Nitori eran Ileya; osise ijoba koju ija sawon araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 8, 2017

Nitori eran Ileya; osise ijoba koju ija sawon araalu

Iyalenu loro naa je lojo Tusde to koja yi nigba ti okan lara awon osise ijoba ipinle Ogun nipa eto ipawo wole ati okan lara awon to wa ra agbo odun Ileya koju ija sira won nitori owo ori.

Gege b'AWIKONKO se gbo, Muhammad Sanusi la gbo pe o lo si Oja Olomore nijoba ibile Abeokuta North-East ipinle naa lati loo ra agbo Ileya, to je egberun marundinlogoji (35,000) naira.

Sugbon nigba to ra eran agbo naa tan, ni osise ijoba yi loo ba a pe dandan lo gbodo san owo ori eran agbo to ra, eedegbeta (500) naira.

Ohun taa gbo ni pe, se ni Muhammad lanu sile pe igba wo ni sisan owo ori lori oja teeyan ba ra tun bere nigba ti kii se pe akoko re e toun maa maa ra iru nnkan bee.

A gbo pe Muhammad so pe oun ko le san owo naa nitori pe ko si ninu iwe ofin lati maa san iru owo bee, sugbon nkkan taa gno pe osise ijoba naa so pada ni pe dandan ni ko san an motori pe igbese tintun ti ijoba ibile idagbasoke naa sese sagbekale e ni.

Eyi lo fa a tawon osise ijoba se pe afi kawon gba eran agno naa sile digba tokunrin naa yoo fi pada wa a san owo eedegbeta naira naa fun won kawon to yonda e fun un lati maa muu lo.

Bo se di pe awon mejeeji gbena woju ara won re e, ti won si fe maa lu ara won ko too di pe awon toro naa soju e ko si won laarim pe ki won ni suuru funra won.

Nigba to n bakoroyin wa soro, Muhammad so pe iyalenu loro naa je foun nitori pe oun ko gboru oro bee ri laye oun, o ni bi eni to fee fowo ola gba oun loju lo ri.

Ninu oro e, o ni "Mi o lowo kankan lati so, nibo ni won ti n seru e. Ki won gbe mi lo sibikibi, mo setan lati tele won, koda to ba je ile ejo ni. Mi o gbo ri pe won n san owo ori lati pa eran ti a ba ra fun Ileya."

Bee ni okan lara awon toro naa soju e, toun naa wa ra eran, ti ko setan lati daruko e fun wa so pe ona eburu lawon osise ijobaa naa tu fee gba lati maa fi lu awon araalu ni jibiti owo, ti won pe ni owo ori.

Nigba toro naa koja oju tawon eeyan fi pe lo faa tawon oloye oja naa fi sepade pajawiri pelu awon osise ijoba naa,sugbon leyin ipade la gno pe won ti fi owo naa sinu abadofin ipawo wole sinu apo ijoba ibile idagbasoke naa.

Nigba to n soro oludari eka (Veterinary Services) nipinle Ogun, Dokita Dotun Sorunke to lewaju iko to loo sabewo soja lojo naa nigba to n soro so pe igbese tuntun ni, awon ko si le yii pada.

Ninu oro e, "A ri gege bi anfaani lati maa fi ri owo. Ti won kii ba a se be e tele, iyen o tunmo si pe won tun ni se e nitori pe ofin si wa. Onikaluku lo n wa ona lati fi pawo wole sapo ara e."

Bakan naa ni olori oja Olomore, Alaaji Seni Folarin so pe gnogbo igbese lati petu sawon osise ijobaa naa ninu lo ja si pabo, toun si ri gege bi ona lati le awon onibara jinna si oja naa.

Bee ni Arabinrin Kehinde Shodunke to je okan lara awom to n ta eran loja naa fehonu han pe iwa odaju lawon eeyan naa hu nitori pe owo ti won n gba yen ti poju nnkan tawon araalu le maa san.

O ni pe eeyan wa ra eran ko tunmo si pe owo wa lowo won, onikalu lo nibi ti bata ti n ta lese, wipe eeyan ko owo wa ra eran ko tunmo si pe owo wa lowo won. O lelo min in wa to je pe o lo ya owo lati wa fi ra eran Ileya ni.

Gbogbo igbese lati ba alaga ijoba ibile idagbasoke naa soro lo ja si pabo, bee naa ni ako ri komisana foro ipawo wole sapo ijoba ipinle Ogun soro titi digba ti a fi n sakojopo iroyin yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI