Gomina
ana nipinle Ogun, Oloye Otunba Gbenga Daniel, OGD ti so o jade sita gbangba pe
ko seni to le di oun lowo lati di ipo alaga egbe oselu Peoples Democratic
Party, PDP nile Yoruba (Southwest).
OGD
soro yi lojo Aje Monde ijeta lati fi tako awuyewuye to n lo kaakiri orileede
yii pe o see se ko so pe oun ko dupo naa mo lati fi aaye sile fun Oloye Olabode
George to je igbakeji alaga egbe oselu naa tele.
Daniel
so pe oun ko ni lero lati so pe boya oun ko nii dupo naa mo lati fi faye sile
fenikeni, o ni iro to jinna si ooto oro ni nitori pe gbogbo nnkan loun fi kun
oju osuwon lati di alaga egbe oselu alatako, PDP naa.
Daniel
so pe bo tile je pe oun bowo fun Oloye Bode George gege bi agbalagba, to si je
pe gbogbo awon tawon jo n le ipo naa lo je ore oun, sugbon oun ko le tori e so
pe oun ko se mo nitori pe onikaluku lo ni ipinu e to fee se lokan.
O
loun se iwadii daadaa, paapaa nibi ipade gbogboogbo egbe tawon se lai pe yi
niluu Port Harcourt, toun ri bawon eeyan se nife oun to, toun tun mo awon
agbaagba to se tan lati gbaruku ti oun.
Ninu
oro e, o so pe "Gbogbo awon oludije fun ipo yi ni won je ore mi, sugbon
gege bi e se mo mi pe mo maa n tun nkan se ni, ti mo si tun je eni to kun oju
osuwon ju fun ipo naa.
"
Mi o ni so pe mo fee pada seyin nitori pe mo se iwadi daadaa lakoko ipade
gbogboogbo taa se niluu Port Harcourt, mo si mo awon agbaagbaa nile Yoruba to
fe mi, ti won si setan lati fowosowopo pelu mi.
"Onikaluku
lo ni erongba ti won lati dupo. Bawon kan se jade dupo lati fi kun oro ile aye
won (CV), bee lawon kan n dupo lati fi ri nnkan gba, tawon kan si n dupo lati
jawe olubori.
"Kii
se oro boo-ba-o-pa. Oro oselu inu ile wa ni, eyi lo fa ti mo fi pinu lati jade
dupo naa, ki n si gbegba oroke lati le lo iriri ati ogbon mi lati satunto egbe
oselu yii."
Yato si
Otunba Gbenga Daniel, lara awon min in to tun n foju sona lati di alaga egbe
oselu PDP ni Ogbeni Jimi Agbaje lo dupo gomina ipinle Eko lodun 2015; Ojogbon
Tunde Adeniran, minisita tele foro eto eko ati Ojogbon Toaheed Adedoja toun naa
je minisita foro ere idaraya teleri lorileeede yii.
No comments:
Post a Comment