Nitori ayeye ogoji odun nidi tiata to se; Dele Odule fibinu soro sawon osere tiata - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 30, 2017

Nitori ayeye ogoji odun nidi tiata to se; Dele Odule fibinu soro sawon osere tiata

Mo saaju Osagie bere ise tiata

Omoba Dele Odule, to tun je Aare egbe osere tiata TAMPAN lorileede yi ti so pe kawon eeyan lo gbenu dake lori itan ti won o mo, ti won n so kaakiri, ati pe oun saaju Oloye Osagie bere ise tiata, awon kan le jo da egbe sile lasiko kan  naa ni.

Dele Odule soro naa lai pe yi niluu Abeokuta, o leti oun ti kun lakoko toun n palemo ayeye ogoji odun nidi ise tiata, ati leyin ayeye naa pe oun ko tii pe ogoji odun nidi ise tiata, oun fi odun kun un ni.

O niyalenu lo je nigba tawon eeyan n so pe oun fodun kun iye odun toun ti bere ere ni, ati pe pupo ninu awon to n gbe iroyin naa kaakiri ni won ki tii bi nigba toun bere nitori pe odun 1982 loun di akowe fegbe ANTP toun wa tele, toun si di igbakeji aare lodun 1995.

Ninu oro e, o so pe “To ba je oselu igboro ni, iyen partisan politics, emi ni mo dagba ju ni gbogbo ipinle Ogun gege bi adari. Kii se pe emi ni mo dagba ju lojo ori, sugbon ni ti ipo. Igba ti mo maa di akowe agba fun egbe osere ANTP, opo awon to wa nibi ni won ko tii bi, kii se pe won ko tii bere ere tiata ni mo n so o, won o tii bi won ni. Mo di akowe fun egbe osere ANTP, eka tipinle Ogun lodun 1982.

“Awon to wa ninu egbe nigba naa ko to nkan. Odun 1995 ni mo di igbakeji aare egbe ANTP, ka sese to maa menuba awon eyi to tele. Nipa oore ofe Olorun, emi ni aare akoko ti won dibo yan fegbe TAMPAN ta n se lonii. To ba je gbogbo nkan la maa ka po, e e mo wipe ko tii si enikankan nipinle Ogun yi ninu yin to tii de ipele yen. Ti m ba wa so pe mo wa gege bi baba osere nipinle Ogun, se mo si so ni.?

“Nigba ti mo n sayeye ogoji odun ti mo bere ere ori itage, opo awon eeyan ni won n so pe ko ri bee. Mo so pe ko le ye won, sugbon yoo ye won lola. Osagie wa nibi, igba ti mo lo sileewe awon olukoni (Teachers’ Training College) to wa ni Oru ni mo pade Osagie. Sugbon Osagie funra e mo wipe ipile ise tiata ni mo ti n bo.

“O mo pe won mu mi kuro leyin elere wa sileewe ni. Owo ti mo fi ran ara mi jade ileewe olukoni, idi ise tiata ni mo ti pa a. Awon kan so pe sebi emi ati awon Osagie jo bere ere tiata nigba kan naa ni, o le ri be looto nitori taa jo da egbe sile, sugbon ipile ere le mi ti n bo, bo tile je pe kii se oro ojo tonii. Mo kan sare yan fun un yin ni. Odun 1977 gangan ni mo bere ise tiata, iyen ogoji odun seyin.”

Bee lo gboriyin fawon osere tiata nipinle Ogun, o so pe “Mo dupe fun nkankan nipinle Ogun, mo si gbodo f’onte luu. Awon omo ipinle Ogun nikan lo n se deede, won n sise takuntakun gan an, won n fi gbogbo ara sise gidigidi. Inu mi dun pe mo je oomo ipinle Ogun, mo si le fowo e soya pe omo ipinle yi ni mi, nitori pe won n gbiyanju gan an, to ba ti doro ka sise tiata.

“Oro won kii se ka soju aye, tabi ka ri mi, bi ija ba wa nibe, e je ka mu yen kuro. Won n sise takun-takun, idi ni yi to fi je pe awon ni won n tayo ju, ko si jo mi loju. Olorun Olodumare ma ko si ni je ki won wale.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI