Owo te Kugu ogbologbo adigunjale to n dawon loro ni Obantoko l'Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 23, 2017

Owo te Kugu ogbologbo adigunjale to n dawon loro ni Obantoko l'Abeokuta

Orin ope lawon araadugbo Fajol, Obantoko mu senu lai pe yii nigba ti asiri odomokunrin kan, Nureni Odejobi tawon eeyan tun mo si Kugu, ti won loun ni olori awon ogbologbo adigunjale to n pawon araalu lekun jaye.

Nureni Kugu
Gege b'AWIKONKO se gbo, ojo kesan osu yi lasiri e tu sita leyin ti won loo lo fo gilaasi moto okunrin kan, Oluyemi Akala  to si ko gbogbo eru to wa ninu e salo, sugbon tasiri e si pada tu sita.

Ohun ta a gbo ni pe, okunrin kan ti won n pe ni Abbey Bencash ti won lo maa n saye fawon eeyan  sese de latilu oyinbo, to si se faaji fawon eeyan lojo kejo osu yii nibi ti Kugu naa wa.

Bencash yi la gbo pe o ranse pe Oluyemi toun n ta oti wi pe ko loo ko oti sii wa, nigba to si maa pada de be lo sakiyesi pe oti ti won muu ti poju, eyi ti ko je ko ko oti naa bo sile ninu moto titi ti won fi setan lale ojo naa.

AWIKONKO gbo pe nigba tonikaluku won n gba ile won lo ni moto Oluyemi taku, to si paaki e segbe kan lero wi pe oun yoo pe mekaniiki lati wa wo nnkan to n se e lojo keji, lai mo pe Kugu n so o.

A gbo pe bi Oluyemi se lo tan, ni Kugu atawon ore e meji kan, Yaradua ati Fajol lo sidi moto naa, ti won si fo gilaasi e, ti won ko awon oti naa pelu awon eru min in, to fi mo batiri ati redio inu moto naa salo.

Ohun taa gbo nipe awon eeyan ni won ranse pe Oluyemi laaro ojo keji pe won ti fo gilaasi moto e, toun naa si tete gbera lati loo wo o, iyalenu ni won loo je fun, to si fibinu loo foro naa to Abbey Bencash leti.

Abbey Bencash ni won loo fura pe o seese ko je pe Kugu lo sise naa nitori to so pe oun ti n gbo iroyin pe awon adigunjale n dawon eeyan laamu ladugbo naa, eyi ti Kugu naa wa lara won.

Lesekese ni won so pe won ti loo ka Kugu mole lati foro wa a lenu wo, sugbon Awon oro to n so ni won loo mu ifura dani, ti won lawon eeyan bii mewaa tun jade lati jerii tako o.

Moto naa re e
Iya agbalagba to n ta ounje ladugbo naa, okunrin Ahusa to n ta Suya ati aso gini (Guinea), odomokunrin to n ta komputa ati okunrin kan toun se batiri saja (battery charger) la gbo pe Kugu ti ja lole, ti won si b'AWIKONKO soro.

Won ni osu to koja lo jale kan, ti won muu lo si tesan olopaa to wa ni Obantoko nibi ti won ti pada fi sile pelu ajosepo e pelu awon olopaa naa.

A gbo pe bo tile je pe ko koko jewoo, sugbon bi won se n muu wonu ogba awon SARS to wa ni Magbon lo ti bere sii bebe pe ki won se oun jeje, ati pe awon meta lawon jo n sise naa.

Ojo keta ni won so pe awon SARS lo ye ile Kugu wo nibi ti won ti ba ibon ilewo kan, ero komputa alagbeka atawon eru min in to jo eru ole nibe.

Lati fidi oro naa mule, agbenuso fun ileese olopaa nipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba to n bakoroyin wa soro laaro ojo Tosde ose to koja, o loun ko tii gbo nipa isele naa, sugbon toun yoo sewadi nigba toun ba de ibi ise.

Ohun ta a gbo ni pe awon SARS ti gbe Kugu lo si ogba awon elewon to wa ni Oba, nibi to ti n gbategun itura, bee ni won ni iwadii si n lo lowo lori bi won se maa mu Yaradua ati Fajol to na papa bora.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI