Soosi ni Oriyomi ti n bo kawon kositoomu to yinbon pa l'Ajilete - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 23, 2017

Soosi ni Oriyomi ti n bo kawon kositoomu to yinbon pa l'Ajilete

Bi ijoba apapo ko ba tete wa nnkan se soro awon eso asobode, kositoomu to n fojoojumo da emi awon araalu legbodo latari bi won lawon n gbogun ti awon oni fayawo, ti won si n paro mo asita ibon, o seese ki omi teyin wo igbin lenu nitori ta a gbo wi pe awon eeyan awon tawon eso asobode kositoomu n pa ti fe e dide ogun si won.


Oku Paul Oriyomi
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo, a gbo pe ojo Aiku Sande to koja yi ni won lawon eso asobode naa tun yinbon pa odomokunrin kan, Oriyomi Paul Ayomaya labule Ajilete nijoba ibile Ipokia nipinle Ogun.

AWIKONKO gbo pe soosi ni Oriyomi ti n bo laaro ojo naa ko to o di pe ibon ba a, to si gbabe dero orun alakeji. Won ni Oriyomi loo tun soosi naa se ko too di pe won bere isin laaro ojo Sande naa, to si n pada loo sile e lati loo mura, ko to o di pe awon oni fayawo naa pa a danu. 


Nise loro tun di boolo o yago lona lojo Aiku Sande to koja yii lagbegbe Ajilete, Idiroko, nijoba ibile Ipokia, ipinle Ogun nigba ti awon eso asobode, Nigeria Custom Service loo kolu awon eeyan to wa nibe, ti won si bere sii da ibon bole lorisirisi.

Lakoko naa la gbo pe ibon ba odomokunrin kan to n lo jeje e, Oriyomi Paul Ayomaya, to si gbabe dero orin alakeji lesekese.

Gege b'AWIKONKO se gbo, won lawon kan to n ta awon eso asobode naa lolobo to tun ta won lolobo wi pe awon onifayawo kan tun ti se fayawo moto tokunbo meta kan wole, ki won si tete wa a dawon lona.

Paul nigba aye e
A gbo pe lesekese lawon eso asobode naa ti gbera lati loo dawon lona, sugbon ti won ko rii nnkan to jo bee. Ko pe leyin ti won bere iwadii la gbo pe asiri enikan lara awon oni fayawo naa tu si won lowo, ti won si gba moto pounpoun Toyota Tundra lowo e.

A gbo pe orileede Olominira Benin (Republic of Benin) la gbo pe awon eeyan naa ti n bo, ti won si fee gba abule Ajilete salo ko too di pe awon eeyan tu asiri won sita.

Lara awon to gbe iroyin naa s'Awikonko leti so pe bi awon toogi kan se rii pe awon eso asobode ti de agbegbe naa ni won ti loo gbe igi ati orisirisi nnkan dina, ki won ma ba a ri aaye lati gbe eyikeyi ninu awon moto naa lo.

Eyi lo fa a ti won fi so pe awon eso asobode naa se fibinu da ibon bole, tawon araalu si bere sii sa kijokijo lati sa asala fun emi ara won, ko too di pe ibon ba Paul lakoko to n lo sile.

Lati fidi isele naa mule, nigba to n b'AWIKONKO soro, agbenuso fun eso asobode nipinle Ogun, Ogbeni Abdullahi Maiwada so pe looto nisele naa, ati wi pe asita ibon lo ba okunrin naa.

Abdullahi so pe awon araalu lo ta awon lolobo pe awon onifayawo ti se fayawo moto meta wonu Abule Ajilete, tawon eso won si tete gbera lati loo dawon lona, ki won si mu won.

O ni nise loro naa yi pada nigba ti won de be, eyi to mu kawon eeyan won bere sii yinbon soke lero wipe awon janduku to fe e koju ija si won yoo salo, lai mo pe omi maa teyin wo igbin lenu.

Iwadii si n lo lowo titi di asiko ti a n sakojopo iroyin yi lowo, ti AWIKONKO yoo si mu abajade e wa fun un yin lai pe. Sugbon si be, ohun ta a gbo ni pe awon eso asobode naa ti fese fe e kuro lagbegbe naa, ti won si loo duro si agbegbe Oke Odan lati yago fun ibinu awon odo ilu naa.

Bakan naa la gbo pe wahala awon eso asobode naa ti po ju, to je pe ojoojumo ni won n da emi awon eeyan legbodo nibe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI