mo pe omo kekere lawon eeyan yi sa. Eku oriire nla. Mo maa n fi yin yangan, ipinle Ogun naa si n fi yin yangan. Boya e fe tabi e ko, e pelu awon to n gbe ogo ipinle Ogun soke.”

Nigba toun naa soro, olojo ibi funra e, Kayode Akindina so pe ko si nkan meji toun fee so ju pe koun dupe lowo Olorun lo, nitori pe opo ojo loti ro, opo iji lo si ti ja, sugbon ti Olorun moun bori e.

O wa dupe lowo awon alejo atawon to sagbateru ayeye naa pe ko le lo bawon se lero.

Lara awon osere to tun wa nibe lojo naa ni Omoba Dele Odule; Otunba Bolaji Amusan, Mr Latin; Omoba Yomi Osagie; Omoba Surajudeen Adewunmi Dagilapa, alagba egbe TAMPAN; Saheed Balogun; Faithia Balogun; Odunlade Adekola; Alaaji Waheed Ijaduade, Dimeji; Akeem Alamutu, Eba; Yinka Adebanjo; Baba Super; Ganiyu Edunjobi; Monsuru Ijayegbemi; YS Kareem; Yemi Adegunju; Afeez Owo Abiodun; Muyiwa Ademola; Toyosi Adesanya; Olaniyi Afonja, Sanyeri; Segun Ogungbe; Eniola Ajao atawon min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI