Abewo Makarfi siluu Abeokuta ko lese nile - Bayo Dayo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 4, 2017

Abewo Makarfi siluu Abeokuta ko lese nile - Bayo Dayo


Tolu Ogunlana, Ijebu Igbo

Alaga egbe oselu PDP nipinle Ogun, Oloye Onimo Ero Adebayo Adedayo ti so pe abewo ti Oloye Ahmed Markafi to je olori egbe oselu naa wa a se siluu Abeokuta ko lese nile nitori ti ko so fawon to je gege bi ojulowo omo egbe, paapaa oun toun je alaga egbe nipinle naa ni ko fi to leti.

Ahmed Makarfi ati Bayo Dayo
Bayo Dayo soro yi lakoko to n b'AWIKONKO soro nile e to wa niluu Ijebu Igbo laaro oni ojo Abameta Satide, ojo kerin osu kokanla, o so pe oun ko gbo nkankan nipa wi pe eni to je gege bi alaga egbe oselu naa lapapo lorileeede yi n bo wa siluu Abeokuta to je olu-ilu ipinle toun ti je alaga egbe oselu naa.

Ninu oro e, O so pe "Emi o rii gbo pe Makarfi n bo niluu Abeokuta nitori pe gege bi ilana se so, ti olori egbe patapata ba n lo sibi kan, o gbodo fi to awon ara agbegbe naa paapaa alaga to wa nibe leti lati le maa mura sile.

"Sugbon eni to m bo lati ilu Abuja wa silu Abeokuta, o gbodo so fun alaga ipinle naa pe oun n bo lakoko bayii, won a si se eto ayeye bi won se maa pade e, sugbon eyi ti Makarfi n se ko ye enikan nitori pe o ti wa si odo Baba wa Olusegun Obasanjo ti a si se ayeye bi a se maa pade e, ti gbogbo awon omo egbe si ti loo duro sile ise wa, ti a ko si rii. Eyi ti won tun so pe o n bo yii, mi o mo nkankan nipa e, sugbon a ba awon to n bo wa ki ku oriire."

Siwaju sii lo so pe "Gbogbo egbe to ba je egbe nla bi egbe oselu PDP, a gbodo mo wi pe orisirisi awon eeyan lo maa wa nibe. Bi awon to da a se po ninu egbe wa naa ni awon to ku die kaato naa wa. Sugbon leyin ti a se ipade apapo to gbe wa wole la ti n gbo awuyewuye won, a si lo sile ejo, ile ejo si so pe awa gan an la ni eto lati je agbateru egbe wa, lati woodu titi de ijoba ibile ati ijoba ipinle.

"Nigba ti kootu ti soro yi jade, ti ko si tii si ile ejo to gbe idajo naa ti segbe kan, ko si nkan tenikeni tun le se, bi ko se pe ki awa naa si maa tesiwaju gege bii ojulowo lati maa se agbateru egbe naa. Gbogbo awon to sa lo sodo Makarfi ni won so pe oun lo ye ko wa nibe, a si ba won gba a be e pe oun ni oga gbogbo wa, lati din wahala ku, sugbon ibi ti won n ba oro lo yii, won fe e ba egbe je ni.

Bakan naa lo so pe "Ti Makarfi ba je eni to mo bi won se n to egbe, o ye ko pe otun ati osi lati beere ona ti a fe e gbe e gba lati pana wahala to n sele, sugbon Makarfi gan an funra e ko figba kan gbe apoti, iran lo wa a wo ni Port Harcourt tawon bii Ayodele Fayose si rii nibe, ti won pe e pe ko wa maa se olori egbe lo.

"Sugbon gbogbo agbateru e to n se lo maa dopin lojo kesan an osu kejila ti a ba lo sibi ipade gbogboogbo nitori pe osu merin pere ni won fun in tele ki won to o sun siwaju di osu to m bo, iyen Disemba. A si ba a gbadura pe ki Olorun ka ise rere mon on lowo."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI