Wahala de: Won ni olori ile igbimo asofin ipinle Ogun gbe opa ase pamo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 11, 2017

Wahala de: Won ni olori ile igbimo asofin ipinle Ogun gbe opa ase pamo

Bo tile je pe oludamoran pataki fun olori ile igbimo asofin nipinle Ogun, Ogbeni Waheed Akinola ti so pe ko si ooto oro ninu aheso ti won n gbe kaakiri nipa oga e, Omoba Suraju Ishola Adekunbi wi pe awon kan fe e dite lati yoo nipo, ati pe nitori e lo se gbe opa ase ile igbimo asofin naa pamo, sibe ohun tawon eeyan n so ni pe iro nla ni won n pa.

Gege b'AWIKONKO se gbo, won ni afaimo ni ki wahala maa be sile nile igbimo asofin tipinle Ogun nitori bi won se lawon asofin kan se n gbero lati yo olori won naa, iyen Suraju Adekunbi nipo.

Ohun ta gbo ni pe won ni Okunrin olori ile igbimo asofin naa ti n fura pe nnkan kan fee sele idi niyii to fi loo gbe opa ase ile igbimo naa pamo sile ijoba, ti ko je kenikeni mo ibi to gbe e sii.

Won ni se lokunrin naa loo gbe opa naa pamo kawon omo ile igbimo asofin naa maa ba dite gbajoba mo on lowo, ko to ti irinajo to loo siluu London to sese de yii de.

Lose to lo lohun ni Adekunbi rin irinajo loo siluu London nibi apero kan tawon  omo ile Yewa sagbekale e, paapaa lati tun fi wa ojurere awon eeyan naa fun ti ipinu oselu e lati dupo Gomina lodun 2019.

A gbo pe anfaani naa lawon ti ko gba ti Adekunbi naa fee lo lati fi le kuro nipo sugbon toun naa tete fura pe o seese ki omi teyin wogbin oun lenu toun ko ba tete dogbon soro ara oun.

Iroyin to te AWIKONKO lowo je ko ye wa pe lati bi osu meloo kan seyin lawon omo ile igbimo asofin ipinle Ogun ti pin si meji, metala, metala ni won mu ara won.

Idi won ni won se fee yo okunrin naa ko ju bi won se so pe ibasepo pelu gomina Amosun lenu ojo meta yi n fa akoba nla fun won.

Iwadii tun fi ye wa pe nitori olori ile igbimo asofin naa ko fokan tan awon omo abe yii lo mu ko pinu lati loo gbe opa ase naa pamo sile ijoba.

AWIKONKO gbo pe bi Suraju Adekunbi se de lati ilu London lo ti sare loo gbe opa ase naa jade sita lahamo to gbe e pamo si ko too lo, eyi gan ni won loo fun oludamoran pataki e yi, Ogbeni Waheed lenu oro lati tako iroyin naa pe ko si nkan to jo be.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI