Maketa ni isoro ti mo ni - Sheidat Ta L'Olohun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 13, 2017

Maketa ni isoro ti mo ni - Sheidat Ta L'Olohun

Okan lara awon irawo to sese n dide bo nidi ise orin Islam, Hajia Sheidat Silifat Akanni (Omo Iyawo Anobi) tawon eeyan mo si Ta L'Olohun ti so pe ko si isoro meji toun n ni lasiko yi, bi kose ti ipenija maketa to n mu ifaseyin ba oun. O so pe nigba toun maa gbe awo orin orin akoko oun jade lodun 2013, maketa toun ri nigba naa lo mu ifaseyin ba orin naa, peluu bi awon eeyan se feran orin naa to. Hajia Sheidat, akobi omo ilumooka olorin Fuji nni, Alaaji Ramoni Akanna tawon eeyan tun mo si Mista Lecturer lo soro yi lakoko to n b'AWIKONKO soro niluu Ogbomoso nibi ayeye odun marundinlogoji ti baba e, Akanni ti n korin. E ka bi iforowero naa se lo sii.

AWIKONKO: Oruko yin?
TA L’OLOHUN: Oruko mi ni Sheidat Silifat AbdulRahmon Akanni tawon eeyan mo si Tal’Olohun, omo bibi ilu Ogbomoso ni mi

AWIKONKO: Bawo le se bere?
TA L’OLOHUN: Lati kekere ni mo ti ni ebun orin kiko nitori pe olorin ni baba to bi mi lomo, Alaaji Ramon Akanni tawon eeyan tun mo si Mista Lecturer, idi ni yii ti maa fi so pe ajogunba ni ise orin ti mo n ko. Nnkan ti mo ri ni pe lati kekere ti mo ti wa nileewe, emi ni mo maa n saaju awon egbe ta a jo n korin, igba ti baba mi si rii pe mo ni ebun e, inu won dun gege bawon naa se n korin, won gba mi nimoran pe ki n ri daju wi pe mo teju mo iwe mi, ki n si kawe yanju daadaa.

AWIKONKO: Awo orin meloo le ti gbe jade?
TA L’OLOHUN: Awo orin kan soso ni mo si gbe jade, Ta l’Olohun ni akole e, odun 2013 lo jade, sugbon nnkan ti ko je ki orin naa ta daadaa ni maketa ti mo ri nigba naa. Oun lo da bi eni pe ko je ki orin naa ta bo se ye. Adura mi ni pe ki Olohun je ka ri eeyan gidi ba dowo po.

AWIKONKO: Nje e tun ti n pinu lati gbe awo orin miran jade leyin Ta L’Olohun?
TA L’OLOHUN: Nigba ti mo se Ta L’Olohun, opo awon eeyan lo n beere pe iru orin wo leleyi, sugbon nigba ti won gbo o, won rii pe orin to se e gbo ni. Ibeere lasan ni akole yen. A mo orin i gbo ju ara wa lo. Ninu orin naa ni mo ti beere pe ta lo da Olohun mo, ta ni Olohun, mo je ko ye awon eeyan pe o se koko ka da Olohun mo ti a ba so pe a n sin Olohun. Nnkan to n dun mi ni pe ko tii rin de ibi ti mo fe ko rin de, lo fa a ti mi o tii se fe e pinu lati se awo orin min in jade. Ipenija maketa lo fa a ti ko fi rin bo se ko rin. Mo gbiyanju lati paaro maketa, eni ti mo tun ri nigba naa, oun naa ko gbe orileede Naijiria, ko raaye fun mi. Sugbon mo nigbagbo pe orin naa si maa rin nitori pe ko seni to gbo orin naa, ti ko ni kan saara sii.

AWIKONKO: Ki lawon ipenija tabi adajuko ti a ti ba pade?
TA L’OLOHUN: Looto, ipenija po, sugbon mi o ri won gege bi ipenija. Eyi ti mo rii pe o dun mi ju, mo lo lokesan kan niluu Ilorin, ti awon kan pe wa si, nigba ta a se tan, eni naa ko fun wa lowo ise wa, o si dun emi atawon taa jo lo nitori pe gbogbo ara la fi sise naa. Fun bi ojo meta ta a fi wa ninu oko abule to mu wa lo ni a o fi ri ounje je. Mo ni lati gbe e kuro lara nitori pe mo sese n dide bo ni, mi o si gbodo wo owo ju nitori pe lara awon amoran ti baba mi n fun mi niyen, ka le debi ta n lo. Ati pe baba mi maa n royin awon nnkan toju won ti ri nidi ise yii, eyi lo je ki emi naa gbe e kuro lokan pe bo pe, bo ya, o si maa da. Teeyan ba si ni amumora, o maa jana lojo kan. Mi o ri ojo ti inu mi baje nidi ise yi, nitori pe ise ti mo feran ni, nnkan to ba si wa, a fi ki n gba a.

AWIKONKO: Kini e fe e so nipa imura awon obinrin olorin Musulumi?
TA L’OLOHUN: Looto imura opo awon obinrin to n korin lasiko yi ko bojumu to. A o le tori i pe olaju ti wole de, nnkan esin la n se, eeyan si gbodo maa mura bo se to ati bo se ye, nitori pe iwa ati imura yen gan an lawon eeyan a fi maa wo wa pe a n ko won lekoo. Won si gbodo ri eko ti a n ko won lara wa.

AWIKONKO: Nje e ti bawon eeyan korin papo ri?
TA L’OLOHUN: Beeni, mo ti bawon gbajumo olorin korin papo ri. Lara won ni Alaaji Taye Currency, Big Dadi; Alaaja Amina; Dadi mi niluu  Ilorin, Aburido. Lowolowo bayii, mo tun n gbaradi fun kolabo peluu Ere Asalatu, ti mo si gbagbo pe o maa yori si irorun.

AWIKONKO: Gege bi eni ni baba e korin, nje baba yin maa n ri aaye lati ko o yin lorin?
TA L’OLOHUN: Awon kan ti beere iru ibeere yi ri lowo mi. Nigba ti mo se awo orin Ta L’Olohun lodun 2013, opo awon eeyan ni won so pe baba mi lo ko mi lorin. Ti m ba so fun un yin pe lati ojo ti mo ti n lo yara igbohunsile (studio), baba mi ko tele mi lo ri, ko da a, wo ko mo ibi ti mo ti n korin, won ko ko ri mi nibi ti mo ti n se igbaradi orin (reheasar) ri. Sugbon baba mo pe mo ni ebun orin.

AWIKONKO: Ewo lo dara ju ninu kolabo ati keeyan da se orin?
TA L’OLOHUN: Ni temi o, to ba je pe eeyan ri maketa gidi, o dara keeyan da se orin jade, nitori pe eeyan maa mo nnkan ti eeyan n se. Nnkan mi in le sele lati ibi ka maa se kolabo, awon min in le bere sii maa fe ara won, ki won si maa wo orisirisi aso ti ko boju mu. Sibe, kolabo naa dara pupo, nitori pe o maa n gbe opolopo awon olorin, paapaa awon to sese n dide bo bii temi. A kan gbodo fi iberu Olohun se gbogbo nkan ti a ba n se ni

AWIKONKO: Afojusun yin lojo iwaju?
TA L’OLOHUN: Afojusun mi po nitori pe mo ni nkan ti mo fe e se lojo iwaju. Won si maa n so pe ki a ma tori nkanti a fe je, ka fi ba nkan ti a fe e je je. Eni to ba ni ojo iwaju to dara, o ma maa ro bi ipinle ojo iwaju naa ko se nii baje, ko si ni fe e se nkan to maa ba loruko je, nitori pe ibi to n lo si jin.

AWIKONKO: Ki ni amoran yin fawon olorin to sese n dide bo bii ti yin?
TA L’OLOHUN: Imoran fawon asiwaju wa, nitori pe mo ba orin nile ni, emi naa o tii le pe ara mi asiwaju, ohun ni pe ki won se daadaa lati le je eko rere fawon to m bo leyin. Ka ma tori olaju to de ba ara wa je, nitori ara wa ni a le ba je, a ko le ba esin je. Bi eeyan se duro loto naa ni esin duro loto. Fun awon to m bo leyin, ki won ma kanju nitori baba mi maa n so fun mi pe asiko onikaluku otooto ni, ki a ma kanju, igba eeyan ko si nii koja onigba. Awon kan maa n so pe ki won wa feyin lele ti won ba fe edabi lagbaja, iro ni won n pa. Awon gan an ni won a pada maa fi eeyan se yeye teeyan ba di gbajumo lawujo.

Ramoni Akanni
AWIKONKO: Ayeye odun marundinlogoji ti baba yin se lai pe yi, bawo le se rii si?
TA L’OLOHUN: Ko da a, Olohun gbakoso nitori pe awon ti a ko lero pe won le wa ni won dide wa. Eeyan o le so bi inu enikan se dun to, on’inu lo le so nitori pe awon ta o lero pe won le fi taratara ba wa se ni won fara sise fun wa lojo naa. Gbogbo eto lo si lo bo se ye ko lo.

AWIKONKO: Ki ni e le so nipa baba yin?
TA L’OLOHUN: ti m ba ni ki n maa menuba oro nipa baba mi, ile a su, bee naa ni ile a tun mo. Onifuji ni baba mi, ti won ko ba si sise Fuji, Aafa ni won ko ba se. Idi ni pe ti won ba soro, o maa ri be e ni. Ti won ba si pe eeyan si akiyesi, keni naa gbo. Eni to ti ni iriri ninu aye yi ni, Olohun si so iriri won di ola fun won. Mo si gbadura pe won a pe laye je ounje omo. Ko si ibi ti baba mi le wa lorileede Naijiria yi ti won kii wa sile wa a sun, ayafi to ba je pe won lo sere mojumo, won kii gbagbe ile. Baba mi ko feran faaji repete, won maa n wa sile wa a sinmi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI