Gbogbo awon to gboro
lenu Kelani Azeez, eni odun metalelogbon ti won loo sere ore e, David Adima,
eni odun mejilelaadota lada pa nitori paki e to ji wu lose to koja n'Ibogun lo
mo pe ejo e lowo ninu.
AWIKONKO gbo
pe, asiko naa ni David loo lati wo nnkan to n sele ninu oko e, sugbon nigba to
maa de be, Kelani lo ri to n wa paaki, won loo ti ji apo paaki kan wa.
Eyi gan an ni won
loo bi David ninu, to si pariwo lee lori pe ki lo de ti ko so foun, ko too wonu
oko oun wa, nnkan taa gbo pe David so fun Kelani re e, to fi daa lohun pe oun
ko nilo lati Gba ase koun too wonu oko naa.
Won loo so pe oun
loun ya David nile to fi da oko si, nitori loun ko se nilo lati gbase lowo
enikeni, nitori pe oun maa di lase lori oko naa. Nibe ni won so pe David ti
gbana je, tawon mejeeji si bere sii fa oro naa mo ara won lowo.
Ko pe ti won lawon
mejeeji bere sii tahun sira won la gbo pe David ti sunmo Kelani ti won si bere
sii lu ara won ninu oko to wa labule Sojulu, Alaparun nijoba ibile Ifo, ipinle
Ogun.
AWIKONKO gbo pe
nigba ti Kelani rii pe agbara oun ko fee ka David mo, lo fi sare fa ada, to si
fi sa a lorun, leemeeji, tiyen si ku.
Won ni nigba ti Kelani
rii pe David ti ku, Lo fi sare gbe apo isu kan to ti ji wa, to si salo, sugbon
ti ko mo pe okunrin kan to n je Peter Ator rii, lakoko to n salo pelu apo paaki
naa.
Ojo keji leyin ti
won ri oku David nibi to wa, lariwo ta kaakiri abule, tiroyin si kan si Peter
ti won loun lo lo foro naa to awon olopaa leti. Peter so pe bi tile je pe
oun ko mo nkan to sele, sugbon pelu boun se rii, Lo je koun fura sii.
Oku David |
Bee la gbo pe Baale
Abule naa ti pase pe ojo ti won ba tun mu pe o jale, awon yoo fi seleya kaakiri
inu abule kawon too lee danu.
A gbo pe inu ahere
kan ti Kelani loo sapamo si kasiri e ma baa tu sita lawon olopaa ti loo mu.
Nigba to n dahun
ibeere logba olopaa to wa ni Eleweran lose to koja, Kelani so pe oun kabamo iwa
odaju toun hu, no tile je pe oun ko lero lati seku pa David, baba olomo merin
lojo naa, ise esu ni.
O ni "Ko sowo
lowo mi lojo naa, to fa Ki n fi ronu lati loo ji isu David wa, Ki n le fi ri
owo lati fi se nkan to move fee fi se. Inu oko e lo ti ba mi lojo naa, to si n
pariwo lemi.
"Ko je ki n
soro daadaa lojo naa. Mo ti pinnu lokan ara MI pe ti n ba ta paaki yen tan, maa
yo owo temi, maa si ko owo toku fun. Sugbon ko fee gboro lenu mi. Ada to yo
simi lo je keru ba mi.
"Mo sare gba
ada naa lowo e, mo kan fee fi hale mo ni, mi o mo pe o maa ba lorun. Eru lo ba
mi ti mo fi loo fara pamo, Ki won too wa mu mi. E dari ji mi. "
Ahmed Iliyasu to je
Komisana olopaa ti pase pe ki won loo foju Kelani bale ejo nitori pe ko tun si
iwadii kan tawon tun fee se mo, Tori pe o ti jewo fawon.
No comments:
Post a Comment