FUNAAB fee sayeye ikekoo gboye fawon akekoo jade - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 13, 2017

FUNAAB fee sayeye ikekoo gboye fawon akekoo jade

Bee ni won fee yan giwa agba ati giwa tuntun

Gbogbo eto lo ti pari bayii fun ti ayeye ikekoo gboye fawon akekoo to ti kekoo jade lati odun odun 2013 si 2014; odun 2014 si 2015 ati odun 2015 si 2016, ti ileewe giga ti ogbin, Federal University of Agriculture, Abeokuta (FUNAAB), fe e se ninu osu kewaa ta a wa yi bere lati oni ojo ketala.

Gege bi a se gbo, ayeye ikekoo gboye eleekelelogun, ikerinlelogun ati ikarundinlogbon ni won fe e se, ti won si la orisirisi eto arambara olokan-o-jokan kale lati fi mu ki ayeye ikekoo gboye naa larinrin ju eyi ti won ti n se lateyin wa lo.

Lara awon eto ti won ti la kale ni bi won se fe e bere peluu isin nilana Islam, eyi ti won fe e fi si side eto naa, inu Mosalasi to wa ninu ogba naa ni won yoo ti kirun Jumat laago kan osan ojo Eti Fraide, ojo ketala.

Leyin naa ni won yoo se isin Onigbagbo ni soosi Chapel of Grace to wa ninu ogba lojo Aiku Sande, ojo keedogun, laago laago mesan aabo aaro.

Ojo Monde to tele, iyen ojo kerindinlogun ni won yoo pe ipade awon oniroyin ninu gbongan ayeye FUNAAB laago mewaa aaro, nigba ti won yoo se iwadiiijinle ati ipate oja lojo Isegun Tusde, Ojoru Wesde ati Ojobo Tosde laago mewaa ojoojumo.

Ayeye ikekoo gboye naa ti won pe akori e ni “Ounje ati Ojo Iwaju”, iyen Food and the Future la gbo pe Minisita foro ise ogbin ati igberiko lorileede yi, Oloye Dokita Audu Ogbeh ni yoo dawon eeyan lekoo lojo Tosde ojo kokandinlogun, iyen ose to m bo laago meji osan ninu gbogan ayeye FUNAAB, iyen FUNAAB Ceremonial Building.

AWIKONKO gbo pe ojo Eti Fraide to tele ni won yoo yan giwa agba (Chancellor) tuntun, iyen Oba Alayeluwa, Edidem Ekpo Okon Abasi-Otu (V), Obon tiluu Calabar laago mewaa aaro.

Lojo Abameta Satide ti eto naa ba n lo lowo, leyin ti won ba ti bere eto laago mewaa aaro, ni won yoo fawon akekoo to peregede julo (First Degree), iyen awon to jade lati odun 2013 si 2015 ni aami eye, awoodu, nigba ti won yoo fawon to setan lodun 2015 si 2016 lami eye awoodu ti won.

Bakan naa ni won yoo fawon min in lawoodu Postgraduate ati Honourary Degree, gbogan ayeye ni eto naa yoo ti waye lojo kokanlelogun.

Ohun ta a gbo ni pe ojo naa ni won yoo gbe opa ase fun giwa tuntun ti won sese yan, iyen Ojogbon Felix Salako, toun naa yoo si bere ise lesekese.

Lakotan la gbo pe won ti so fawon akekoo to fee kopa nibi eto ayeye naa pe ki won loo ri daju pe won tete se ohun to ye ki won se ko too di ojo naa, nitori pe awon ti won ba ti yege ni won maa lanfaani lati gba iwe eri moyege.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI