OGD fee pa egbe oselu PDP ni o - Kasamu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 24, 2017

OGD fee pa egbe oselu PDP ni o - Kasamu

Bo tile je pe "ija lo de lorin d'owe" loro tawon eeyan n so nigba ti won gbo pe Seneto to n soju ekun Ijebu East nile igbimo asofin agba niluu Abuja, Buruji Kasamu so pe bi egbe PDP ba fi le yan gomina ana nipinle Ogun, Otunba Gbenga Daniel gege bi alaga apapo egbe naa, ajalu nla ni yoo je.

Kasamu soro yi lati fi tako ipinu Gbenga Daniel, OGD lati di alaga gbogboogbo fun egbe oselu alatako naa, iyen Peoples Democratic Party (PDP) to waye lojo Wesde ose to koja yii.

O so pe OGD ko ye lati di ipo kankan mu ninu egbe oselu naa, depodepo wi pe ko wa a di alaga gbogboogbo fun egbe oselu PDP naa.

Kasamu so pe ere loun koko ro pe Otunba Gbenga Daniel n se nigba toun gbo nipa iroyin e to so pe oun fe e dupo alaga egbe naa, sugbon toun ti wa rii wi pe kii se oro ere rara, o ti koja oju lasan.

Ninu atejade to te AWIKONKO lowo, Kasamu so pe "Nigba ti mo gbo wi pe Daniel fe e lo fun ipo alaga egbe, ero okan mi ni wi pe ere lo n se. Sugbon ni bayii, to ti so ipinu e jade sita lona to ye, maa fi gbogbo enu so o wi pe Daniel ti mu awada naa koja oju lasan.

Nje e ti ka a: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/asiri-iku-to-pa-funke-abisogun-osere.html 

"E je ki n so fun un yin pe Daniel ko ni awon amuye to le fi dari egbe oselu wa. Konkun oju osuwon lati de ipo naa rara."

Kasamu tun so siwaju wi pe iro ni Daniel n pa wi pe oun ti jawe olubori nibi idibo kan to waye. O ni nigba ti Ojogbon Maurice Iwu si wa gege bi alaga INEC, eni tawon ti gbagbe nipa e.

"Lodun 2011 ni Daniel kuro ninu egbe oselu PDP lo sinu egbe oselu PPN ko to tun lo sinu egbe oselu Labour nibi to ti padanu. Bakan naa lo je pe idibo to sagbateru e pelu adije kan toun naa wa nile igbimo asofin (House of Representative), Onarebu Ladi Adebutu, ijakule lo ba pade."

E wo o: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/eyi-ni-bi-gomina-ambode-di-alaga-egbe.html 

"Nigba ti idibo odun 2015 nbo ni Daniel sare pada wa sinu egbe oselu PDP. Won fi je olori olupolongo ibo aare nipinle Ogun, to si kuna koja afenuso latari bi ko se na owo to ye ko na. Oun si leni to je ki egbe oselu PDP padanu ni South West ati nipinle Ogun.

"Titi di asiko yi ni Daniel ko ti le e salaye owo to le ni oodunrun milionu (N300,000,000) naira fun ajo EFCC."

O ma se o: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/awon-eso-asobode-yinbon-pa-paul.html 

O wa a rawo ebe sawon agbaagba egbe oselu naa pe ki won ma se sasise lati so pe won fe e yan Daniel lati di alaga egbe naa nitori pe lakoko to n sejoba nipinle Ogun, opo awon emi lo pa danu, eyi to je pe titi di asiko yi, ko tii seni to le so bawon odo ileewe fasiti Olabisi Onabanjo to to ogofa (120) se ku latari wi pe won ja feto won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI