Beeyan
ba wa nibi tawon agbaagba ile Yewa ti n bawo oniroyin soro lai pe yi niluu
Abeokuta, yoo mo pe oro naa kii soju lasan, o lowo kan ninu ni.
Olusegun Osoba |
Egbe
agbagba ile Yewa ti ke gbajare faraye pe kawon eeyan gba awon lowo Oloye
Olusegun Osoba to ti figba kan je gomina nipinle Ogun tele lori bi ko se ro
rere kan awon lati di gomina lodun 2019.
Alaaji
Mohammed Ajibola Olagbayi to je alaga fegbe awon agbagba Yewa lo soro yii
lakoko ti won se ipade po peluu awon oniroyin lojo Tosde to koja yi ni Iwe Iroyin.
O
soro yii lati fesi si oro ti won ni Oloye Olusegun Osoba so pe won ko ti
tii
pin ipo gomina si isori kankan ninu isori metetaa ti won pin ipinle naa si
sugbon awon yoo fa eni to kun oju osuwon jade takoko ba to.
E ma gbagbe: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/eyi-ni-bi-gomina-ambode-di-alaga-egbe.html
E ma gbagbe: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/eyi-ni-bi-gomina-ambode-di-alaga-egbe.html
Okunrin
to gbenuso fawon egbe agba ile Yewa so pe latile lawon ti mo Osoba gege bi eni
a lo pa ti, won ni se lo so awon Yewa di ohun alopati ti ko si ye ko ri bee.
Won
ni kii se akoko yii to je pe awon eeyan pataki lawujo bii Oloye Olusegun
Obasanjo to je aare tele lorile ede yii ati Gomina Ibikunle Amosun peluu awon
min in ti panupo so pe Yewa ni gomina odun 2019 kan, ni Osoba wa n so iskuso
jade pe won ko tii pin ipo gomina si isori
Gege
bi oro ti Oloye Olagbayi so, o ni Osoba ko sese maa se iru e, asiko si ti to
lati pariwo e faraye nitori o fee so awon di amunisin.
Se e ti ka: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/ipa-ti-fijilante-n-ko-lorileede-yi-ko.html
Se e ti ka: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/ipa-ti-fijilante-n-ko-lorileede-yi-ko.html
Okunrin
naa so pe “Lojo kesan osu kejo odun yii ni Oloye Olusegun Osoba to tun je Araba
Yewa soro kan nile e ni Abeokuta pe won ko tii pin ipo gomina fodun 2019 sibi
kankan ati pe eni to ba wu lati Ijebu le jade sita, ko wa du ipo naa”
O
ni oro yii ku die kaato to je pe akoko tawon ti fimo sokan lati fa gomina kale
lati bi ogoji odun le seyin ti won ti da ipinle naa sile.
Egbe
agbalagba ile Yewa ti won tun je ti gomina so pe o ti pe die seyin ti Osoba ko
ti ro rere ko awon, fun apeere lodun 1992, se ni won lo fa oludije meji kale
laarin won lati fi tako Ojogbon Afolabi Olabimtan ti gbogbo araalu se tie.
Bee
naa ni won lo je esu leyin awon laarin won lodun 1998 si 2003 sugbon ti Olorun
gbeja awon ja lodun 2007.
E gbo: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/e-je-ki-ise-yin-tubo-fese-rinle-sii.html
E gbo: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/e-je-ki-ise-yin-tubo-fese-rinle-sii.html
Sibe
won ni ko tii deyin leyin awon, won wa ro lati peluu won nipa ipolongo lati je
ki Yewa di gomina. Bakan naa ni won tun so pe egbe awon nii se peluu oselu.
Olagbayi
tun so pe awon gbo pe won tun ti fee maa lo awon eeyan kan lati fi da aarin won
ru, amo Olorun ko ni gba fun won, Bee ni won ro gbogbo egbe oselu lati rii le
won fa oludije gomina won kale lati Yewa
Lesekese
ni Oloye Kayode Odunaro to je akowe iroyin fun Oloye Olusegun Osoba nigba to fi
wa nipo gomina so pe ko si ooto oro ninu ipade tawon agbaagba Yewa naa gbe jade
nitori ko sigba kankan ti Oga oun yii tako Yewa lati ma se di gomina.
Ninu
atejade to gbe jade lati fi tako ipade tawon eeyan naa se, to si so pe o lowo
oselu ninu. O ni gege bi enikan to ti sise peluu Osoba, toun si tun sun mon on
daadaa, oun nigbagbo pe awon agbaagba naa si oro ti oga oun so yii gbo, ati pe
ko si ninu awon eeyan ti won pejo naa ni won beere oro lowo Osoba nipa erongba
e lati je ki Yewa di gomina lodun 2019.
Oro sunukun: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/vso-rawo-ebe-sijoba-ipinle-ogun.html
Oro sunukun: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/vso-rawo-ebe-sijoba-ipinle-ogun.html
Odunaro
so pe o je iyalenu pe ninu awon ti won pe ara won ni agbagba naa ni won ti ba
Osoba sise po ri ti won si mo bi oro Yewa se ri.
Bee
lo so pe gege bi imo oun, nnkan to je Oloye Olusegun Osoba logun ni ki Yewa di
gomina lodun 2019, ati pe idagbasoke agbegbe naa tun je logun. Nitori idi eyi
awawi ni oro awon agbagba naa, won si fee fi da wahala sile ni.
A n gbadun yin
ReplyDeleteBeeni o
ReplyDelete