Olaiya fibinu sepe fawon onitiata to loun kii s'Oba won - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 30, 2017

Olaiya fibinu sepe fawon onitiata to loun kii s'Oba won

L’Odunlade ba ni ko fi ko ma sepe mo

Kekere lawon eeyan koko pe oro naa tele, sugbon to je pe se lo koja oju tawon eeyan fi woo nigba ti okan lara awon agba to tun je gbajumo nidi ise tiata, Oloye Ebun Oloyede tawon eeyan mo si Olaiya beere sii fibinu soro sawon to n so pe oun kii se oba tiata.


Bo tile je pe se lawon eeyan ro pe Olaiya tawon eeyan tun n pe ni Igwe muti yo lojo naa ni, sugbon tawon kan so pe nnkan to wa lokan e lo so jade sita, ti ko si muu loro awada rara.

Igwe lo fibinu soro lakoko to n soro nibi ayeye aadota odun okan lara won ti won se lojo Sande to lo lohun niluu Abeokuta. Won loro naa ti n ja rain-rain nile tipe pe se lokunrin naa deedee maa pe ara e ni l’oba tiata, iyen ‘King of theatre’.

O so pe kii se pe oun deedee ji lojo kan lati so pe oba tiata loun, awon akekoo fasiti Obafemi Awolowo ni won wo sunsun leyin ti won ri ipa toun n ko nidi ise naa lati foun loye naa, ti won tun dana ayeye nla.

Ninu oro e lo ti so pe “Mo tun fee fasiko yi se atunse lori oro tawon kan n so pe mo n pe ara mi ni oba awon oni tiata (King of Theatre). Nigba ti won fi mi je oba tiata ni Fasiti Obafemi Awolowo, egbon mi Dele Odule wa lori ijokoo; Mista Latin, aburo mi wa lori ijokoo; Clarion Chukwura wa lori ijokoo, kii se pe mo ji lojo kan, mo pe ara mi l’oba yin. Bi o mi o ba waja, e o le je min in nigba tee ya were. Ko si baba nla enikeni to le dide pe ara e l’oba. Mo gba opa ase, bi ko ba ti e gun.”

Bo se soro yi tan ni Odunlade Adekola ba soro sii leti pe ita gbangba lo wa, awon oniroyin si wa nibe, won le gbe e ju bo se ye lo, loun naa ba tun fogbon yi oro e pada pe “E o le so pe mi o kii se oba yin, nigba to je pe oloriire ni yin, nitori t’Odunlade so fun mi pe e o kii se were, e ma binu pe mo so bee, mi o ni so bee mo, mo ti satunse (point of correction). Odunlade naa n dogbon koreeti baba e.

“Nipa bee, won fun mi lopa kekere kan ni fasiti Ife (University of Ife), sugbon ko gun to debi pe mo le maa fopa naa tele kaakiri. Opa naa wa ninu ile e, sugbon Igwe yin, oga yin lo n soro yi. Iwe eri tun wa, to tii nidii, mi o di oba yin lojiji o. Ki e si maa reti lati je oba min in leyin ti mo ba ku, iyen leyin ti mo ba pe ogofa odun (120years).”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI