Won kede akoroyin gege bi Oba Olota tuntun; lo ba bu sekun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 28, 2017

Won kede akoroyin gege bi Oba Olota tuntun; lo ba bu sekun

Yoruba bo won ni "Ori to ba ma a de ade, inu agogo ide lo ti n wa; orun ti yoo wo ejigba ileke, inu agogo ide naa lo ti n wa; a n joo rin, a o mo ori olowo", eyi gan an lo lo nibamu pelu bi won se yan Dokita AbdulKabir Adeyemi Obalanlege gege bi Oba Olota tiluu Ota nijoba ibile Ado-Odo Ota ipinle Ogun lonii, ojo kejidinlogbon, osu kokanla, odun 2019.

Obalanlege
Bi won se kede Obalanlege gege bi eni to jawe olubori laarin awon oludije marun lo ku die ko bu sekun, sugbon ti omije ayo ti le sii loju lai ro tele, tawon abaniyo si sare gba a mu.

Obalanlege to ti figba kan je akoroyin fun ileese iwe iroyin Concord tele, to tun je oluko agba ni eka ise iroyin ati igbohunsafefe (Mass Communications) ni Yunifasiti Crescent to wa niluu Abeokuta ni won ti fowo si bayii gege bi Oba Olota ketala latigba ti won ti bere sii yan Oba.

Gege b'AWIKONKO se gbo, idibo ita gbangba ni won fi yan Obalanlege laarin awon marun un to peregede ninu awon oruko Omoba mejilelogun to dide lati di Oba Olota tuntun naa.

Be o ba gbagbe, ni nnkan bi ose meta si merin seyin nijoba ipinle Ogun so pe ki eto yiyan Oba Olota tuntun naa bere, ti won si gbodo pari e lonii, ojo Isegun Tusde, eyi to mu kawon afobaje ilu naa foruko awon omoba mejilelogun ranse si idile Ijemo/Isoloshi ti ipo naa kan dide, sugbon to je pe awon marun un ni won pada wa a muu.

Ogba ileese ijoba ibile ni eto naa ti Oloye Bamgboye Osunlabu to je Ekerin tiluu Ota siwaju awon afobaje marun to sakoso eto naa ti waye, nibi ti akowe ijoba ibile naa, Onarebu Wale Dada atawon eso eleto aabo ko ti gbeyin.

Ojo kejidinlogbon osu kejo odun 1966 ni won bi Dokita Yemi Obalanlege ni Mushin, ipinle Eko. Baba e ni Omoba Hassan Taiwo Obalanlege ti agboole Ijemo nigba ti iya e je Arabinrin Mutiat Afolake Obalanlege (Nee Anjorin), ti agboole Isoloshi niluu Ota.

Dr. Yemi Obalanlege je okan lara awon omo egbe akoroyin, eka ti United Kingdom; okan lara awon omo egbe olukoni Higher Education Academy, UK. 

Lara awon ibi ti Obalanlege tun ti sise ni University of East London, England; University of Lincoln, England.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI