Bunmi ti won loo ta omo fi san gbese so pe won lu oun ni jibiti omo ni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 1, 2017

Bunmi ti won loo ta omo fi san gbese so pe won lu oun ni jibiti omo ni

Beeyan ba gbo bi Arabinrin kan, Olubunmi Tajudeen, eni odun metadinlogoji ti won loo ta omo e, omodun meta fi san gbese lose to koja, yoo mo pe oro naa kii soju lasan, nnkan to mon on je lo sakoba fun un.

Bunmi
Nigba to n b’AWIKONKO soro ninu ogba SARS to wa ni Magbon, Abeokuta lojo Tosde ose to koja, bo tile je pe ojo Tusde ni oga olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu ti foju e pelu awon odaran kan han fawon oniroyin kan, o so pe abamo loro naa je foun.

Olubunmi to so pe Ogere loun n gbe ni bii eni pe won lu oun ni jibiti lori loju oun, nitori ti Abibat Onasanya toun pade ladugbo kan ti won n pe ni Geto (Ghetto) so foun pe won fe e lo ba oun toju omo oun ni, to si se be e foun ni to ku die ko to egberun lona oodunrun naira.

O ni bo tile je pe ise awon to n ta omo alaini baba (Local Adoption) lo n se, ati pe odo e lawon asewo to ba bimo ti ko ni baba lo maa n ta omo fun un ni oteeli e to wan i Geto naa.

Olubunmi so pe Abibat lo w aba oun pe se oun ko ni omo toun fe e fi tore ni, nitori pea won kan wa ti won ko bimo, ti won si n wa omo ti won fe e mu gege bi omo ti won, lati maa ran nile iwe, lai mop e se lo loo ta omo oun.

Ninu oro e, O so pe “Ogere ni mo n gbe, sugbon mo maa n lo siluu Ibadan leekookan, agbo orisirisi bii jedi, opa eyin ni mo maa n ta fawon asewo, emi naa si maa n sise naa leekookan ti ko ba sowo lowo mi. eni to ba lo roba idaabobo maa n san #250naira, eni ti ko ba lo roba idaabobo maa n san #500naira. Mi o ta omo mi, Abibat to loun n ta omo tawon asewo ba bi fawon olowo ti ko bimo ri. Oteeli meta to ni ninu Geto lagbegbe Toll Gate naa lo maa n mu awon asewo lo tawon eeyan yoo si ma aba won sun titi ti won fi maa loyun.

“O mo pe mo ni awon omo ti ko ni baba, lo je ko beere lowo mi wipe se mo le gba ki omo mi, Oyindemilade ti mo bi le awon ibeji mi, omodun meta ni, wi pe oun ri enikan to le ma aba mi toju e nitori eni naa ko bimo ri. Igba ti mo gbe omo naa fun won, lo fun mi ni (#280,000) naira leyin ojo keta. O si seleri fun mi pe odun keji-keji loun yoo maa foju kan an.

“Gbese ni mo fi gbogbo owo naa san nitori pe mo ti ya owo lowo awon eeyan nigba ti mo ni ijamba moto, ti mo kan lese, atawon owo min in ti mo tun ti ya seyin ni owo naa ba lo. Gbogbo omo ti mo bi ni won ko ni baba nitori pe otooto ni baba won.

“Mo beere lowo e nigba to fun mi lowo naa pe se o loo ta omo mi ni, o so pe rara ko ri bee. O tun so pe ki n so fawon ore mi ti won ban i iru awon omo bayii, ki n bawon gba a nitori pea won nilo omo kan si, awon a si fun mi lowo.

“Mo so pe mi o ni, o wan i se mi o le bawon jii gbe ni, idi ni yii temi naa fi lo ba asewo kan ti a jo wa ni Ogere lo so pe egbon oun kan ni omo ni Bodija lagbegbe Oju-Irin, o sig be omo naa fun mi. awon araadugbo ti mo ise ti won n se tele, sugbon ti mi o mo.”

Awon meteeta
Olubunmi so pe oun ko nii lokan lati ta omo oun, nitori lati ojo ti alaye ti da ile aye ni awon eeyan ti n gba omolomo toju, toun naa sir i gege bi anfaani lati ri eni ti yoo ba oun toju omo oun.

Bee lo seleri pe bawon olopaa ba fi le foju aanu woo un, oun setan lati ran won lowo lori bi won se le mu awon toku ti won sise buruku yi, paapaa toun yoo si sa gbogbo ipa oun lati ri omo oun gba pada.

“Ti olopaa ba le fi mi sile labe ofin, mo seleri fun won pe gbogbo ibi tawon eeyan naa wa, ti won ko lero pe mom o ni maa mu won de. Tete ni won n gba, maa rii pe mo gba omo mi pada nigba ti mo ti mo wi pe nise ni won ta omo mi.”

Abibat nigba toun tako esun ti Olubunmi fi kan an so pe oun koo ta omo, nitori pe leyin toun kuro ni Ogere ni Abibat pe oun pe oun nijamba moto, oun si nilo owo lati fi toju ara oun, ati pe toun ba ni omo ti won fee ta (adopt), oun nilo eyokan.

Ninu oro e, “Omo bibi ilu Ago Iwoye ni mi sugbon Ibafo ni mo n gbe. Omodun mokanlelaadota ni mi. o ti le ni odun marun ti mo ti kuro ni Geto. Agbo ni mo n ta ni Eko, nitori latigba tijoba ti wo awon ile pako ti mo fi se renti fawon asewo ni mot i ko lo si Eko. Lai pe yin i Abibat pe mi pe oun nijamba moto, ti m ba ri awon ti won fe e adopt omo, oun fe e gbe omo oun Oyinade sile, mo si ni ko si wahala.

“Obinrin kan to so pe olopaa loun, ati pe Alakaraloun ti n sise naa tun so fun mi pe ti n ba ni awon ti won fe e adopt omo, ki n je koun gbo, mo wa ni ki iyawo egbon mi lo ba mi gba lowo e, nitori mo n gba omi lowo nileewosan. Igba ti obinrin yen wa, o fun mi egberun lona oodurun naira (#300,000), mo si fun Olubunmi, iya Oyin ni #280,000 lesekese, mo tun fun iyawo egbon mi ni egberun marun naira.

“Gbogbo oro to n so yen, isokuso ni nitori pe nigba ti mo si wan i Geto, ahusa ni gbogbo awon asewo ti mo n lo, eyi to bas i ti bimo maa n gbe omo won sile pelu egberun meji naira, leyin ojo keta ni won maa to wag be omo won. Ko si asewo to bimo sodo mi, odun kan soso naa ni mo fi se e.

“Mo kabamo pe mo sise yi fun igba akoko nitori pe gbogbo ebi lo ti ko mi. iya mi, oko mi atawon omo mi ko tii yoju si mi latigba ti won ti mu mi. Asise lo je fun mi nitori pe asise ko ni oga. Mi o nkan kan nipa wi pe won gbe omo lo siluu Ghana, aheso lasan ni.”

Morenike Shituu, eni ogoji odun, ti won loun lo loo gba omo lowo Olubunmi so pe ipekere (plantain chips) ni loun n ta, oun loun si maa n gba omo dani nigba ti iya oko oun, Abibat si n se ise (lodging) ni Ogere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI