Omoba fee bere eto tuntun lori redio Paramount - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 13, 2017

Omoba fee bere eto tuntun lori redio Paramount

Ko si ibeere meji tawon ololufe okan lara awon agba ilumooka nidi ise sorosoro, Babatunde AbdulGafar Okunade tawon eeyan mo si Omoba n beere, bi ko se pe ki lo de ti ko fi soro lori redio mo, sugbon toun n naa n so fun won pe oun nikan lo ye, ki won loo fokan bale.
 
Omoba Okunade
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, gbogbo eto lo ti pari bayii fun ti eto tuntun ti Omoba Okunade tawon ololufe e tun mo si Alabi Okumase fe e bere lori ikanni redio Paramount 94.4FM to wa ni opopona marose Abeokuta si Sagamu, iyen ni Kabape.

Ohun ta a gbo ni pe ibeere tawon to gbo nipa akoile eto ti Omoba to feran lati maa n gbe esin Islam laruge n beere ni pe ki lo o de to fi je pe esin igbagbo lo tun fe e maa gbe laruge sugbon ta a pada gbo pe esin Kristeni ati Islam lokunrin naa n se bayii latari awon iwadii ijinle to n se nipa esin.

Idi ni pe akole eto ti won ni Omoba fe e bere ni ose to m bo yi lo pe ni “Lati Inu Iwe Mimo Lori Paramount FM”, to si ti pari gbogbo awon nnkan to ye lati je ki eto naa te awon ololufe e lorun.

AWIKONKO gbo pe aago mokanla aabo aaro ni gbogbo ojo Abameta Satide ni eto naa yoo maa waye, ati pe ojo kokanlelogun, iyen ojo Abameta Satide to m bo yi ni akoko eto naa yoo bere nibi ti yoo ti maa foro Olorun bo awon eeyan.

Bakan naa la gbo pe yoo maa beere ibeere lowo awon to ba n gbo o, ti yoo si tun fi anfaani sile fawon eeyan lati beere ibeere, ti yoo si da won lohun lona to ye.Nigba to n jerii si, Alaga egbe sorosoro nipinle Ogun, Komureedi Olufemi Iyanda Omilani so pe lati le mu ileri toun se fawon omo egbe lasiko ipolongo idibo ti won fi gbe oun wole gege bi alaga lo je koun loo sepade alaafia po peluu awon alase ileese redio naa, ti won fun egbe won ni aaye lati maa seto nibe.


O ni leyin ipade naa ni won fawon silooti merinla (14 slots), toun si fawon omo egbe won lati maa seto lori redio naa, eyi ti Omoba funra e wa lara won, gege bi eni to ti bo sori afefe tipe.

Fawon to ba mo ileese redio Paramount FM to wa niluu Abeokuta yi daadaa, won yoo mo pe ileese redio naa tan kaakiri ile Yoruba, eyi ti yoo fawon to ba fe e polowo oja won lori eto naa lati je kawon eeyan tete mo nipa oniruuru oja tabi okoowo ti won ba n se.

Fun alaye lekunrere tabi ibeere, yala e fe e se ipolowo ni tabi e fe e gbe eto naa laruge, e le pe Omoba Babatunde Okunade funra e sori nomba e, iyen 08032370756.

E ku ojulona eto tuntun “Lat’Inu Iwe Mimo lori Paramount FM 94.5.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI