Awon adigunjale meji ta teru nipa ni J4 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 16, 2017

Awon adigunjale meji ta teru nipa ni J4

Bi kii ba a se pe awon olopaa Ijebu Ode tete dide lati loo koju awon adigunjale ti won so pe won maa n da awon eeyan lona lopopona Sagamu si Ore, iyen lagbegbe J4 ipinle Ogun, o seese ki won ti na papa bora nigba ti sose won bi won se maa n se e.
 
Gege b'AWIKONKO se gbo, ni nnkan bii aago mesan aaro ojo Eti Fraide ose to koja la gbo pe awon adigunjale naa lo lati lo dawon eeyan lona, ko too di pe awon to ri won ta awon olopaa lolobo.
Ohun ta a gbo ni pe lesekese ni oga olopaa Ijebu Ode ti lewaju awon iko e lati loo koju won, ibi ti won ti n gba dukia awon to ko si panpe won ni won ti ri won.
A gbo pe bawon adigunjale naa ti se ri moto awon olopaa ni won ti koju ibon si won, toro si di boo lo o yago laarin awon olopaa atawpon odaran naa, ko too di pe awon meji fara gbota, ti won si ku lesekese.
AWIKONKO gbo pe owo te okan lara won nigba tawon to ku na papa bora.

Odomokunrin towo te naa, nigba to n soro so pe oun ko si lara awon adigunjale naa, ati pe awon kan ni won pe oun jade kuro ninu Mosalasi toun wa lagbegbe J4, ko too di pe won mu oun.

Nigba to n jeri soro naa ni tesan olopaa Ijebu Ode, Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu so pe looto ni, ati pe lara awon ero ja oloro ti won ri gba lowo won ni ibon ilewo kekere kan, ero ibanisoro kan atawon ero to n pa feere moto, (carton of car sound protector).

Iliyasu so pe okan lara awon adigunjale towo te naa ti wa ni akolo awon, nibi tawon ti n foro wa a lenu wo. O ni leyin iwadii awon, towo si ti te awon toku e to salo, ileejo ni won yoo gbeyin si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI