O ma se o; Tanka epo te okunrin kan pa lori okada l'Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 23, 2017

O ma se o; Tanka epo te okunrin kan pa lori okada l'Abeokuta

Adura to ye ki a maa tete se Amin si ni ti won ba n gbadura pe ki eeyan ma rin arinfese si, tabi ki eeyan ma rin lojo ti ebi n pa ona, nitori eyi lo nibamu pelu bi Tanka ileepo kan ti a ko tii mo oruko e titi dasiko ta a sakojopo iroyin yin tan se te okunrin kan pa lori okada lose to koja.

Oku e re nile
Gege b’AWIKONKO se gbo, ni nnkan bii aago mejo aabo asale ojo Monde to koja nijamba buruku naa waye niwaju ile ounje igbalode kan ta a foruko bo lasiri, to wa ni adojuko Tarmac ti won ti n ta foonu lagbegbe Ibara niluu Abeokuta nisele ti waye.

Ohun ta a gbo ni pe ina kan to maa n da awon moto duro to lo da awon moto duro lale ojo naa, sugbon ti won so pe awako to wa tanka epo naa ko duro, nitori ti ona e ko gba ibi ti awon moto toku n lo, ti ina naa tori e da won duro.

Lara awon to ta AWIKONKO lolobo je ko di mimo pe olokada to n bo leyin tanka epo naa ni ko tete fura wi pe tanka epo yi ko duro, ko too di pe o fe e lo ona eburu lati sare koja legbe e, sugbon ti ori tako o lale ojo naa.

A gbo pe pe olokada naa se de egbe tanka yi lati sare koja legbe e, abe taya iwaju lo ko si, toun ati eni to gbe si subu sii labe, ko too di pe taya e to wa leyin te eni to gbe seyin pa, sugbon ti ori ko oun yo.

Won ni esekese ni okunrin ti olokada naa gbe seyin ti ta teru nipa nitori ti taya tanka epo naa te ori e fo si wewe, ti opolo e si fo jade sita.

Awon tisele naa soju won la gbo pe won tete da awako tanka naa duro pe o ti pa eeyan, sugbon ti won so pe ariwo to gbo lo je ko duro lati mo nnkan to sele.

Eya ara e
AWIKONKO gbo pe ko seni to mo bi awako tanka epo naa se rin in nigba to bo sile lati mo nnkan to sele, to si rii pe oun ti pa eeyan, bee naa ni won so pe olokada ti ori ko yo naa na papa bora, ti ko seni to le so bo se rin in.

Won lesekese lawon tisele naa soju won ti ranse sawon ajo to n dari oko lopopona nipinle Ogun, iyen ajo TRACE, ti won si palemo oku naa lo si mosuari osibitu ijoba to wa ni Ijaye.

Lati fidi isele naa mule, Ogbeni Babatunde Akinbiyi b’AWIKONKO soro lori foonu laaro ojo keji, oun lo si je ko ye wa pe lesekese tawon ti gbo lawon ti sare lo, tawon si ti gboku naa lo si mosuari to wa n’Ijaye.

Akinbiyi so pe iwadii si n lo lowo lati mo ileepo to ni tanka epo yi ati olokada to salo naa toun yoo si fi to wa leti bi nnkan ba se n lo si, sugbon ti a ko tii gbo nnkankan titi dasiko ta a sokojopo iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI