Nitori eto aabo to pe ye, VSO rawo ebe sijoba ipinle Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, October 14, 2017

Nitori eto aabo to pe ye, VSO rawo ebe sijoba ipinle Ogun

Ki ise eto aabo ba tubo le kesejare sii nipinle Ogun, ajo Fijilante ojulalakanfinsori ipinle Ogun, Vigilante Service of Ogun state (VSO) ti rawo ebe sijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun lati ran won lowo ki ise eto aabo tun le gbe peeli soke sii.

Soji Ganzallo
Nibi ayeye eto ibura fawon oloye ekun Egba, iyen Egba Zone tuntun ti won sese yan lati rii daju pe emi ati dukia awon araalu wa bo se ye ko wa, ko ma si si wahala kankan to jomo iwa odaran mo.

Ayeye naa waye ninu ogba ileese won tuntun to wa ni Arakanga, ijoba ibile Abeokuta North lojo Abameta Satide oni yii, iyen ojo kerinla osu kewaa.

Gege bi a se gbo, won so pe ekun naa ko ni awon irin se ti won le maa lo, eyi to le mu ki ise won rorun lona igbalode lati le maa daabo bo emi ati dukia awon araalu.

Lara awon oloye tuntun ekun Egba naa ni; Salisu Najeemdeen to ke Commander; Ewuoso Sakiru to je igbakeji Commander; Akinwunmi Ismail toun je Administrative; Bode Kusimo toun ni Operation; Osanyinpeju Adewole to wa Finance; Omolaja Bankole toun je Operation II.

Awon min in ni Ogundimu Adebisi toun je Logistics; Akinola Olufunmilayo toun wa ni Anti Human Trafficking; Taiwo Adesegun to je Welfare; Oladipupo Olaifa to wa ni Intelligence ati Mayoade Samuel toun je Provost.

Lara awon nnkan ti won so pe o n je won niya ni moto ati okada ti won le maa fi sise, ibon, ofiisi atawon irinse min in ni won so pe awon n foju sona fun ijoba ibile Abeokuta North paapaa ijoba ipinle Ogun.

Igbakeji alaga ijoba, to tun je oga ajo ipawo wole nijoba ibile naa, Isiaq Bada to soju fun oga e gboriyin fun ajo naa fun ise ti won n se laarin ilu.

Bada so pe bo tile je pe awon ti n da si oro naa lateyinwa nitori pe ijoba ibile naa lo pese ofiisi tuntun ti won n lo naa fun won, si be, awon ko dawo duro nitori tawon mo riri ati ipa ise ti won n se fun won laarin ilu, paapaa nijoba ibile naa.

O wa ro awon oloye egbe tuntun naa pe ki won ma ri ara won gege bi oga, sugbon ki won ri ara won gege bi eni to wa sin ilu e pelu ife to ni sii, ki won si rii daju pe won ko fi oro eleseyameya sise ti won yan won fun.

Nigba to n soro, adari pata fun ajo naa nipinle Ogun, Ogbeni Olusoji Ganzallo nigba to n ba oniroyin wa soro, o so pe bo tile je pe awon ko duro ninu ise eto aabo ilu, tawon sii n ri daju pe emi ati dukia awon araalu je awon logun, sibe awon si nilo ki ijoba tubo pese awon irinse to joju fawon.

Ganzallo so pe ki awon to o pinu lati bura fawon oloye ekun Egba tuntun naa lawon ti n ri ipa ti won n ko laarin ilu lati rii daju pe ise aabo ilu tubo kese jare, eyi lo foun lokan bale pe won a sise ti won gbe le won lowo bo se to ati bo se ye.

adari tuntun
Sibe, adari naa gbawon oloye naa lamoran pe ki won ma se ri ara won gege bi eni to ti de ibi ti won fe e de, sugbon ki won ri ara won gege bi eni to setan lati sin ilu e tokantokan nitori orin ogo ipinle Ogun to so pe "ise ya", won ko si gbodo duro.

Nigba toun naa n soro, adari eka ekun Egba Zone, Ogbeni Najeem Salisu Alao so pe inu oun dun latari bi eto naa se waye, ati pe nnkan toun ti n foju sona fun lati ojo pipe wa ni, nitori toun ti sise sin ajo naa tokantokan.

O ni ipinu toun ni gege bi adari tuntun lekun naa pelu ife toun ni si ipinle oun, loun yoo se rii daju pe ise n tesiwaju ni gbogbo igba.

Salisu wa rawo ebe sijoba ipinle Ogun ati ijoba ibile lati tubo ran awon lowo, nitori tawon nilo irinse bii moto, okada atawon nnkan to le mu ki ise aabo tubo le rorun fawon lati le se aseyori sii.

Saaju akoko yi ni asoju Gomina Ibikunle Amosun, Ogbeni Q.O Usman dupe lowo ajo VSO fun ipa ati akitiyan ti won n ko nipa eto aabo nipinle Ogun, pelu bo se je pe awon nikan ni ijoba fowo si gege bi ojulowo ajo Fijilante.

O loun yoo jise tawon eeyan naa ran oun sijoba, toun si mo pe ijoba yoo gbe igbese to ye le e lori nitori pe gomina to nife araalu lawon ni nipinle Ogun, ti ko si ni doju ti won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI