Ori ko oga agba FCE Abeokuta yo ninu ijamba ojo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 12, 2017

Ori ko oga agba FCE Abeokuta yo ninu ijamba ojo

Die lo ku kawon akekoo to n se 'danwo farapa

Bi kii ba a se opelope ori to ko oga agba ileewe awon olukoni Federal College of Education, Osiele Abeokuta nipinle Ogun yo lojo Isegun Tusde ana nibi ijamba ojo arooroda to wo apa kan lara ofiisi oga agba (Provost) naa, nnkan ta n ko yi ko ni a o ba maa ko.

Gege b'AWIKONKO se gbo, ojo nla kan ni won loo bere sii ro ni nnkan bii aago meji osan, sugbon ti ko seni to fura pe o see se ki ojo naa fa ijamba fawon osise atawon akekoo ileewe naa.

A gbo pe ni deede aago meji aabo ni iji nla bere sii ja, to si tun wo opolopo igi nla to wa  igba ileewe naa. Lakoko ti idanwo saa ikekoo yi n lo lowo ni ojo naa bere.

AWIKONKO gbo pe ere lawon eeyan koko pe e nigba ti iji naa bere, ti won n gbo ariwo, sadede ni won so pe iji naa wu igi nla kan pelu gbongbo, to si woo lu ile tawon akekoo ti n se idanwo lowo, tawon eeyan si bere sii sa kijokijo.

Lara awon to ta AWIKONKO lolobo nipa isele naa so pe awon eeyan farapa lakoko isele naa nitori bi ile se wo lu awon eeyan to n se idanwo lowo, atawon to wa ninu ofiisi won, nibi ti won ti n sise won.

Orisirisi ile la gbo pe ojo naa baje kaakiri inu igba ileewe naa, to si ko awon alase, osise atawon akekoo ileewe naa sironu latari ose ti won lojo naa se.

Lara awon ile ti ijamba naa se lose ni ofiisi oga agba ileewe naa, ile eka akekoo nipa ise owo (iyen vocational education department), ofiisi Dean; laabu ti eka ikekoo Micro Teaching, iyen Laboratory; ofiisi awon egbe akekoo (Students Union building), ileegbe awon akekoo (hostels); gbongan ikawe to gba egberun aabo awon akekoo (1500-seater hall) atawon min in.

Nigba to n b'AWIKONKO soro nipa ijamba naa, igbakeji oga agba ileewe naa, Dokita Rafiu Soyele so pe lojiji ni isele naa ba won, nitori pe awon ko mura sile fun in, ati pe akoko re e ti iru nkan bee maa sele.

O banuje pe asiko ti ko sowo nile lati naa niru ijamba yi waye, to si rawo ebe sijoba apapo lati ran won lowo, lati satunse awon ibi ti ojo naa baje.
 
Soyele so pe a fi kijoba apapo tete da si oro naa, ki won si sagbateru bi awon atunse to ye se maa waye ko too di pe awon akekoo wole saa tuntun losu kokanla to m bo yi.

Bee lo dupe lowo Olorun pe ijamba naa gba emi enikeni lakoko to sele nitori pe to ba je pe awon eeyan fara pa ju bo se ye, o seese ko je pe nnkan tawon n so yi ko ni won o ba maa so.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI